ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w96 5/15 ojú ìwé 15-20
  • Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Àǹfààní Pípẹ́ Títí
  • Ó Ṣe Pàtàkì fún Gbogbo Wa
  • Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Sókè
  • Ọ̀nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Oníkókó-Ọ̀rọ̀
  • Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Nígbà Gbogbo
  • Jíjàǹfààní Láti Inú Bibeli Kíkà Lójoojúmọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Fi Ara Rẹ fún Ìwé Kíkà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Máa Ṣe Bí Ọba
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Tẹ́wọ́gba Bibeli Nítorí Ohun Tí Ó Jẹ́ Nítòótọ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
w96 5/15 ojú ìwé 15-20

Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Kí O Sì Máa Ṣiṣẹ́ Sìn ín ní Òtítọ́

“Oluwa, kọ́ mi ní ọ̀nà rẹ; èmi óò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.”—ORIN DAFIDI 86:11.

1. Ní ti gidi, kí ni ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn yìí sọ nípa òtítọ́?

JEHOFA ń rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ jáde. (Orin Dafidi 43:3) Ó tún ń fún wa ní agbára láti ka Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ìwé ìròyìn yìí—July 1879—wí pé: “Òtítọ́ dà bí òdòdó kékeré nínú aginjù ìgbésí ayé, tí àwọn èpò èké títutù yọ̀yọ̀ yí ká, tí wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ fún pa. Bí ọwọ́ rẹ yóò bá tẹ̀ ẹ́, o gbọ́dọ̀ wà lójúfò. Bí ìwọ yóò bá rí ẹwà rẹ̀, o gbọ́dọ̀ rọ́ àwọn èpò èké àti igi ẹ̀gún ẹ̀tanú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Bí ìwọ bá fẹ́ rí i já, o ní láti lóṣòó kí o tó lè rí i já. Má ṣe jẹ́ kí òdòdó kan nípa òtítọ́ tẹ́ ọ lọ́rùn. Bí ó bá jẹ́ pé ọ̀kan ti tó ni, kì bá tún sí òmíràn mọ́. Túbọ̀ máa kó o jọ, túbọ̀ máa wá púpọ̀ sí i.” Kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye, kí a sì rìn nínú òtítọ́ rẹ̀.—Orin Dafidi 86:11.

2. Kí ni ó yọrí sí, nígbà tí Esra àti àwọn mìíràn ka Òfin Ọlọrun sí etígbọ̀ọ́ àwọn Júù ní Jerusalemu ìgbàanì?

2 Lẹ́yìn tí a tún odi Jerusalemu kọ́ ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa, àlùfáà Esra àti àwọn mìíràn ka Òfin Ọlọrun sí etígbọ̀ọ́ àwọn Júù. Àjọ Àgọ́ tí ń kún fún ìdùnnú, ìjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, àti paríparí rẹ̀, “májẹ̀mú tí ó dájú,” sì tẹ̀ lé e. (Nehemiah 8:1–9:38) A kà pé: “Wọ́n kà nínú ìwé òfin Ọlọrun ketekete, wọ́n túmọ̀ rẹ̀, wọ́n sì mú kí ìwé kíkà náà yé wọn.” (Nehemiah 8:8) Àwọn kan sọ pé àwọn Júù kò gbọ́ èdè Heberu dáadáa, wọ́n sì ń tún ọ̀rọ̀ náà sọ ní èdè Aramaiki ni. Ṣùgbọ́n ẹsẹ náà kò fi wíwulẹ̀ mú kí àwọn ọ̀rọ̀ èdè ṣe kedere hàn. Esra àti àwọn mìíràn làdí Òfin náà kí àwọn ènìyàn baà lè lóye àwọn ìlànà rẹ̀, kí wọ́n sì fi wọ́n sílò. Àwọn ìtẹ̀jáde Kristian àti ìpàdé tún ń ṣèrànwọ́ láti ‘jẹ́ kí’ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ‘yéni yékéyéké.’ Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn alàgbà tí a yàn sípò, tí wọ́n “tóótun lati kọ́ni.”—1 Timoteu 3:1, 2; 2 Timoteu 2:24.

Àwọn Àǹfààní Pípẹ́ Títí

3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tí a rí nínú Bibeli kíkà?

3 Nígbà tí àwọn ìdílé Kristian bá ń ka Bibeli pa pọ̀, wọ́n lè jàǹfààní pípẹ́ títí. Wọn óò dojúlùmọ̀ pẹ̀lú òfin Ọlọrun, wọn óò sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa àwọn èrò ìgbàgbọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀, àti àwọn kókó ẹ̀kọ́ mìíràn. Lẹ́yìn kíka apá kan nínú Bibeli, olórí ìdílé lè béèrè pé: Báwo ni èyí ṣe kàn wá? Ọ̀nà wo ni èyí gbà ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ mìíràn nínú Bibeli? Báwo ni a ṣe lè lo àwọn kókó yìí nínú wíwàásù ìhìn rere náà? Ìdílé kan ń jèrè òye inú púpọ̀ sí i nígbà tí wọ́n bá ń ka Bibeli, bí wọ́n bá ń ṣe ìwádìí nípa lílo ìwé Watch Tower Publications Index tàbí àwọn atọ́ka mìíràn. A lè jàǹfààní nípa lílo àwọn ìdìpọ̀ méjì ìwé gbédègbéyọ̀ náà, Insight on the Scriptures.

4. Báwo ni Joṣua ṣe ní láti fi ìtọ́ni tí a kọ sílẹ̀ nínú Joṣua 1:8 sílò?

4 Àwọn ìlànà tí a fà yọ láti inú Ìwé Mímọ́ lè darí wa nínú ìgbésí ayé. Ní àfikún sí i, kíka ‘ìwé mímọ́’ àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ‘lè sọ wa di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà.’ (2 Timoteu 3:15) Bí a bá jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun darí wa, a óò máa bá a nìṣó ní rírìn nínú òtítọ́ rẹ̀, ọwọ́ wa yóò sì tẹ ìfẹ́ ọkàn òdodo wa. (Orin Dafidi 26:3; 119:130) Bí ó ti wù kí ó rí, a ní láti wá òye, gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀lé Mose, Joṣua, ti ṣe. ‘Ìwé òfin náà’ kò ní láti kúrò ní ẹnu rẹ̀, ó sì ní láti máa kà á ní ọ̀sán àti ní òru. (Joṣua 1:8) Kí ‘ìwé òfin náà’ má ṣe kúrò ní ẹnu rẹ̀ túmọ̀ sí pé Joṣua kò gbọdọ̀ jáwọ́ nínú sísọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa àwọn ohun tí ń lani lóye tí ìwé náà sọ. Kíka Òfin náà ní ọ̀sán àti ní òru túmọ̀ sí pé, Joṣua ní láti ṣàṣàrò lórí rẹ̀, kí ó kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Lọ́nà kan náà, aposteli Paulu rọ Timoteu láti “sinmẹ̀dọ̀ ronú”—ṣàṣàrò lórí—ìwà, iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bíi Kristian alàgbà kan, Timoteu ní láti ṣọ́ra gan-an kí ìgbésí ayé rẹ̀ lè jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ, kí ó sì lè kọ́ni ní òtítọ́ Ìwé Mímọ́.—1 Timoteu 4:15.

5. Kí ni a nílò bí a bá ní láti rí òtítọ́ Ọlọrun?

5 Òtítọ́ Ọlọrun jẹ́ ìṣúra ṣíṣeyebíye. Ṣíṣàwárí rẹ̀ ń béèrè wíwalẹ̀, títẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ìwádìí nínú Ìwé Mímọ́. Kìkì ìgbà tí a bá fi ara wa hàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tí Atóbilọ́lá Olùfúnninítọ̀ọ́ni náà ń kọ́, ni a tó lè jèrè ọgbọ́n, tí a sì lè lóye ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ Jehofa. (Owe 1:7; Isaiah 30:20, 21) Àmọ́ ṣáá o, a ní láti fi ẹ̀rí ohun gbogbo hàn lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. (1 Peteru 2:1, 2) Àwọn Júù ní Berea “ní ọkàn-rere ju awọn ti Tessalonika lọ, nitori pé wọ́n gba ọ̀rọ̀ naa pẹlu ìháragàgà ńláǹlà ninu èrò-inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ níti pé bóyá nǹkan wọnyi [tí Paulu sọ] rí bẹ́ẹ̀.” A gbóríyìn fún àwọn ará Berea dípò bíbá wọn wí fún ohun tí wọ́n ṣe.—Ìṣe 17:10, 11.

6. Èé ṣe tí Jesu fi lè fi hàn pé kò ṣe àwọn Júù kan ní àǹfààní kankan láti ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́?

6 Jesu wí fún àwọn Júù kan pé: “Ẹ̀yin ń wá inú awọn Ìwé Mímọ́ káàkiri, nitori ẹ rò pé nípasẹ̀ wọn ẹ óò ní ìyè àìnípẹ̀kun; iwọnyi gan-an sì ni ó ń jẹ́rìí nipa mi. Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ kò sì fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi kí ẹ lè ní ìyè.” (Johannu 5:39, 40) Wọ́n ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú èrò rere—kí èyí baà lè darí wọn sí ìyè. Ní tòótọ́, Ìwé Mímọ́ ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Messia nínú tí ó tọ́ka sí Jesu gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti rí ìyè. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kò tẹ́wọ́ gbà á. Nítorí náà, ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ kò ṣe wọ́n láǹfààní kankan.

7. Kí ni a nílò láti dàgbà nínú òye Bibeli, èé sì ti ṣe?

7 Láti lè dàgbà nínú òye Bibeli, a nílò ìdarí ẹ̀mí Ọlọrun, tàbí ipá agbékánkánṣiṣẹ́ rẹ̀. “Ẹ̀mí ń wá inú ohun gbogbo, àní awọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun pàápàá,” láti lè mú ìtumọ̀ wọn jáde. (1 Korinti 2:10) Àwọn Kristian ní Tessalonika ní láti “wádìí ohun gbogbo dájú” nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n gbọ́. (1 Tessalonika 5:20, 21) Nígbà tí Paulu kọ̀wé sí àwọn ará Tessalonika (ní nǹkan bí ọdún 50 Sànmánì Tiwa), kìkì apá tí a tí ì kọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ni Ìhìn Rere Matteu. Nítorí náà, àwọn ará Tessalonika àti Berea lè wádìí ohun gbogbo dájú, bóyá nípa yíyẹ ẹ̀dà ìtumọ̀ Septuagint èdè Gíríìkì ti Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu wò. Wọ́n ní láti ka Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni àwa náà pẹ̀lú.

Ó Ṣe Pàtàkì fún Gbogbo Wa

8. Èé ṣe tí àwọn alàgbà tí a yàn sípò fi ní láti ta yọ nínú ìmọ̀ Bibeli?

8 Àwọn alàgbà tí a yàn sípò ní láti ta yọ nínú ìmọ̀ Bibeli. Wọ́n gbọ́dọ̀ “tóótun lati kọ́ni,” wọ́n sì gbọ́dọ̀ “di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin.” Alábòójútó náà, Timoteu, ní láti “fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” (1 Timoteu 3:2; Titu 1:9; 2 Timoteu 2:15) Ìyá rẹ̀, Eunike, àti ìyá-ìyá rẹ̀ Loide ti kọ́ ọ ní ìwé mímọ́ láti ìgbà ọmọdé jòjòló, ní gbígbin ‘ìgbàgbọ́ tí kò ní àgàbàgebè’ sí i lọ́kàn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìgbàgbọ́ ni bàbá rẹ̀. (2 Timoteu 1:5; 3:15) Àwọn bàbá onígbàgbọ́ ní láti tọ́ àwọn ọmọ wọn dàgbà “ninu ìbáwí ati ìlànà èrò-orí Jehofa,” ní pàtàkì, àwọn alàgbà tí wọ́n jẹ́ bàbá gbọ́dọ̀ ní ‘àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́ tí wọn kò sí lábẹ́ ọ̀ràn ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè.’ (Efesu 6:4; Titu 1:6) Nítorí náà, láìka àyíká ipò wa sí, a ní láti fi ọwọ́ pàtàkì mú àìní náà láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, láti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ àti láti fi í sílò.

9. Èé ṣe ti a fi ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa?

9 A tún ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Paulu fẹ́ kí àwọn Kristian ní Tessalonika jíròrò ìmọ̀ràn rẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ara wọn. (1 Tessalonika 4:18) Láti mú kí òye wa nípa òtítọ́ túbọ̀ pọ̀ sí i, kò sí ọ̀nà míràn ju dídara pọ̀ mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ olùfarajìn pátápátá fún ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́. Òtítọ́ ni òwe náà pé: “Irin a máa pọ́n irin: bẹ́ẹ̀ ni ọkùnrin í pọ́n ojú ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Owe 27:17) Ohun èèlò irin lè dípẹtà bí a kò bá lò ó, tí a kò sì pọ́n ọn. Lọ́nà jíjọra, a ní láti máa pàdé pọ̀ déédéé, kí a sì máa pọ́n ara wa nípa ṣíṣàjọpín ìmọ̀ tí a ti jèrè nínú kíka Ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọrun, kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àti ṣíṣàṣàrò lé e lórí. (Heberu 10:24, 25) Ní àfikún sí i, ọ̀nà kan nìyí láti rí i dájú pé a ń jàǹfààní láti inú àwọn ìbùyẹ̀rì ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí.—Orin Dafidi 97:11; Owe 4:18.

10. Kí ni ó túmọ̀ sí láti rìn nínú òtítọ́?

10 Nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́, a lè gbàdúrà sí Ọlọrun lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú gẹ́gẹ́ bí onipsalmu náà ti ṣe pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde, kí wọn kí ó máa ṣe amọ̀nà mi.” (Orin Dafidi 43:3) Bí a bá fẹ́ láti ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọrun, a gbọ́dọ̀ rìn nínú òtítọ́ rẹ̀. (3 Johannu 3, 4) Èyí ní nínú títẹ̀ lé àwọn ohun àbéèrè-fún rẹ̀, kí a sì ṣiṣẹ́ sìn ín pẹ̀lú ìṣòtítọ́ àti òtítọ́ inú. (Orin Dafidi 25:4, 5; Johannu 4:23, 24) A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ sin Jehofa ní òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti ṣí i payá, tí a sì mú un ṣe kedere nínú ìtẹ̀jáde “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú.” (Matteu 24:45-47) Èyí ń béèrè fún ìmọ̀ pípéye nípa Ìwé Mímọ́. Nígbà náà, báwo ni a ṣe ní láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀? A ha ní láti bẹ̀rẹ̀ kíkà á láti Genesisi orí 1, ẹsẹ 1, ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀-lé jálẹ̀ àwọn ìwé 66 náà bí? Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo Kristian tí ó bá ní Bibeli lódindi ní èdè àbínibí rẹ̀ yẹ kí ó kà á láti Genesisi títí dé Ìṣípayá. Ète wa fún kíka Bibeli àti àwọn ìtẹ̀jáde Kristian yẹ kí ó jẹ́ láti mú òye wa nípa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ òtítọ́ Ìwé Mímọ́ tí Ọlọrun ń pèsè nípasẹ̀ ‘olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà pọ̀ sí i.

Máa Ka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Sókè

11, 12. Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní láti ka Bibeli sókè ní àwọn ìpàdé?

11 A lè máa kàwé sínú, bí ó bá jẹ́ àwa nìkan. Ṣùgbọ́n, ní ìgbàanì, tí ẹnì kan bá ń dá kàwé, ó máa ń kà á sókè. Bí ìwẹ̀fà ará Etiopia ti ń lọ nínú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ajíhìnrere náà, Filippi, gbọ́ ọ nígbà náà tí ó ń kà láti inú àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah. (Ìṣe 8:27-30) Ọ̀rọ̀ Heberu náà tí a túmọ̀ sí “kà” ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ túmọ̀ sí “pè.” Nítorí náà, àwọn tí kò lè kàwé sínú, kí wọ́n sì lóye ohun tí wọ́n ń kà, ni a kò ní láti kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá nígbà tí wọ́n bá ń pe ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan jáde. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a kọ sílẹ̀.

12 Ó ṣàǹfààní láti ka Bibeli sókè ní àwọn ìpàdé Kristian. Aposteli Paulu rọ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀, Timoteu, pé: “Máa bá a lọ ní fífi aápọn lo ara [rẹ] ninu ìwé kíkà ní gbangba, ninu ìgbaniníyànjú, ninu kíkọ́ni.” (1 Timoteu 4:13) Paulu sọ fún àwọn ará Kolosse pé: “Nígbà tí ẹ bá sì ti ka lẹ́tà yii láàárín yín, ẹ ṣètò pé kí a kà á pẹlu ninu ìjọ awọn ará Laodikea kí ẹ̀yin pẹlu sì ka èyí tí ó wá lati Laodikea.” (Kolosse 4:16) Ìṣípayá 1:3 sì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni naa tí ń ka awọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yii sókè ati awọn wọnnì tí ń gbọ́, tí wọ́n sì ń pa awọn ohun tí a kọ sínú rẹ̀ mọ́; nitori àkókò tí a yànkalẹ̀ ti súnmọ́lé.” Nítorí náà, olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba ní láti ka àwọn ẹsẹ láti inú Bibeli láti lè ti ohun tí ó ń sọ fún ìjọ lẹ́yìn.

Ọ̀nà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Oníkókó-Ọ̀rọ̀

13. Ọ̀nà yíyára kánkán jù lọ wo ni a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ àwọn òtítọ́ Bibeli, kí sì ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti wá àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ rí?

13 Ìkẹ́kọ̀ọ́ oníkókó-ọ̀rọ̀ ni ọ̀nà yíyára kánkán jù lọ tí a lè gbà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ìwé Mímọ́. Àwọn atọ́ka, tí ó to àwọn ọ̀rọ̀ Bibeli ní ìtòtẹ̀léra a, b, d, nínú àyíká ọ̀rọ̀ wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìwé, orí, àti ẹsẹ, ń mú kí ó rọrùn láti wá àwọn ẹsẹ tí ó bá kókó ẹ̀kọ́ kan pàtó mu. A sì lè so irú àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ ara wọn nítorí pé, Òǹṣèwé Bibeli kò ta ko ara rẹ̀. Nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, ó mí sí nǹkan bí 40 ọkùnrin láti kọ Bibeli jálẹ̀ sáà ọ̀rúndún 16, kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kókó ọ̀rọ̀ jẹ́ ọ̀nà ìgbàkẹ́kọ̀ọ́, tí ẹ̀rí ti fi hàn pé ó gbéṣẹ́.

14. Èé ṣe tí a fi ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti Gíríìkì pa pọ̀?

14 Ìmọrírì wa fún òtítọ́ Bibeli yẹ kí ó sún wa láti ka Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Gíríìkì pa pọ̀ pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ wọn. Èyí yóò fi hàn bí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì ṣe so pọ̀ mọ́ ète Ọlọrun, yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ sórí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. (Romu 16:25-27; Efesu 3:4-6; Kolosse 1:26) Bibeli New World Translation of the Holy Scriptures ti ṣèrànwọ́ púpọ̀ lọ́nà yìí. Àwọn olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Ọlọrun, tí wọ́n lo àǹfààní ìmọ̀ púpọ̀ sí i tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nípa àwọn ẹsẹ Bibeli ìpilẹ̀ṣẹ̀ àti ipò àtilẹ̀wá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn àkànlò èdè rẹ̀, ni wọ́n mú un jáde. Àwọn àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli tí Jehofa pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” ṣe pàtàkì pẹ̀lú.

15. Báwo ni ìwọ yóò ṣe fi hàn pé ó bá a mu wẹ́kú láti ṣàyọlò níhìn-ín lọ́hùn-ún láti inú Bibeli?

15 Àwọn kan lè sọ pé, ‘Ìtẹ̀jáde yín ń ṣàyọlò ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹsẹ láti inú Bibeli, ṣùgbọ́n èé ṣe tí ẹ fi ń yọ ọ́ níhìn-ín lọ́hùn-ún?’ Nípa ṣíṣàyọlò níhìn-ín lọ́hùn-ún láti inú ìwé 66 tí ó wà nínú Bibeli, àwọn ìtẹ̀jáde náà ń mú ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tí a mí sí jáde láti jẹ́rìí sí ìjótìítọ́ ẹ̀kọ́ kan. Jesu alára lo ọ̀nà ìtọ́ni yìí. Nígbà tí ó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó ṣàyọlò ẹsẹ 21 láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Àwíyé yẹn ní àyọlò mẹ́ta láti inú Eksodu, méjì láti inú Lefitiku, ọ̀kan láti inú Numeri, mẹ́fà láti inú Deuteronomi, ọ̀kan láti inú Awọn Ọba Kejì, mẹ́rin láti inú Orin Dafidi, mẹ́ta láti inú Isaiah, àti ọ̀kan láti inú Jeremiah nínú. Nípa ṣíṣe èyí, Jesu ha wulẹ̀ ‘ń gbìyànjú láti mú ohunkóhun dáni lójú bí’? Ó tì o, nítorí ‘ó kọ́ wọn bí ẹnì kan tí ó ní ọlá àṣẹ, kì í ṣe bí àwọn akọ̀wé òfin.’ Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé, Jesu fi ọlá àṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a kọ sílẹ̀ ti ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn. (Matteu 7:29) Bẹ́ẹ̀ sì ni aposteli Paulu ṣe.

16. Àwọn àyọlò Ìwé Mímọ́ wo ni Paulu ṣe nínú Romu 15:7-13?

16 Nínú ẹsẹ ìwé mímọ́ tí a rí nínú Romu 15:7-13, Paulu ṣàyọlò láti inú àwọn apá mẹ́tẹ̀ẹ̀ta Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu—Òfin, àwọn Wòlíì, Orin Dafidi. Ó fi hàn pé àwọn Júù àti àwọn Kèfèrí yóò yin Ọlọrun lógo, nípa báyìí, àwọn Kristian ní láti fi inú dídùn tẹ́wọ́ gba àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè. Paulu wí pé: “Ẹ fi inúdídùn tẹ́wọ́gba ara yín lẹ́nìkínní kejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹlu ti fi inúdídùn tẹ́wọ́gbà wá, pẹlu ògo fún Ọlọrun ní iwájú. Nitori mo wí pé Kristi níti gàsíkíá di òjíṣẹ́ awọn wọnnì tí a kọnílà nitori jíjólóòótọ́ Ọlọrun, kí ó baà lè fìdí ẹ̀rí ìlérí tí Oun ṣe fún awọn baba-ńlá wọn múlẹ̀, ati kí awọn orílẹ̀-èdè baà lè yin Ọlọrun lógo fún àánú rẹ̀. Gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ̀ [ní Orin Dafidi 18:49] pé: ‘Dájúdájú ìdí nìyẹn tí emi yoo fi jẹ́wọ́ mímọ̀ ọ́n ní gbangba wálíà láàárín awọn orílẹ̀-èdè emi yoo sì kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ dájúdájú.’ Ó sì tún wí [ní Deuteronomi 32:43] pé: ‘Ẹ máa yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, pẹlu awọn ènìyàn rẹ̀.’ Ati pẹlu [ní Orin Dafidi 117:1]: ‘Ẹ yin Jehofa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ sì jẹ́ kí gbogbo awọn ènìyàn yìn ín.’ Isaiah [11:1, 10] sì tún wí pé: ‘Gbòǹgbò Jesse yoo wà, ẹni kan tí ń dìde lati ṣàkóso awọn orílẹ̀-èdè yoo sì wà; orí rẹ̀ ni awọn orílẹ̀-èdè yoo gbé ìrètí wọn kà.’ Kí Ọlọrun tí ń fúnni ní ìrètí fi ìdùnnú-ayọ̀ ati àlàáfíà gbogbo kún inú yín nipa gbígbàgbọ́ yín, kí ẹ̀yin lè ní ìrètí púpọ̀ gidigidi pẹlu agbára ẹ̀mí mímọ́.” Nípa ọ̀nà oníkókó-ọ̀rọ̀ yìí, Paulu fi bí a ṣe lè ṣàyọlò ẹsẹ ìwé mímọ́ hàn láti fìdí àwọn òtítọ́ Bibeli múlẹ̀.

17. Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ ìṣáájú wo ni àwọn Kristian fi ń ṣàyọlò níhìn-ín lọ́hùn-ún láti inú odindi Bibeli?

17 Lẹ́tà onímìísí tí aposteli Peteru kọ́kọ́ kọ, ní ẹsẹ 34 tí a ṣàyọlò láti inú ìwé mẹ́wàá nínú Òfin, àwọn Wòlíì, àti Orin Dafidi. Nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì, Peteru ṣàyọlò nígbà mẹ́fà láti inú iwé mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ìhìn Rere Matteu ní àyọlò 122 láti Genesisi sí Malaki. Nínú ìwé 27 ti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì, a ní 320 àyọlò tààràtà láti Genesisi sí Malaki àti ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ìtọ́kasí mìíràn sí Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu. Ní ìbámu pẹ̀lú àpẹẹrẹ ìṣáájú tí Jesu fi lélẹ̀ tí àwọn aposteli rẹ̀ sì tẹ̀ lé, nígbà tí àwọn Kristian òde òní bá ń kẹ́kọ̀ọ́ kókó ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ kan nípa lílo kókó ọ̀rọ̀, wọ́n ń ṣàyọlò láti inú apá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú odindi Bibeli. Èyí bá a mu ní pàtàkì ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” wọ̀nyí, nígbà tí apá tí ó pọ̀ jù lọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu àti Gíríìkì ti ń ní ìmúṣẹ. (2 Timoteu 3:1) ‘Olùṣòtítọ́ ẹrú’ náà ń lo Bibeli lọ́nà bẹ́ẹ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde rẹ̀, ṣùgbọ́n kò fìgbà kan rí fi kún Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tàbí yọ kúrò nínú rẹ̀.—Owe 30:5, 6; Ìṣípayá 22:18, 19.

Máa Rìn Nínú Òtítọ́ Nígbà Gbogbo

18. Èé ṣe ‘tí a fi ní láti rìn nínú òtítọ́’?

18 A ko gbọdọ̀ yọ ohunkóhun kúrò nínú Bibeli, nítorí àpapọ̀ ẹ̀kọ́ Kristian tí ó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun jẹ́ “òtítọ́” tàbí “òtítọ́ ìhìnrere.” Rírọ̀ mọ́ òtítọ́ yìí—‘rírìn’ nínú rẹ̀—ṣe pàtàkì fún ìgbàlà. (Galatia 2:5; 2 Johannu 4; 1 Timoteu 2:3, 4) Níwọ̀n bí ìsìn Kristian ti jẹ́ “ọ̀nà òtítọ́,” nípa ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú mímú ire rẹ̀ pọ̀ sí i, a ń di “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ ninu òtítọ́.”—2 Peteru 2:2; 3 Johannu 8.

19. Báwo ni a ṣe lè máa “bá a nìṣó ní rírìn nínú òtítọ́”?

19 Bí a bá ní láti máa “bá a lọ ní rírìn ninu òtítọ́,” a gbọ́dọ̀ ka Bibeli, kí a sì mú ara wa wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí Ọlọrun ń pèsè nípasẹ̀ ‘olùṣòtítọ́ ẹrú.’ (3 Johannu 4) Ǹjẹ́ kí a ṣe èyí fún ire wa, kí a sì lè wà ní ipò láti kọ́ àwọn ẹlòmíràn nípa Jehofa Ọlọrun, Jesu Kristi, àti ète àtọ̀runwá. Ẹ sì jẹ́ kí a máa dúpẹ́ pé ẹ̀mí Jehofa ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti láti ṣàṣeyọrí nínú ṣíṣiṣẹ́ sìn ín ní òtítọ́.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

◻ Àwọn àǹfààní pípẹ́ títí wo ni Bibeli kíkà ní?

◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?

◻ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ṣàyọlò láti inú onírúurú apá jálẹ̀ Bibeli?

◻ Kí ni ó túmọ̀ sí láti “rìn ninu òtítọ́,” báwo sì ni a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ẹ̀yin òbí, ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín ní Ìwé Mímọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Nínú Ìwàásù rẹ̀ Lórí Òkè, Jesu ṣàyọlò onírúurú apá láti inú Ìwé Mímọ́ Lédè Heberu

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́