ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • kp ojú ìwé 28-31
  • “Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”
  • Ẹ Máa Ṣọ́nà!
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”—Kí Ló Ń Jẹ́ Bẹ́ẹ̀?
  • Kí Nìdí Tá A Fi Ní Láti Nífẹ̀ẹ́ Ara Wa?
  • Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ẹlòmíràn
  • “Òpin Ohun Gbogbo Ti Sún Mọ́lé”
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Bá A Ṣe Lè Mú Kí Ìfẹ́ Tá A Ní Sáwọn Ará Túbọ̀ Lágbára
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Ìfẹ́ Máa Gbé Yín Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run Tó Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
Àwọn Míì
Ẹ Máa Ṣọ́nà!
kp ojú ìwé 28-31

“Lékè Ohun Gbogbo, Ẹ Ní Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”

“Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. . . . Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 PÉTÉRÙ 4:7, 8.

JÉSÙ mọ̀ pé ìwọ̀nba wákàtí díẹ̀ tó kù kóun lò pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì òun ṣeyebíye gan-an. Ó mọ ohun tó ń dúró dè wọ́n níwájú. Iṣẹ́ ńlá ń bẹ fún wọn láti ṣe, àmọ́ àwọn èèyàn yóò kórìíra wọn, wọn yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn, bí wọ́n ti ṣe sí òun. (Jòhánù 15:18-20) Lálẹ́ tí wọ́n jọ wà pa pọ̀ kẹ́yìn náà, ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tó rán wọn létí pé ó pọn dandan kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì.”—Jòhánù 13:34, 35; 15:12, 13, 17.

2 Àpọ́sítélì Pétérù, tó wà níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà lóye bí ọ̀rọ̀ Jésù yìí ṣe ṣe pàtàkì tó. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, tí Pétérù ń kọ̀wé nígbà tó kù díẹ̀ kí ìparun Jerusálẹ́mù ṣẹlẹ̀, ó tẹnu mọ́ bí ìfẹ́ ṣe ṣe pàtàkì tó. Ó fún àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé. . . . Lékè ohun gbogbo, ẹ ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Pétérù 4:7, 8) Ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe kókó gan-an fún àwọn tó ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (2 Tímótì 3:1) Kí ló ń jẹ́ “ìfẹ́ gbígbóná janjan”? Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn? Báwo la sì ṣe lè fi hàn pé a ní in?

“Ìfẹ́ Gbígbóná Janjan”—Kí Ló Ń Jẹ́ Bẹ́ẹ̀?

3 Ọ̀pọ̀ máa ń rò pé ìfẹ́ jẹ́ ànímọ́ kan tó kàn máa ń jẹ yọ fúnra rẹ̀. Àmọ́ kì í kàn án ṣe irú ìfẹ́ èyíkéyìí ni Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ o; irú ìfẹ́ kan tó dára jù lọ ló ń sọ. Ọ̀rọ̀ náà “ìfẹ́,” tó wà ní 1 Pétérù 4:8 jẹ́ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, a·gaʹpe. Ọ̀rọ̀ yìí, a·gaʹpe, túmọ̀ sí ìfẹ́ tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan, tó jẹ́ pé ìlànà ló ń darí rẹ̀ tàbí pé ìlànà ló ń tọ́ ọ. Ìwé kan sọ pé: “Ìfẹ́ agape ṣeé darí nítorí kì í kàn án ṣe ìmọ̀lára lásán bí kò ṣe ohun téèyàn dìídì pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ láti ṣe tó sì wá ṣe é.” Nítorí pé a ti jogún ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan, a nílò ìránnilétí láti lè máa fi ìfẹ́ hàn síra wa, ká sì máa ṣe èyí láwọn ọ̀nà tí ìlànà Ọlọ́run ní ká gbà fi hàn.—Jẹ́nẹ́sísì 8:21; Róòmù 5:12.

4 Èyí kò wá túmọ̀ sí pé a fẹ́ nífẹ̀ẹ́ ara wa torí pé wọ́n ṣáà ti ní ka ṣe bẹ́ẹ̀ o. Ìfẹ́ A·gaʹpe kì í ṣe ìfẹ́ tí kò ní ọ̀yàyà tàbí tí kì í fọ̀rọ̀ rora ẹ̀ wò. Pétérù sọ pé a gbọ́dọ̀ ‘ní ìfẹ́ gbígbóná janjan [ní ṣáńgílítí, “tó ń ràn”] fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.’a (Kingdom Interlinear) Àmọ́ ṣá o, ìrú ìfẹ́ yìí ń béèrè ìsapá. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a pè ní “gbígbóná janjan,” ó sọ pé: “Ó gbé èrò asáré ìje kan wá síni lọ́kàn, ẹni tó jẹ́ pé ó ń ran gbogbo iṣan bó ti ń lo ìwọ̀nba okun tó kù lára rẹ̀ láti dé ìparí eré ìje náà.”

5 Ìfẹ́ wa nígbà náà kò gbọ́dọ̀ mọ sí ṣíṣe kìkì ohun tó bá ṣáà ti rọ̀ wá lọ́rùn tàbí ká fi mọ sọ́dọ̀ kìkì àwọn èèyàn díẹ̀ péré tá a fẹ́. Ìfẹ́ Kristẹni ń béèrè pé ká fi í hàn kódà nígbà tó bá ṣòro láti ṣe bẹ́ẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 6:11-13) Ó ṣe kedere pé, irú ìfẹ́ yìí jẹ́ ohun tó pọn dandan pé ká ní ká sì ṣiṣẹ́ lé lórí, gẹ́gẹ́ bí asáré ìje kan ṣe gbọ́dọ̀ máa gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kó sì máa ṣakitiyan láti túbọ̀ já fáfá. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní ìrú ìfẹ́ yìí fún ara wa. Kí nìdí? Ó kéré tán, ìdí mẹ́ta pàtàkì ló fi yẹ ká ní irú ìfẹ́ yìí

Kí Nìdí Tá A Fi Ní Láti Nífẹ̀ẹ́ Ara Wa?

6 Àkọ́kọ́, “nítorí pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìfẹ́ ti wá.” (1 Jòhánù 4:7) Jèhófà, ẹni tó jẹ́ orísun ànímọ́ fífanimọ́ra yìí, ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Nípa èyí ni a fi ìfẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn tiwa, nítorí Ọlọ́run rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde sínú ayé kí a lè jèrè ìyè nípasẹ̀ rẹ̀.” (1 Jòhánù 4:9) Ọlọ́run “rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo jáde” ní ti pé Ọmọ yìí di èèyàn, ó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ láyé ó sì kú lórí igi oró—gbogbo èyí sì ṣẹlẹ̀ “kí a lè jèrè ìyè.” Ìhà wo ló yẹ ká kọ sí ìfẹ́ gíga jù lọ tí Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí? Jòhánù sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 4:11) Ṣàkíyèsí pé ohun tí Jòhánù kọ ni pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa”—kì í ṣe ìwọ nìkan àmọ́ àwa. Kókó náà ṣe kedere, ìyẹn ni pé: Bí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa, nígbà náà, ó yẹ káwa náà nífẹ̀ẹ́ wọn.

7 Èkejì, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa gidigidi nísinsìnyí ká bàa lè nawọ́ ìrànwọ́ sáwọn arákùnrin wa tó wà nínú àìní nítorí “òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” (1 Pétérù 4:7) “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Ipò àwọn nǹkan nínú ayé, àjálù àti àtakò ń fa ìnira bá wa. Lábẹ́ àwọn ipò tí kò bára dé, ó pọn dandan ká túbọ̀ sún mọ́ ara wa ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ìfẹ́ gbígbóná janjan ni yóò so wá pọ̀ lọ́nà lílágbára tí yóò sì sún wa láti ní ‘aájò fún ara wa.’—1 Kọ́ríńtì 12:25, 26.

8 Ẹ̀kẹta, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa nítorí pé a ò fẹ́ “fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù” kó rí wa mú. (Éfésù 4:27) Sátánì máa ń yára lo àìpé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, ìyẹn kùdìẹ̀-kudiẹ wọn, àléébù wọn àti àṣìṣe wọn, gẹ́gẹ́ bí ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wa. Ṣé àá wá tìtorí ọ̀rọ̀ tẹ́nì kan ò ronú dáadáa kó tó sọ tàbí ohun àìdáa tẹ́nì kan ṣe sí wa ká má lọ sípàdé mọ́? (Òwe 12:18) A ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ bá a bá ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara wa! Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká lè máa wà ní àlàáfíà ká sì máa fi ìṣọ̀kan sin Jèhófà “ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—Sefanáyà 3:9.

Bó O Ṣe Lè Fi Hàn Pé O Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ẹlòmíràn

9 Fífi ìfẹ́ hàn gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ látinú ilé. Jésù sọ pé ìfẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn òun tòótọ́ ní fún ara wọn la óò fi dá wọn mọ̀. (Jòhánù 13:34, 35) Kì í ṣe inú ìjọ nìkan ló yẹ kí ìfẹ́ ti hàn kedere, ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ìdílé pẹ̀lú, ìyẹn láàárín tọkọtaya àti láàárín òbí pẹ̀lú ọmọ. Kò tó láti mọ̀ nínú wa pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa; a gbọ́dọ̀ fi hàn láwọn ọ̀nà tó dára.

10 Ọ̀nà wo ni tọkọtaya lè gbà fi ìfẹ́ hàn síra wọn? Ọkọ tó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ dénúdénú máa ń jẹ́ kí aya rẹ̀ mọ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, ní gbangba àti ní ìkọ̀kọ̀, pé òun mọyì rẹ̀ gan-an. Á máa bu iyì tirẹ̀ fún un á sì máa gba èrò rẹ̀, ojú ìwòye rẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára rẹ̀ rò. (1 Pétérù 3:7) Kò ní máa fi ọ̀ràn ìyàwó rẹ̀ ṣeré, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti bójú tó àwọn ohun tó nílò nípa tara, nípa tẹ̀mí àti ní ti ìmí ẹ̀dùn. (Éfésù 5:25, 28) Aya tó bá nífẹ̀ẹ́ ọkọ rẹ̀ lóòótọ́ máa ń fún ọkọ rẹ̀ ní “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀,” kódà bí kò bá tiẹ̀ ṣe tó bó ṣe yẹ lójú ẹ̀ nígbà míì. (Éfésù 5:22, 33) Ó máa ń ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn ó sì máa ń tẹrí ba fún un, kò ní máa ní kí ọkọ òun ṣe nǹkan tí agbára rẹ̀ kò gbé, àmọ́ á máa bá a fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n lè jọ máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18; Mátíù 6:33.

11 Ẹ̀yin òbí, báwo lẹ ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sáwọn ọmọ yín? Gbígbọ́ tẹ́ ẹ̀ ń gbọ́ bùkátà wọn tinútinú jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ nífẹ̀ẹ́ wọn. (1 Tímótì 5:8) Àmọ́ ohun táwọn ọmọ nílò ju oúnjẹ, aṣọ àti ibi tí wọ́n máa gbé lọ. Bí wọn yóò bá dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bí wọ́n bá dàgbà, kí wọ́n sì máa sìn ín, ẹ óò ní láti kọ́ wọn nípa tẹ̀mí. (Òwe 22:6) Ìyẹn túmọ̀ sí pé ẹ ó ṣètò àkókò gẹ́g̣ẹ́ bí ìdílé láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti láti máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. (Diutarónómì 6:4-7) Ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí déédéé ń béèrè ìfara-ẹni-rúbọ tó ga, pàápàá jù lọ láwọn àkókò líle koko yìí. Àníyàn rẹ àti ìsapá rẹ láti bójú tó ohun táwọn ọmọ rẹ nílò nípa tẹ̀mí jẹ́ ọ̀nà kan tó ò ń gbà fi ìfẹ́ rẹ hàn sí wọn, nítorí pé ńṣe lò ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé bó ṣe máa dára fún wọn títí ayé jẹ ọ́ lọ́kàn.—Jòhánù 17:3.

12 Ó tún ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí fi ìfẹ́ hàn nípa bíbójútó ohun tí àwọn ọmọ wọn nílò ní ti ìmí ẹ̀dùn. Àwọn ọmọdé ò nírìírí; gẹ́gẹ́ bí ọmọdé, ohun tí wọ́n ń fẹ́ ni pé kó o máa fi dá wọn lójú nígbà gbogbo pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Máa sọ fún wọn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn kó o sì máa kó wọn mọ́ra gan-an, nítorí pé irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń fi dá wọn lójú pé ẹni téèyàn ń nífẹ̀ẹ́ ni wọ́n àti pé ẹni iyì ni wọ́n. Máa yìn wọ́n tọkàntọkàn, nítorí pé ìyẹn ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ò ń rí àwọn ìsapá wọn o sì mọyì rẹ̀. Bá wọn wí tìfẹ́tìfẹ́, nítorí pé irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ń fi yé wọn pé ò ń ronú nípa irú èèyàn tí wọ́n máa dà lọ́jọ́ ọ̀la. (Éfésù 6:4) Irú gbogbo àwọn ọ̀nà bíbójúmu báwọ̀nyí láti fi ìfẹ́ hàn á jẹ́ kí ìdílé yín jẹ́ ìdílé aláyọ̀, kó ṣọ̀kan, kó sì wà nípò tó dára láti lè kojú àwọn wàhálà ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.

13 Ìfẹ́ ń jẹ́ ká lè gbójú fo àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn dá. Rántí pé nígbà tí Pétérù ń gba àwọn òǹkàwé rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n “ní ìfẹ́ gbígbóná janjan fún ara [wọn] lẹ́nì kìíní-kejì,” ó sọ ìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì, ó ní: “Nítorí ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pétérù 4:8) Láti “bo” ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ká “bo” àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńlá mọ́lẹ̀ o. Ohun tó bójú mu ni pé ká jẹ́ kí àwọn tá a fa ẹrù iṣẹ́ lé lọ́wọ́ nínú ìjọ mọ̀ kí wọ́n sì bójú tó o. (Léfítíkù 5:1; Òwe 29:24) Kò ní fìfẹ́ hàn rárá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní bá Ìwé Mímọ́ mu láti jẹ́ kí àwọn tó ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì máa bá a nìṣó láti máa ṣàkóbá fún àwọn tí kò mọ̀kan tàbí kí wọ́n máa ṣèpalára fún wọn.—1 Kọ́ríńtì 5:9-13.

14 Lọ́pọ̀ ìgbà jù lọ, àwọn àṣìṣe àtàwọn àléébù àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kì í tó nǹkan. Gbogbo wa là ń kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ tàbí nínú ìṣe nígbà míì, tá a máa ń ṣe ohun táwọn mìíràn kò retí tàbí ká tiẹ̀ ṣe ohun tó máa dùn wọ́n. (Jákọ́bù 3:2) Ǹjẹ́ ó yẹ ká yára máa ro àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn káàkiri? Ńṣe nirú nǹkan bẹ́ẹ̀ á wulẹ̀ dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìjọ. (Éfésù 4:1-3) Bí ìfẹ́ bá ń darí wa, a ò ní máa “gbé àléébù” àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa “sáyé.” (Sáàmù 50:20) Bí sìmẹ́ǹtì àti ọ̀dà ṣe máa ń bo àwọn ibi tí kò dára lára ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ṣe máa ń bo àìpé àwọn ẹlòmíràn mọ́lẹ̀.—Òwe 17:9.

15 Ìfẹ́ yóò sún wa láti dìde ìrànwọ́ fáwọn tó wà nípò àìní gan-an. Bí ipò àwọn nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, àwọn ìgbà mìíràn lè wà táwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa máa nílò ìrànlọ́wọ́ ní ti pé ká fún wọn ní nǹkan tàbí ká lọ ṣèrànwọ́ fún wọn. (1 Jòhánù 3:17, 18) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ẹnì kan nínú ìjọ wa ti dẹni tí nǹkan ò lọ déédéé fún mọ́ tàbí pé iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, bóyá a lè fi àwọn nǹkan kan ṣèrànwọ́ díẹ̀ bí ipò wa bá ṣe yọ̀ǹda sí. (Òwe 3:27, 28; Jákọ́bù 2:14-17) Ǹjẹ́ ilé opó kan tó ti dàgbà nílò àtúnṣe? Bóyá a lè lo ìdánúṣe fúnra wa láti bá a ṣe nǹkan kan sí i.—Jákọ́bù 1:27.

16 Fífìfẹ́ hàn sí àwọn ẹlòmíràn kò mọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé lágbègbè wa o. Nígbà míì a lè gbọ́ ìròyìn nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run láwọn ilẹ̀ mìíràn tí ìjì líle, ìsẹ̀lẹ̀ tàbí rúkèrúdò ti kó ìṣòro bá. Wọ́n lè nílò oúnjẹ, aṣọ àtàwọn nǹkan míì lójú méjèèjì. Wọn lè jẹ́ ẹ̀yà tàbí ìran mìíràn, ìyẹn ò ní ká má ràn wọ́n lọ́wọ́. A “ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pétérù 2:17) Nítorí náà, bíi tàwọn ìjọ ọ̀rúndún kìíní, a fẹ́ láti hara gàgà láti kọ́wọ́ ti ètò ìpèsè ìrànwọ́ tá a bá ṣe lẹ́yìn. (Ìṣe 11:27-30; Róòmù 15:26) Tá a bá fi ìfẹ́ hàn ní gbogbo irú àwọn ọ̀nà bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń mú kí ìdè tó so wá pọ̀ ṣọ̀kan láwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí túbọ̀ lágbára sí i.—Kólósè 3:14.

17 Ìfẹ́ ń sún wa láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn. Wo àpẹẹrẹ ti Jésù. Kí ló mú kó wàásù kó sì tún kọ́ni? “Àánú” àwọn èèyàn ló ṣe é nítorí pé wọ́n tòṣì nípa tẹ̀mí. (Máàkù 6:34) Àwọn olùṣọ́ àgùntàn ìsìn èké pa wọ́n tì wọ́n sì tún ṣì wọ́n lọ́nà, ìyẹn àwọn tó yẹ kó kọ́ wọn ní òtítọ́ tẹ̀mí kí wọ́n sì fún wọn ní ìrètí. Nítorí náà, ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ti ọkàn wá àti ìyọ́nú ló sún Jésù tó fi fi “ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run” tù wọ́n nínú.—Lúùkù 4:16-21, 43.

18 Lónìí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti dẹni tá a pa tì nípa tẹ̀mí, tí wọ́n ti kó ṣìnà tí wọn ò sì ní ìrètí kankan. Bíi ti Jésù, báwa náà bá ní ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn nípa bí àìní tẹ̀mí ṣe ń bá àwọn tí kò tíì mọ Ọlọ́run tòótọ́ náà fínra, ìfẹ́ àti ìyọ́nú á sún wa láti sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún wọn. (Mátíù 6:9, 10; 24:14) Pẹ̀lú bó ṣe jẹ́ pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló kù, ó ti di ohun kánjúkánjú gan-an báyìí láti wàásù ìhìn ìgbàlà náà.—1 Tímótì 4:16.

“Òpin Ohun Gbogbo Ti Sún Mọ́lé”

19 Rántí pé Pétérù fi gbólóhùn kan ṣáájú ìmọ̀ràn rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ó sọ pé: “Òpin ohun gbogbo ti sún mọ́lé.” (1 Pétérù 4:7) Láìpẹ́, ayé tuntun òdodo Ọlọ́run yóò rọ́pò ayé búburú yìí. (2 Peter 3:13) Nítorí náà, ìsinsìnyí kì í ṣe àkókò láti jáfara. Jésù kìlọ̀ pé: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri àti àwọn àníyàn ìgbésí ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yóò sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn.”—Lúùkù 21:34, 35.

20 Ní gbogbo ọ̀nà, nígbà náà, ẹ jẹ́ ká “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà,” ká máa wà lójúfò pé àkókò ti lọ tán. (Mátíù 24:42) Ẹ jẹ́ ká máa ṣọ́ra ká má ṣe gba èyíkéyìí nínú àwọn ìdẹwò Sátánì tó lè pín ọkàn wa níyà láyè. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba ayé aláìnífẹ̀ẹ́ yìí láyè kó ṣèdíwọ́ fún wa láti fìfẹ́ hàn sáwọn ẹlòmíràn. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ ká túbọ̀ máa sún mọ́ Ọlọ́run òtítọ́ náà, Jèhófà, ẹni tí Ìjọba rẹ̀ látọwọ́ Mèsáyà máa tó mú ète rẹ̀ ológo fún ilẹ̀ ayé yìí ṣẹ.—Ìṣípayá 21:4, 5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní 1 Pétérù 4:8, àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì mìíràn sọ pé a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wa “tinútinú,” “jinlẹ̀jinlẹ̀,” tàbí “tọkàntọkàn.”

ÌBÉÈRÈ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́

• Ìmọ̀ràn wo ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nígbà tó ń fi wọ́n sílẹ̀ láyé, kí ló sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ tó sọ yé Pétérù? (Ìpínrọ̀ 1 àti 2)

• Kí ló ń jẹ́ “ìfẹ́ gbígbóná janjan”? (Ìpínrọ̀ 3 sí 5)

• Kí nìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ara wa? (Ìpínrọ̀ 6 sí 8)

• Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn? (Ìpínrọ̀ 9 sí 18)

• Kí nìdí tí àkókò yìí kì í fi í ṣe àkókò láti jafara, kí ló sì yẹ ká pinnu pé a óò ṣe? (Ìpínrọ̀ 19 sí 20)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ìdílé tó bá ṣọ̀kan yóò wà nípò tó dára láti lè kojú àwọn wàhálà ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Ìfẹ́ ń sún wa láti dìde ìrànwọ́ fún àwọn tó wà nípò àìní gan-an

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Sísọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn jẹ́ ọ̀nà kan tá à ń gbà fi ìfẹ́ hàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́