Walaaye Titilae Ninu Paradise Lori Ilẹ Ayé
Ọlọrun ṣeleri ìyè ayérayé fun awọn wọnni tí wọn bọlá fún un. “Olododo ni yoo jogún ayé, yoo sì maa gbé inú rẹ̀ láéláé,” ni Ọ̀rọ̀ rẹ mu un da wa lójú.—Saamu 37:29.
Síbẹ̀, lati kà ọ mọ́ awọn “olododo,” iwọ nílò lati ṣe pupọ sii ju kí ó mọ ìsọfúnni nipa ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan. Iwọ nilati tẹsiwaju ninu ìmọ̀ nipa Ọlọrun. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo layọ lati ràn ọ lọ́wọ́, bi iwọ ko ba tii maa gba iranlọwọ naa ṣaaju isinsinyi. Wulẹ kọwe si Watch Tower ni lilo àdírẹ́sì biba a mu tí a tò lẹ́sẹẹsẹ si isalẹ yii, ni bibeere fun isọfunni siwaju sii tabi pe ki ọkan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wa si ile rẹ ki o si maa kẹkọọ Bibeli deedee pẹlu rẹ lọ́fẹ̀ẹ́.