Orin 73
Ká Nífẹ̀ẹ́ Ara Wa Látọkàn Wá
1. Ká ní ìfẹ́ látọkàn wá,
Ibẹ̀ ni ìfẹ́ ti ńṣẹ̀ wá;
Táa fi ńní ìgbatẹnirò
Fáwọn ará ọ̀wọ́n.
Aó wá ọ̀nà láti fi hàn
Pé a nífẹ̀ẹ́ ará dọ́kàn,
Ká máa ṣoore bí Ọlọ́run,
Kífẹ̀ẹ́ wa jẹ́ tòótọ́.
Ká fẹ́ni lọ́rọ̀, níṣe,
Ká lawọ́ sí àwọn aláìní,
Ká lo àǹfààní táa ní
Láti máa fi ṣe oore.
Ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn ará;
Ká sì máa fọ̀rọ̀ wọn sọ́kàn.
Aò ní máa wá àṣìṣe wọn.
Aó jẹ́ adúróṣinṣin,
Tó ńpa ìṣọ̀kan wa mọ́.
2. Tí ìfẹ́ táa ní bá dénú,
A kò ní tètè máa bínú;
Aó máa fi gbogbo ọkàn tán
Àwọn ará tòótọ́.
Aó láwọn ọ̀rẹ́ àìṣẹ̀tàn;
Aó sì mọrírì ara wa.
Aó máa fayọ̀ ṣe ìpàdé,
Okun wa yóò dọ̀tun.
Ojoojúmọ́ la ńṣàìtọ́;
Sísọ̀rọ̀ láìronú ńfa aáwọ̀.
Ká máa ní sùúrù fáwọn
Tí Ọlọ́run wa fẹ́ràn.
Láéláé laó jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́,
Tó ńmú kí ìrẹ́pọ̀ máa wà.
Wá gbé ìfẹ́ wọ̀ bí ẹ̀wù.
Máa gbé Ọlọ́run wa ga,
Fara wé ìfẹ́ tirẹ̀.
(Tún wo 1 Pét. 2:17; 3:8; 4:8; 1 Jòh. 3:11.)