Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Jésù bìkítà nípa àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún. Ó ṣeé ṣe kí Jésù ti kíyè sí i pé ojú ń ti ọkùnrin adití kan tó fẹ́ wò sàn bó ṣe wà láàárín èrò, torí náà Jésù mú u kúrò láàárín èrò, ó sì wò ó sàn níbi táwọn èèyàn kò sí. (Máàkù 7:31-35) Jésù fi hàn pé òun gba tàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rò bó ṣe mọ ibi tí agbára wọn mọ, tí kì í sì í rọ́ ìsọfúnni tó pàpọ̀jù sí wọn lágbárí lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. (Jòh. 16:12) Nígbà tí Jésù wà lọ́run pàápàá, ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ ẹ́ lógún. (2 Tím. 4:17) Torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, àpẹẹrẹ rẹ̀ la fẹ́ máa tẹ̀ lé. (1 Pét. 2:21; 1 Jòh. 3:16, 18) Bákan náà, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò túbọ̀ múná dóko tá a bá ń gba tàwọn onílé rò, tá a sì ń kíyè sí ipò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn wà, ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó ń jẹ wọ́n lọ́kàn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ wa tí wọ́n bá rí i pé kì í kàn ṣe torí ká lè wàásù fún wọn tàbí torí ká lè fún wọn ní ìwé la ṣe wá, ṣùgbọ́n ó jẹ́ torí pé a dìídì nífẹ̀ẹ́ wọn.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Nígbà ìjọsìn ìdílé yín, ẹ ṣe ìdánrawò bí akéde kan ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ohun tí onílé sọ mu, ẹ sì lè ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́ ẹ bá wà lóde ẹ̀rí.
Arákùnrin tó máa darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá lè jíròrò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún tàbí kó ṣe àṣefihàn bá a ṣe máa ṣe é.