ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g04 11/8 ojú ìwé 13-14
  • Báwo Ni Kíkọ́ Ọmọ Láti Kékeré Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo Ni Kíkọ́ Ọmọ Láti Kékeré Ti Ṣe Pàtàkì Tó?
  • Jí!—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Àbínibí Ló Ṣe Pàtàkì Ni àbí Bá A Ṣe Tọ́mọ?
  • Irú Ẹ̀kọ́ Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọdé
  • Ojúṣe Rẹ Gẹ́gẹ́ bí Òbí
    Jí!—2004
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Ìgbà Ọmọdé Jòjòló
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín
    Jí!—2007
  • Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kó Lè Borí Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ikú Fà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—2004
g04 11/8 ojú ìwé 13-14

Báwo Ni Kíkọ́ Ọmọ Láti Kékeré Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

FLORENCE ti pé ọmọ ogójì ọdún, ojú ọmọ sì ń pọ́n ọn. Àmọ́ nígbà tó jàjà lóyún, dókítà kan kì í nílọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ọmọ tó máa fi oyún náà bí má lè kẹ́kọ̀ọ́. Kò mà ṣẹ́yún náà o, ọmọkùnrin làǹtì lanti ló sì foyún náà bí.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Florence bí Stephen ọmọkùnrin ẹ̀ tán tó fi bẹ̀rẹ̀ sí kàwé sí i létí tó sì ń bá a sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà tí àyè bá yọ. Bó ṣe ń dàgbà sí i, òun àti ìyá rẹ̀ máa ń ṣeré, wọ́n jọ máa ń jáde, wọ́n máa ń ka ení, èjì, ẹ̀ta, wọ́n sì máa ń kọrin. Florence sọ pé: “Kódà nígbà tí mo bá ń wẹ̀ ẹ́, a máa ń rí nǹkan kan fi ṣeré.” Àwọn ohun tó ṣe fún ọmọ rẹ̀ yìí sì yọ lára ẹ̀ nígbà tó yá.

Stephen gboyè jáde ní ilé ìwé gíga University of Miami nígbà tó ṣì wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlá. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìndínlógún, ó jáde nílé ìwé ẹ̀kọ́ṣẹ́ amòfin, òun sì ni amòfin tọ́jọ́ orí rẹ̀ kéré jù lọ ní ilẹ̀ Amẹ́ríkà, gẹ́gẹ́ bí ìtàn ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe sọ. Ìyá rẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Florence Baccus, tó ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ rí tó sì ti fẹ̀yìn tì gẹ́gẹ́ bí olùgbaninímọ̀ràn fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́, ti fi àkókò gígùn kàwé nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ láti kékeré. Ó dá a lójú pé bí òun ṣe ń fún ọmọ òun ní àfiyèsí àti dídá tóun ń dá a lára yá ló yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.

Ṣé Àbínibí Ló Ṣe Pàtàkì Ni àbí Bá A Ṣe Tọ́mọ?

Ọ̀rọ̀ tàwọn olùṣèwádìí ń jiyàn lé lórí lọ́wọ́ báyìí ni pé bóyá “àbínibí,” ìyẹn ohun tí ọmọ ti jogún lọ́dọ̀ àwọn tó bí i, ló ń pinnu bí ọmọ ṣe máa dàgbà ni àbí “bí wọ́n ṣe tọ́ ọ,” ìyẹn ẹ̀kọ́ àti ìtọ́ni tó rí gbà. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn olùṣèwádìí ló gbà pé àwọn méjèèjì ló ní ipa tí wọ́n ń kó nínú bí ọmọ ṣe ń dàgbà.

Ọ̀mọ̀wé kan tó mọ̀ nípa bí ọmọdé ṣe ń dàgbà, Dókítà J. Fraser Mustard, ṣàlàyé pé: “Ohun tí ìwádìí fi yé wa nísinsìnyí ni pé àwọn nǹkan tó bá ṣẹlẹ̀ sí ọmọ ní kékeré

máa nípa lórí bí ọpọlọ rẹ̀ á ṣe dàgbà.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Susan Greenfield náà sọ pé: “Bí àpẹẹrẹ, a mọ̀ pé àwọn atagòjé máa ń mọ ìka ọwọ́ òsì lò ju àwọn èèyàn tó kù lọ nítorí pé apá ibi tó máa ń jẹ́ kí èèyàn mọ ọwọ́ òsì lò nínú ọpọlọ máa ń ṣiṣẹ́ dáadáa nínú ọpọlọ àwọn atagòjé ju ti àwọn tó kù lọ.”

Irú Ẹ̀kọ́ Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọdé

Látàrí ohun táwọn ìwádìí wọ̀nyí ti fi hàn, ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti rí i pé ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi tó dáa làwọn mú ọmọ àwọn lọ. Kì í ṣèyẹn nìkan o, wọ́n tún ń ná òbítíbitì owó lórí kíkọ́ àwọn ọmọ wọn ní orin kíkọ àti iṣẹ́ ọnà. Àwọn kan gbà pé tí ọmọ bá fi gbogbo nǹkan dánra wò, tó bá dàgbà tán, á lè mọ gbogbo nǹkan ṣe. Àwọn àkànṣe ẹ̀kọ́ kíkọ́ àtàwọn ilé ìwé jẹ́lé-ó-sinmi ń pọ̀ sí i. Àwọn òbí kan ò kọ ohun tó máa ná wọn láti rí i pé ipò iwájú lọmọ àwọn ń mú.

Ṣé kò sí ìṣòro kankan nídìí rírúnpá rúnsẹ̀ sórí kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà yìí? Lóòótọ́ ló dà bíi pé yóò fún àwọn ọmọdé láìmọye àǹfààní bí wọ́n bá ń dàgbà, síbẹ̀ èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọmọdé wọ̀nyí ló ti pàdánù ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọn ì bá rí kọ́ ká ní wọ́n ríbi ṣeré tó wá látọkàn wọn. Àwọn akọ́mọlẹ́kọ̀ọ́ sọ pé tí ọmọ bá ń ṣe eré tó bá wá sí i lọ́kàn, á mú kí ọmọ náà lè máa dá nǹkan ṣe, á sì mú kó mọ ọgbọ́n tá a fi máa bá àwọn èèyàn ṣe nǹkan pọ̀, ọpọlọ rẹ̀ á jí pépé, á sì mọ bí èèyàn ṣe ń fọkàn balẹ̀.

Àwọn ògbógi onímọ̀ nípa bí ọmọ ṣe ń dàgbà gbà pé, yíyàn táwọn òbí bá ń yan eré tí ọmọ á ṣe fún wọn ń dá ìṣòro mìíràn sílẹ̀ fáwọn ọmọ. Ìṣòro ọ̀hún ni pé, ara máa ń ni àwọn ọmọ tí wọn ò lè yan ohun tó wù wọ́n, ọkàn wọn kì í balẹ̀ tó bẹ́ẹ̀, wọn kì í lè sùn, wọ́n sì máa ń kígbe òní ẹ̀fọ́rí, ọ̀la ara ríro. Afìṣemọ̀rònú kan sọ pé nígbà táwọn ọmọdé wọ̀nyí bá fi máa di ọ̀dọ́langba, ọ̀pọ̀ wọn ni kò tíì ní kọ́ bí wọ́n á ṣe máa ṣe tí ìṣòro bá dé, “kíá sì ni agara á máa dá wọn, tí wọ́n á wá ya ara wọn láṣo tí wọ́n á sì wá di oníjàgídíjàgan kalẹ̀.”

Tóò, ọ̀rọ̀ náà wá tojú sú ọ̀pọ̀ òbí. Wọ́n fẹ́ ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti dàgbà kí wọ́n sì lè lo agbára àbínibí wọn lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Síbẹ̀, wọ́n ti rí i pé kò mọ́gbọ́n dání táwọn bá ń ti àwọn ọmọ kéékèèké lọ́pọnpọ̀n-ọ́n. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì lórí ọ̀rọ̀ kíkọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́? Báwo lòye àwọn ọmọdé ṣe ń pọ̀ sí i bí wọ́n ṣe ń dàgbà, báwo sì ni a ṣe lè tọ́ wọn? Kí làwọn òbí lè ṣe láti rí i pé àwọn ọmọ wọn ṣàṣeyọrí? Àpilẹ̀kọ tó kàn báyìí yòó dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwọn ohun tí ọmọ bá fojú rí láti kékeré lè pinnu bí ọpọlọ rẹ̀ ṣe máa lágbára tó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Bọ́mọdé bá ń ṣeré, á mú kó túbọ̀ já fáfá kó sì mọ nǹkan ṣe

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́