Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 10
Orin 99 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbél15ì Ìjọ:
cl orí 15 ìpínrọ̀ 20 sí 23, àti àpótí tó wà lójú ìwé 157 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 19-22 (10 min.)
No. 1: Diutarónómì 22:20-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Tí Ìwé Mímọ́ Sọ Nípa Ìrántí Ikú Kristi—td 28A (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Á Fẹ́ràn Jésù—lr orí 38 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fọ̀rọ̀ Wá Ọ̀rọ̀ Wò Lẹ́nu Alábòójútó Iṣẹ́ Ìsìn. Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn? Kí ló máa ń jẹ́ àfojúsùn yín tí ẹ bá ń bẹ àwùjọ kan wò? Báwo làwọn tó wà ní àwùjọ náà ṣe lè jàǹfààní nígbà ìbẹ̀wò yín? Báwo lẹ ṣe máa ń ṣèrànwọ́ fún akéde tó wá bá yín pé kẹ́ ẹ ran òun lọ́wọ́ lórí bí òun á ṣe mú apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun sunwọ̀n sí i?
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún.” Ìjíròrò. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ yìí, ṣe àṣefihàn alápá méjì. Lákọ̀ọ́kọ́, ní kí akéde kan fi ìwé tí à ń lò lóṣù yìí ṣe àṣefihàn, àmọ́ kó máà ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ onílé jẹ òun lógún. Lẹ́yìn náà, kí akéde yìí tún àṣefihàn náà ṣe, lọ́tẹ̀ yìí kó fi hàn pé ọ̀rọ̀ onílé jẹ òun lógún.
Orin 84 àti Àdúrà