De Bẹ́líìtì Ara Ìjókòó Rẹ Nítorí Ààbò
◼ Ní United States, àwọn ìjàǹbá ọkọ̀ ìrìnnà ni lájorí okùnfà ikú tí ń pa àwọn èwe ọlọ́dún 5 sí 24.
◼ Ní Japan, ìjàǹbá ọkọ̀ lójú ọ̀nà ń pa ju ìlọ́po méjì àwọn tí àrùn jẹjẹrẹ ọmú ń pa lọ, ó sì ń pa tó ìlọ́po mẹ́rin ènìyàn tí àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀yà ara tí ń pèsè omi tí ń gbé sẹ́ẹ̀lì àtọ̀ ń pa.
◼ Ní Yúróòpù, ìjàǹbá ọkọ̀ ń pa tó ìlọ́po mẹ́rin iye ènìyàn tí àwọn ènìyàn míràn ń pa.
ÀWỌN àkọsílẹ̀ oníṣirò tí ń páni láyà wọ̀nyí ń tẹnu mọ́ ọ̀kan lára àwọn ewu rírin ìrìn àjò nínú ọkọ̀—eré sísá ń pani. Eré sísá lẹ́yìn tí awakọ̀ ti mutí líle ló sì lè pànìyàn jù. Ó dùn mọ́ni pé a lè dín ewu ìjàǹbá àti ìpalára kù. Báwo ni ìyẹn ṣe ṣeé ṣe?
Mímú àṣà ìwakọ̀ láìséwu dàgbà jẹ́ ọ̀nà kan tí ó dára láti fi bẹ̀rẹ̀. Àwọn ògbóǹtagí kan nípa ààbò sọ pé a lè yẹ ìjàǹbá 9 nínú 10 sílẹ̀, tàbí kí a yẹra fún wọn. Kíkọjá ìwọ̀n eré sísá tí a sàmì rẹ̀ síbì kan, yíya àwọn ọkọ̀ míràn sílẹ̀ àti pípààrọ̀ ọ̀nà léraléra, sísún mọ́ ọkọ̀ tó wà níwájú jù, wíwakọ̀ lẹ́yìn lílo oògùn líle tàbí mímu ọtí líle, àti wíwa ọkọ̀ tí a kò tọ́jú dáradára jẹ́ àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ nínú àṣà ìwakọ̀ tó léwu. Ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè àti ìfẹ́ ọmọnìkejì ẹni gbọ́dọ̀ mú kí a ní ìṣarasíhùwà oníṣọ̀ọ́ra àti ìṣeéfọkàntẹ̀ nígbà tí a bá ń wakọ̀.—Mátíù 7:12.
Ìgbésẹ̀ ààbò rírọrùn míràn, ṣùgbọ́n tí a sábà máa ń gbójú fò ni lílo bẹ́líìtì ara ìjókòó ọkọ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Tim Hurd, agbẹnusọ kan ní Ẹ̀ka Ìgbòkègbodò Ọkọ̀ ní United States, ṣe sọ, “lílo bẹ́líìtì ààbò ni ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù láti gba ẹ̀mí rẹ là nígbà tí ọkọ̀ bá ṣèjàǹbá. Ó ń sọ bí ó ti ṣeé ṣe tó láti là á já di ìlọ́po méjì.” Ní ti àwọn ọmọ kéékèèké, bí wọ́n bá lo ìjókòó ààbò ọmọdé, àǹfààní lílàájá wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po mẹ́ta.a
Láìka gbogbo ìwọ̀nyí sí, àwọn ìwádìí fi hàn pé àwọn èrò ọkọ̀ tí kì í lo bẹ́líìtì ìjókòó ní United States fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdámẹ́ta. Ǹjẹ́ ìwọ gẹ́gẹ́ bí òbí kan ń rí i dájú pé àwọn ọmọ rẹ ń de ara wọn mọ́ ìjókòó wọn kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí í wakọ̀? Àkókò tí ó gbà láti de bẹ́líìtì yẹ tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àjọ Àbójútó Ààbò Ojú Pópó Orílẹ̀-Èdè dámọ̀ràn pé: “A kò gbọ́dọ̀ gbé àwọn ọmọdé tó bá wà nínú ìjókòó ọmọdé tó kọjú sẹ́yìn sórí ìjókòó iwájú nínú àwọn ọkọ̀ tó bá ní àpò afẹ́fẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìjókòó èrò. Bí àpò afẹ́fẹ́ bá ń ṣiṣẹ́, tí ó sì gbá ìjókòó ọmọdé tó kọjú sẹ́yìn, ó lè pa ọmọ náà lára.”