Fífi Ìwé Lọni
‘Dídé’ Ijọba Ọlọrun yoo tumọsi ohun pupọ fun araye ju iṣẹlẹ eyikeyii miiran lọ ninu itan. Idi niyẹn tí gbogbo wa fi gbọdọ ní imọ tí ó kúnrẹ́rẹ́ nipa Ijọba naa.
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo layọ lati jiroro akori pataki yii pẹlu rẹ, lọ́fẹ̀ẹ́, gẹgẹ bi idile tabi lẹnikọọkan. Sá ti kọwe si Watch Tower tí ó wà ní adirẹsi ti o baa mu lara eyi ti a tolẹṣẹẹsẹ si oju-ewe tí ó tẹle e ninu iwe yii, ki o sì beere fun irú ijiroro Bibeli bẹẹ. A o ṣeto fun Ẹlẹ́rìí kan tí ó tootun lati késí ọ ki ó sì ràn ọ lọwọ lati dé ori òye ti o ṣe kedere nipa Ijọba naa, ni lílò fun apẹẹrẹ, awọn Ibeere fun Ijiroro ninu iwe yii.
Araadọta ọkẹ awọn eniyan ní apa ibi gbogbo lori ilẹ̀-ayé ti jẹ anfaani ninu iṣẹ-isin ọ̀fẹ́ yii. Iwọ, pẹlu, lè rí awọn idahun tí ń tẹnilọrun gbà tí yoo ràn ọ lọwọ lati gbé igbagbọ ró ninu Ijọba Ọlọrun.