ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ba ojú ìwé 30
  • Ìwé Kan Tí Ó Wà Fún Ọ Ni Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwé Kan Tí Ó Wà Fún Ọ Ni Bí?
  • Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí A Ṣe Lè Jàǹfààní Jù Lọ
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ọ̀nà Méje Téèyàn Lè Gbà Jàǹfààní Látinú Bíbélì Kíkà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ṣé Bíbélì Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ìwé kan tí ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn
ba ojú ìwé 30

Ìwé Kan Tí Ó Wà Fún Ọ Ni Bí?

Sólómọ́nì sọ ní nǹkan bí 3,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Nínú ṣíṣe ìwé púpọ̀, òpin kò sí.” (Oníwàásù 12:12) Wẹ́kú ni àkíyèsí yẹn bá a mu lónìí bíi ti àtẹ̀yìnwá. Ní àfikún sí àwọn ìwé gidi tí a kọ lọ́nà títayọ, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé tuntun ni a ń tẹ̀ lọ́dọọdún. Nígbà tí ìwé púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí o lè ṣe àṣàyàn láti inú wọn wà, kí ni ìdí tí ó fi yẹ kí o ka Bíbélì?

Ọ̀PỌ̀ ènìyàn ń kàwé bóyá fún ìnàjú tàbí láti gba ìsọfúnni, tàbí bóyá fún ìdí méjèèjì. Bíbélì kíkà lè rí bákan náà. Ó ṣeé kà fún ìmúsunwọ̀n sí i ẹni, kódà fún ìdárayá pàápàá. Ṣùgbọ́n Bíbélì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó jẹ́ orísun ìmọ̀ aláìlẹ́gbẹ́.—Oníwàásù 12:9, 10.

Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tí ẹ̀dá ènìyàn ti ń ronú lé lórí láti ìgbà pípẹ́—àwọn ìbéèrè nípa àtẹ̀yìnwá wa, ìsinsìnyí wa, àti ọjọ́ ọ̀la wa. Ọ̀pọ̀ ń ṣe kàyéf ì pé: Ibo ni a ti wá? Kí ni ète ìgbésí ayé? Báwo ni a ṣe lè rí ayọ̀ ní ìgbésí ayé? Ìwàláàyè yóò ha máa wà títí lọ lórí ilẹ̀ ayé bí? Kí ni ọjọ́ ọ̀la ní nípamọ̀ fún wa?

Àpapọ̀ agbára tí gbogbo ẹ̀rí tí a mú jáde níhìn-ín ní f ìdí rẹ̀ múlẹ̀ kedere pé Bíbélì péye ó sì ṣeé gbà gbọ́. A ti ṣe àgbéyẹ̀wò nípa bí ìmọ̀ràn rẹ̀ wíwúlò ṣe lè ṣèrànwọ́ fún wa láti gbé ìgbé ayé tí ó nítumọ̀ tí ó sì láyọ̀ lóde òní. Níwọ̀n bí àwọn ìdáhùn rẹ̀ nípa ìsinsìnyí ti tẹ́ni lọ́rùn, ó dájú pé àwọn ìdáhùn rẹ̀ nípa àtẹ̀yìnwá àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la yẹ fún àgbéyẹ̀wò àfẹ̀sọ̀ṣe wa.

Bí A Ṣe Lè Jàǹfààní Jù Lọ

Ọ̀pọ̀ ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì kìkì láti dúró nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn apá kan nínú rẹ̀ ṣòro lóye fún wọn. Bí ìyẹn bá ti jẹ́ ìrírí tìrẹ, àwọn nǹkan kan wà tí ó lè ṣèrànwọ́.

Wá ẹ̀dà ìtumọ̀ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tí a fi èdè tí ó bóde mu túmọ̀, irú bí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.a Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ kíkà tiwọn látorí àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere nípa ìgbésí ayé Jésù, ẹni tí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ ọlọ́gbọ́n, bí irú àwọn tí a rí nínú Ìwàásù Lórí Òkè, ń ṣàgbéyọ mímọ̀ tí ó mọ àbùdá ẹ̀dá ènìyàn dáadáa tí ó sì ṣètòlẹ́sẹẹsẹ bí a ṣe lè mú kí ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbésí ayé wa sunwọ̀n sí i.—Wo Mátíù orí 5 sí 7.

Ní àfikún sí wíwulẹ̀ ka Bíbélì, lílo ọ̀nà ti ṣíṣèkẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ lè fúnni ní ìsọfúnni gidigidi. Ohun tí èyí ní nínú ni fífẹ̀sọ̀ ṣe ìwádìí lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó ẹ̀kọ́ kan pàtó. Ẹnu lè yà ọ́ nígbà tí o bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ ní ti gidi nípa irú àwọn kókó ọ̀rọ̀ bí ọkàn, ọ̀run, ilẹ̀ ayé, ìwàláàyè, àti ikú, títí kan Ìjọba Ọlọ́run—ohun tí ó jẹ́ àti ohun tí yóò gbé ṣe.b Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì, èyí tí wọ́n ń pèsè lọ́fẹ̀ẹ́. Ìwọ lè ṣèwádìí nípa èyí nípa kíkọ̀wé sí àwọn òǹtẹ̀wé, ní lílo àdírẹ́sì tí ó bá a mu wẹ́kú lára ti ojú ìwé 2.

Lẹ́yìn ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti dé ìparí èrò náà pé Bíbélì wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí Ìwé Mímọ́ pè ní “Jèhófà.” (Sáàmù 83:18) Ó ṣeé ṣe kí ó máà dá ọ lójú pé orísun Bíbélì jẹ́ àtọ̀runwá. Ṣùgbọ́n èé ṣe tí o kò ṣàyẹ̀wò rẹ̀ fúnra rẹ? A ní ìdánilójú pé lẹ́yìn ìgbésẹ̀ ti kíkẹ́kọ̀ọ́, ṣíṣàṣàrò, àti bóyá níní ìrírí ìníyelórí ìwúlò ọgbọ́n rẹ̀ tí kò mọ sí sáà kan fúnra rẹ, ìwọ yóò wá ní èrò náà pé Bíbélì jẹ́ ìwé kan tí ó wà fún gbogbo ènìyàn lóòótọ́, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ—pé ó wà fún ọ.

[Àwọ̀n àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

b Ìwé kan tí ó ti ran ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́ nínú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí kókó ẹ̀kọ́ Bíbélì ni Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́