ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 17-20
  • Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ bí Òbí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ bí Òbí
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ta Ló Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Ní Ìwà Tí Wọ́n Á Máa Hù?
  • Máa Fi Ìfẹ́ Tí Ò Láàlà Hàn sí Wọn
  • Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọmọ Rẹ Kó O sì Máa Bá A Sọ̀rọ̀ Déédéé
  • Wá Àyè Láti Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àwọn Tó Ti Ṣàṣeyọrí Nínú Títọ́ Ọmọ
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Ẹ̀yin Òbí—ẹ Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Tìfẹ́tìfẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ǹjẹ́ Bíbélì Lè Ràn ọ́ Lọ́wọ́ Láti Tọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Báwo Ni Kíkọ́ Ọmọ Láti Kékeré Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
    Jí!—2004
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 17-20

Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ bí Òbí

PETER GORSKI láti ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn ní ilé ìwé gíga Harvard Medical School sọ pé: “Tó o bá jẹ́ kí ọmọ kan mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ òun, pé ilé ni ilé rẹ̀, pé ó wúlò àti pé ó lè béèrè ìbéèrè nípa ohun tó bá rú u lójú, ò ń fún ọpọlọ rẹ̀ lágbára nìyẹn. Ojúṣe wa gẹ́gẹ́ bí òbí kì í wulẹ̀ ṣe mímú kí ọpọlọ ọmọ lè ṣiṣẹ́ lọ́nà tó pé pérépéré, bí kò ṣe pé láti tọ́ ọmọ kó lè dàgbà kó di ọlọ́pọlọ pípé ẹ̀dá tó sì lè ṣàánú fáwọn èèyàn.”

Á mà dùn mọ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí nínú o, tó o bá rí bí ọmọ rẹ ṣe dàgbà, tó di ẹni tó mọ̀wàá hù láwùjọ, tó sì máa ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò! Kó o tó lè ṣe àṣeyọrí lọ́nà bẹ́ẹ̀ ṣá, ó sinmi lórí bó o bá ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ tó, bí ìwọ àti ẹ̀ bá ṣe mọwọ́ ara yín tó, bó o ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ tó àti irú ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ ọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ọmọ tí wọ́n bí tí kò lè mọ ìwà hù, síbẹ̀ ó yẹ káwọn òbí máa fìwà rere kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Ta Ló Máa Kọ́ Àwọn Ọmọ Ní Ìwà Tí Wọ́n Á Máa Hù?

Èrò àwọn olùṣèwádìí ò jọra lórí ẹni tí ọmọ máa fìwà jọ jù lọ. Àwọn kan gbà pé àwọn tí ọmọ bá ń bá rìn

ló máa fìwà jọ. Síbẹ̀, Dókítà T. Berry Brazelton àti Dókítà Stanley Greenspan, táwọn méjèèjì jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa bí ọmọdé ṣe ń dàgbà sọ pé ipa tí òbí ń kó lórí fífi jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tọ́ ọmọ dàgbà kò ṣeé fẹnu sọ.

Àwọn ìrírí tọ́mọ bá là kọjá lẹ́yìn náà àti nǹkan táwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ń ṣe á wá fi kún bó ṣe máa rí nígbà tó bá dàgbà. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí fi àánú àti òye kọ́ àwọn ọmọ nínú ilé. Ó tún yẹ kí wọ́n kọ́ wọn bí wọ́n á ṣe lè mú ohun tó bá ń dà wọ́n láàmú mọ́ra bí àgbàlagbà. Táwọn ọmọ tí wọ́n kọ́ nírú ọ̀nà yìí bá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, wọ́n á lè tètè bá àwọn ẹlòmíràn fọwọ́ sowọ́ pọ̀, wọ́n á lè ní ìyọ́nú, wọ́n á sì lè máa gba tàwọn ẹlòmíràn rò.

Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni iṣẹ́ kíkọ́ ọmọ láti ìkókó o. Kẹ́ ẹ tó lè pegedé nínú ẹ̀, pàápàá jù lọ bẹ́ ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ òwò ọmọ títọ́, ó bọ́gbọ́n mu pé kẹ́ ẹ tọ àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ abiyamọ lọ kẹ́ ẹ sì máa tẹ̀ lé ìlànà gbòógì kan. Àwọn ògbógi ti kọ àìmọye ìwé lórí bọ́mọ ṣe ń dàgbà. Lọ́pọ̀ ìgbà lohun tí wọ́n sọ máa ń jọ ìmọ̀ràn tó ṣeé tẹ̀ lé tó wà nínú Bíbélì. Àwọn ìlànà tó mọ́yán lórí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ran àwọn òbí lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé wọn. Gbé àwọn ìtọ́ni wíwúlò tó wà níbí yẹ̀ wò.

Máa Fi Ìfẹ́ Tí Ò Láàlà Hàn sí Wọn

Àwọn ọmọdé dà bí àwọn irúgbìn tó máa ń dàgbà dáadáa nígbà tá a bá tọ́jú wọn déédéé tá a sì ń fún wọn láfiyèsí tìfẹ́tìfẹ́. Omi àti ìmọ́lẹ̀ oòrùn máa ń mú kí ọ̀jẹ̀lẹ́ irúgbìn kan dàgbà dáadáa kó sì fìdí múlẹ̀. Bákan náà, àwọn òbí tí wọ́n fi ojú, ẹnu àti gbogbo ara sọ fáwọn ọmọ wọn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wọn máa ń tipa bẹ́ẹ̀ ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mú kí ọpọlọ wọn jí pépé kí ọkàn wọn sì lélẹ̀ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Bíbélì sọ ọ́ kedere pé: “Ìfẹ́ a máa gbéni ró.” (1 Kọ́ríńtì 8:1) Àwọn òbí tó ń fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ ní gbogbo ọ̀nà ń fara wé Ẹlẹ́dàá wọn, Jèhófà Ọlọ́run. Bíbélì sọ pé nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, ó gbọ́ ohùn Bàbá rẹ̀ tó ń sọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti bó ṣe fọwọ́ sí ohun tó ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ti dàgbà nígbà náà, ọ̀rọ̀ yìí á mà fi í lọ́kàn balẹ̀ o!—Lúùkù 3:22.

Ìfẹ́ tó o bá ń fi hàn sí ọmọ rẹ, àwọn ìtàn tó o bá ń kà sí i létí lálẹ́ kó tó sùn àti irú eré òṣùpá tó ò ń bá a ṣe wà lára àwọn ohun tó ṣe pàtàkì láti mú kí ọmọ rẹ dàgbà dáadáa. Dókítà J. Fraser Mustard sọ pé ‘Gbogbo nǹkan tí ọmọ bá ń ṣe ló máa mú wọnú ìtàn ìgbésí ayé ẹ̀. Tí ọmọ kan bá ń rákòrò, ó ṣe pàtàkì pé kó o máa ràn án lọ́wọ́ kó má bàa ṣubú.’ Ìfẹ́ àti àfiyèsí tó o bá ń fún ọmọ rẹ gẹ́gẹ́ bí òbí lá á gbé àtẹ̀gùn ìdàgbàsókè síwájú rẹ̀, èyí tá á gùn gòkè àgbà tá a sì fi lè wúlò lọ́jọ́ iwájú.

Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọmọ Rẹ Kó O sì Máa Bá A Sọ̀rọ̀ Déédéé

Tó o bá ń lo àkókò pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ, á fún ìdè òbí sọmọ lágbára. Yàtọ̀ sí ìyẹn, á tún mú kí ọmọ rẹ mọ ọ̀rọ̀ sọ. Ìwé Mímọ́ gba àwọn òbí níyànjú pé kí wọ́n máa wà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn yálà nínú ilé tàbí níbòmíràn ní gbogbo ìgbà tí àyè ẹ̀ bá yọ.—Diutarónómì 6:6, 7; 11:18-21.

Àwọn ògbógi lórí ọ̀ràn ìdàgbàsókè ọmọ gbà pé àkókò táwọn òbí bá lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn ṣe pàtàkì ju àwọn ìṣeré ọmọdé olówó iyebíye àti nǹkan mìíràn tí wọn ì báà ṣe fún wọn. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ náni lówó téèyàn sì máa ń ṣe wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́, ẹ ó lè rí àkókò lò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín tẹ́ ó sì láǹfààní láti máa bá wọn sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, kíkó àwọn ọmọ lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí àgbà lákòókò ìsinmi kúrò ní ilé ìwé lè mú kí wọ́n rí oríṣiríṣi àwọn nǹkan alààyè, òye wọn á sì kún rẹ́rẹ́ sí i báwọn òbí ti ń lo ìbéèrè láti mọ èrò àwọn ọmọ, èyí á sì mú kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ fàlàlà wáyé láàárín òbí àtàwọn ọmọ.

Ìwé Mímọ́ sọ pé “ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri” wà. (Oníwàásù 3:1, 4) Òótọ́ ni o, àǹfààní tí ọmọ ní láti máa ṣeré ẹ̀ bó ṣe wù ú á jẹ́ kó lè gbọ́n dáadáa, kí ọkàn rẹ̀ lè balẹ̀ kó sì lè mọ bó ṣe yẹ kó máa ṣe láàárín èrò. Gẹ́gẹ́ bí Dókítà Mustard ṣe sọ, kì í ṣe pé eré ṣíṣe wúlò fún ọmọdé nìkan ni, àmọ́ ó tún pọn dandan kí ọmọ máa ṣeré. Ó sọ pé: “Ìgbà táwọn ọmọdé bá ń ṣeré ni gbogbo ẹ̀yà inú ọpọlọ wọn tó máa mú kí wọ́n lè ṣe onírúurú iṣẹ́ máa ń dàgbà.” Tá a bá yọ̀ọ̀da kí ọmọ kan máa ṣe irú eré tó wù ú, àwọn ohun ìṣeré tá á máa lò lè jẹ́ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lágbára, irú bíi kòròfo páálí. Àwọn nǹkan tá à ń lò nínú ilé lójoojúmọ́, tí ò sì lè fa ìpalára máa ń jọ àwọn ìkókó lójú bí àwọn ohun ìṣeré táwọn ilé iṣẹ́ dìídì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìṣeré ọmọdé.a

Àwọn ògbógi gbà gbọ́ pé táwọn àgbàlagbà bá kó iṣẹ́ tó pọ̀ jù lé àwọn ọmọdé láyà tí wọ́n sì jókòó tì wọ́n jù, ó lè pa ọgbọ́n wọn mọ́ wọn nínú tí wọn ò sì ní lè dá nǹkan kan ṣe. Wọ́n dábàá pé ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ló gbà. Jẹ́ kí ọmọ rẹ náà ro orí ara rẹ̀ kó o sì wo bí orí rẹ̀ ṣe pé tó. Lọ́pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ọmọ kan á fẹ́ ṣe nǹkan láti dá ara rẹ̀ nínú dùn. Ìyẹn ò ní kó o káwọ́ lẹ́rán kó o máà kíyè sí nǹkan tí ọmọ rẹ ń ṣe àti ibi tó ti ń ṣeré tá á fi di pé á lọ ṣe ara rẹ̀ léṣe.

Wá Àyè Láti Kọ́ Ọmọ Rẹ

Kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó o lè ṣe láti tọ́ wọn dàgbà kí wọ́n sì di ọmọlúwàbí. Ọ̀pọ̀ òbí ló máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ lójoojúmọ́ láti kàwé sí ọmọ wọn létí. Èyí á fún wọn láǹfààní láti lè kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìwà tó bójú mu láwùjọ, èèyàn tún lè fi àǹfààní yẹn gbin àwọn ìlànà ìwà rere, tá a gbé karí ohun tí Ẹlẹ́dàá sọ, sínú ọkàn ọmọ kan. Bíbélì sọ pé Tímótì tó jẹ́ olóòótọ́ olùkọ́ àti míṣọ́nnárì ‘ti mọ ìwé mímọ láti ìgbà ọmọdé jòjòló.’—2 Tímótì 3:15.

Kíkàwé sí ọmọ létí lè mú kí àwọn fọ́nrán inú ọpọlọ rẹ̀ máa tètè so kọ́ra. Ohun pàtàkì kan ni pé ó yẹ kó jẹ́ ẹnì kan tó lákìíyèsí tó sì lè ṣaájò ọmọdé ló ń ka ìwé náà sí ọmọ létí. Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìwé kíkọ́, Linda Siegel, ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Kò gbọ́dọ̀ ju ohun táwọn ọmọdé lè gbádùn lọ.” Bákan náà, gbìyànjú láti jẹ́ kí ìwé kíkà náà ṣe déédéé kó sì máa bọ́ sí àsìkò kan náà lójoojúmọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ọmọ náà á lè máa fojú sọ́nà fún un.

Ìbáwí wà lára kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́. Ìbáwí onífẹ̀ẹ́ lè ṣe àwọn ọmọ kéékèèké láǹfààní. Òwe 13:1 sọ pé: “Ọmọ a jẹ́ ọlọ́gbọ́n níbi tí ìbáwí baba bá wà.” Rántí pé ìbáwí ò mọ sọ́nà kan. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi ọ̀rọ̀ ẹnu bá a wí tàbí kó o fi àwọn ẹ̀tọ́ kan dù ú tàbí kó o bá a wí lọ́nà míì. Dókítà Brazelton tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣáájú sọ pé ohun tó ń jẹ́ ìbáwí ni “pé kéèyàn kọ́ ọmọ láti lè darí èrò inú rẹ̀ kó má sì lè yawọ́. Gbogbo ọmọ ló ń retí kí wọ́n fún àwọn ní gbèdéke. Lẹ́yìn ìfẹ́, ìbáwí ni nǹkan kejì tó ṣe pàtàkì jù tó o lè fún ọmọ.”

Báwo ni ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí ṣe lè mọ̀ bóyá ìbáwí tó ò ń fún ọmọ rẹ á ṣiṣẹ́? Ọ̀nà kan tó fi lè ṣiṣẹ́ ni pé káwọn ọmọ rẹ mọ ìdí tó o fi ń bá wọn wí. Nígbà tó o bá tọ́ àwọn ọmọ rẹ sọ́nà, ṣe é lọ́nà táwọn ọmọ á fi mọ̀ pé tiwọn lò ń ṣe àti pé òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ni ọ́.

Àwọn Tó Ti Ṣàṣeyọrí Nínú Títọ́ Ọmọ

Fred jẹ́ bàbá kan tó ti sọ ọ́ di àṣà láti máa kàwé sí ọmọbìnrin rẹ̀ létí lálaalẹ́, látìgbà ìkókó, kí wọ́n tó sùn. Nígbà tó yá ó ṣàkíyèsí pé ọmọbìnrin rẹ̀ ti mọ ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìtàn tóun máa ń kà fún un sórí tí ọmọ náà sì máa ń ka ìwé náà látorí bí bàbá rẹ̀ bá ṣe ń kà á, ó sì tún ti dá àwọn ọ̀rọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń dún létí mọ̀. Chris tún jẹ́ òbí mìíràn tóun náà ò fi ọ̀rọ̀ kíkàwé sáwọn ọmọ rẹ̀ létí jáfara. Ó rí i dájú pé oríṣiríṣi ìsọfúnni lòun máa ń kà sáwọn ọmọ òun létí. Nígbà táwọn ọmọ rẹ̀ ṣì kéré, ó máa ń fi àwọn àwòrán tó wà nínú àwọn ìwé bí Iwe Itan Bibeli Mi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ìwà rere àtàwọn ẹ̀kọ́ nípa ìlànà Ọlọ́run.b

Láfikún sí kíkàwé fáwọn ọmọ, àwọn òbí míì ń gbìyànjú láti máa ṣe oríṣiríṣi nǹkan míì irú bíi yíyàwòrán, kíkun nǹkan, lílo àwọn èlò orin, pípàgọ́, tàbí rírìnrìn àjò pa pọ̀ bí ìdílé lọ sí ọgbà tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn ẹranko. Wọ́n lè fi àwọn àkókò wọ̀nyẹn kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì gbin ìwà ọmọlúwàbí sí wọn lọ́kàn kí ọkàn wọn má bàa yigbì.

Ṣé gbogbo làálàá yìí tiẹ̀ lérè kankan? Táwọn òbí bá sa gbogbo ipá wọn láti fi àwọn ìlànà àtàtà tá a ti ń jíròrò bọ̀ yìí sílò lábẹ́ ipò tí kò ti sí inú fu ẹ̀dọ̀ fu, wọ́n lè retí pé káwọn ọmọ táwọn ń tọ́ láwọn ànímọ́ tá á jẹ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí. Tó o bá ti kékeré kọ́ àwọn ọmọ rẹ lọ́gbọ́n tó o sì kọ́ wọn bó ṣe yẹ kí wọ́n máa sọ̀rọ̀, wàá lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìwà tó dáa kí wọ́n sì jẹ́ ẹni tẹ̀mí.

Ní ọ̀rúndún bíi mélòó kan sẹ́yìn, Bíbélì sọ kedere nínú Òwe 22:6 pé: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” Ó dájú pé kékeré kọ́ niṣẹ́ àwọn òbí nínú kíkọ́ ọmọ. Máa fi ìfẹ́ tí ò láàlà hàn sí àwọn ọmọ rẹ. Máa lo àkókò pẹ̀lú wọn, máa tọ́ wọn kó o sì máa kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. Bó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ayọ̀ ńláǹlà ló máa mú wá fún ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ.—Òwe 15:20.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà “Awọn Ohun Iṣere Africa Lọfẹẹ,” tó jáde nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn yìí ti March 22, 1993.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́. Ìwé mìíràn tàwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún tẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ láti kọ́ àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ni Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 17]

Bó O Ṣe Lè Máa Bá Ọmọ Rẹ Ṣeré

◼ Àwọn ọmọdé kì í lè fara balẹ̀ fún àkókò tó gùn tí eré fi máa ń sú wọn, nítorí náà ìgbà tó bá dà bíi pé ó ń dùn mọ́ wọn nìkan ni kó o máa bá wọn ṣeré.

◼ Tó o bá ń lo àwọn ohun ìṣeré ọmọdé, rí i dájú pé wọn ò lè ṣe ọmọ léṣe wọ́n á sì jẹ́ kó lè ronú.

◼ Àwọn eré tẹ́ ẹ jọ máa fi pawọ́ dà ni kẹ́ ẹ jọ máa ṣe. Inú àwọn ìkókó máa ń dùn tẹ́ ẹ bá jọ ń ṣeré láṣetúnṣe, irú bíi pé kó o máa bá wọn mú àwọn ohun ìṣeré tí wọ́n jù sílẹ̀.

[Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ìwé ìròyìn Clinical Reference Systems

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn Àbá Lórí Kíkàwé sí Ọmọ Rẹ Létí

◼ Sọ̀rọ̀ ketekete kó o sì máa pe ọ̀rọ̀ dáadáa. Látinú ohun tí obí bá ń sọ lọmọ ti ń kọ́ èdè.

◼ Tó bá jẹ́ ọmọ tó kéré gan-an lò ń kàwé fún, fi àwòrán àwọn èèyàn àtàwọn nǹkan tí wọ́n dárúkọ wọn nínú ìwé ìtàn tó ò ń kà fún un hàn án.

◼ Nígbà tí ọmọ náà bá ń dàgbà, àwọn ìwé tó dá lórí àwọn nǹkan tó fẹ́ràn ni kó o máa kà fún un.

[Credit Line]

Orísun ìsọfúnni: Ìwé ìròyìn Pediatrics for Parents

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18, 19]

Máa lo àkókò láti ṣeré ìtura pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́