Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Kíkíyèsí Ohun Tó Wà Láyìíká Wọn
1 Kò sí ẹlẹgbẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Kristi Jésù nínú ká kíyè sí ohun tó ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn ká sì ṣe é fún wọn. (2 Kíró. 16:9; Máàkù 6:34) Bá a bá ń fòye gbé ohun tó ń jẹ àwọn tá à ń wàásù fún lọ́kàn, a ó lè máa gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà táá fi máa bá ohun tó wà lọ́kàn wọn mu.
2 Máa Kíyè sí Gbogbo Ohun Tó O Bá Rí: Jésù máa ń kíyè sí àwọn èèyàn. (Máàkù 12:41-43; Lúùkù 19:1-6) Bákan náà, bá a bá dé ẹnu ọ̀nà àwọn èèyàn, tá a sì rí àwọn nǹkan ìsìn tí wọ́n fi ṣe ilé wọn lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ sára ọkọ̀ tàbí ohun ìṣeré tó wà nínú ọgbà wọn, a lè bẹ̀rẹ̀ ìwàásù wa látorí àwọn nǹkan yẹn.
3 Ìrísí àti ìṣesí ẹnì kan lè fi ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ hàn. (Òwe 15:13) Ó ṣeé ṣe kí ìrònú dorí ẹ̀ kodò kó sì nílò ìtùnú látàrí ikú èèyàn rẹ̀ kan tàbí ohun mìíràn tó ń dà á láàmú. Àwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà tá a lè kà tó máa tù ú nínú. (Òwe 16:24) Kí ló yẹ ká ṣe bí ẹni tá a fẹ́ bá sọ̀rọ̀ bá ń kánjú tàbí tí ọmọ tó gbé dání bá ń ké? Tí ọ̀rọ̀ bá rí báyìí, ó máa dáa tá a bá lè jọ ṣètò àkókò míì tá a máa padà bẹ̀ ẹ́ wò. Bá a bá ń ro tàwọn ẹlòmíì mọ́ tiwa tá a sì ń fi hàn pé a ní “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì,” ẹni yẹn á lè fetí sí wa nígbà tá a bá padà bẹ̀ ẹ́ wò.—1 Pét. 3:8.
4 Mú Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Bá Ohun Tó O Kíyè sí Mu: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kíyè sí i pé ìlú Áténì ní pẹpẹ kan tí wọ́n mọ fún “Ọlọ́run Àìmọ̀.” Pẹpẹ tó rí yìí ló mú kó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó gbà gbé e kalẹ̀, nígbà tó sọ pé: “Ohun tí ẹ ń fún ní ìfọkànsin Ọlọ́run láìmọ̀, èyí ni mo ń kéde fún yín.” Bí Pọ́ọ̀lù ṣe fọgbọ́n gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀ ló jẹ́ kó rọrùn fáwọn kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ láti ronú lórí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí wọ́n fi di onígbàgbọ́.—Ìṣe 17:23, 34.
5 Bákan náà, bá a bá ń kíyè sí ohun tá a bá rí, a ó lè mọ ohun táwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí, ìyẹn á sì jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà táá fi bá ohun tá a rí mu. Bi ẹni náà láwọn ìbéèrè tó máa mú kó rọrùn fún un láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó lè túbọ̀ fún ẹni náà níṣìírí. (Òwe 20:5) Bá a bá ń kíyè sí ohun tó wà láyìíká àwọn èèyàn, tá a sì ń fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún, a ó lè mọ bó ṣe yẹ ká gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ lọ́nà jíjá fáfá.