Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ November 11
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ NOVEMBER 11
Orin 119 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jl Ẹ̀kọ́ 5 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Hébérù 1-8 (10 min.)
No. 1: Hébérù 4:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Kí “Ọgbọ́n Tó Ti Òkè Wá” Máa Darí Wa?—Ják. 3:17, 18 (5 min.)
No. 3: Ṣé Lóòótọ́ Ni Jésù Kú Sórí Àgbélébùú?—td 2A (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Ṣèrànwọ́ fún Àwọn Èèyàn. Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Kó gbé e ka Ilé Ìṣọ́ November 15, 2013, ojú ìwé 8 sí 9.
10 min: Bó O Ṣe Lè Borí Ìbẹ̀rù Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń bẹ̀rù láti wàásù láti ilé dé ilé? (2) Kí nìdí tí ìbẹ̀rù fi máa dín kù tá a bá múra sílẹ̀ dáadáa? (3) Kí ló lè mú kí ìbẹ̀rù wa dín kù tá a bá ń bá alábòójútó àyíká ṣiṣẹ́? (4) Kí nìdí tí ìbẹ̀rù wa á fi máa dín kù bá a bá ń jáde òde ẹ̀rí déédéé? (5) Kí ló ti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìbẹ̀rù?
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Hóséà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 113 àti Àdúrà