Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì
Bíbélì láwọn ìsọfúnni tó ṣe pàtàkì tó yẹ kó o mọ̀.
• Ó ṣàlàyé ohun tí Ẹlẹ́dàá sọ nípa ète ìgbésí ayé.
• Ó pèsè ìmọ̀ràn tó dára jù lọ nípa béèyàn ṣe lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé ìsinsìnyí.
• Ó sọ ohun tá a ó ṣe láti lè jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà nígbà tí gbogbo wa bá dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.
Ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí à ń ṣe déédéé yíká ayé.
Àwọn ètò wà tó máa bá ipò rẹ mu. A KÌ Í BÉÈRÈ OWÓ.
Kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó bá sún mọ́ ọ jù lọ nínú àwọn tó wà nísàlẹ̀ yìí tàbí kó o béèrè lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà èyíkéyìí ládùúgbò rẹ