Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí A Ka Bíbélì?
BÍBÉLÌ kò dà bí àwọn ìwé mìíràn o, nítorí àwọn ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló wà nínú rẹ̀. (1 Tẹsalóníkà 2:13) Bóo bá fi ohun tí Bíbélì fi kọ́ni sílò, àǹfààní tí wàá jẹ níbẹ̀ á kọyọyọ. Ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run á pọ̀ sí i, wàá sì sún mọ́ Ẹlẹ́dàá, Ẹni tó ń fúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17) Wàá mọ bó o ṣe lè gba àdúrà sí Ọlọ́run. Ọlọ́run á ràn ọ́ lọ́wọ́ lásìkò ìpọ́njú. Bó o bá mú ìgbésí ayé rẹ bá àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì mu, Ọlọ́run á fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 6:23.
Òótọ́ tó ń fúnni lóye ló wà nínú Bíbélì. Àwọn tó bá gba ìmọ̀ Bíbélì ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìrònú òdì tó ń darí ìgbésí ayé àìmọye èèyàn. Fún àpẹẹrẹ, lílóye òtítọ́ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tá a bá kú kì í jẹ́ ká tún máa bẹ̀rù pé àwọn òkú lè ṣe wá ní ibi tàbí pé ńṣe làwọn èèyàn wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa tó ti kú ń joró níbì kan. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa àjíǹde ń tu àwọn téèyàn wọn ti kú nínú. (Jòhánù 11:25) Mímọ ohun tó jóòótọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì burúkú ń jẹ́ ká wà lójúfò, ká má bàa jìn sí ọ̀fìn bíbá ẹ̀mí lò, ó tún ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ìdí tí rògbòdìyàn fi kúnnú ayé.
Àwọn ìlànà tí Ọlọ́run fún wa nínú Bíbélì kọ́ wa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó máa ṣe ara wa lóore. Àpẹẹrẹ kan rèé, jíjẹ́ “oníwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìwà” lè ṣàlékún ìlera. (1 Tímótì 3:2) Bá a bá “wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin ti ẹran ara àti ti ẹ̀mí,” a ò ní sọ ara wa di olókùnrùn. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Fífi àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run èyí tó wà nínú Bíbélì sílò á tún jẹ́ kí ìgbéyàwó wa dùn yùngbà-yungba, àwọn èèyàn á sì fọ̀wọ̀ wa wọ̀ wá.—1 Kọ́ríńtì 6:18.
Bó o bá mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lò, ńṣe layọ̀ rẹ á máa kún sí i. Ìmọ̀ Bíbélì ń fún wa ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn, ó sì ń fún wa nírètí. Ó ń mú ká ní àwọn ànímọ́ tó wuyì bí ìyọ́nú, ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, inú rere, àti ìgbàgbọ́. (Gálátíà 5:22, 23; Éfésù 4:24, 32) Àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn ń sọ wá di ọkọ tàbí aya rere, bàbá tàbí ìyá tó wuyì, àti ọmọ àmúyangàn.
Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí nípa ọjọ́ iwájú? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò tó ṣe pàtàkì nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn la wà yìí. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí kò mọ kìkì sórí sísọ bí ipò ayé ṣe máa rí lónìí, àmọ́ wọ́n tún fi hàn pé Ọlọ́run á sọ ayé yìí di Párádísè láìpẹ́.—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì
Ó ṣeé ṣe kó o ti ka Bíbélì títí àmọ́ kó o máà lóye rẹ̀. Bóyá o ò mọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ nínú Bíbélì. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe ìwọ nìkan lọ̀ràn rẹ̀ rí bẹ́ẹ̀. Gbogbo wa pátá la nílò ìrànlọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ní ìtọ́ni inú Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ láwọn ilẹ̀ bí igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235]. Inú wọn á sì dùn láti ran ìwọ náà lọ́wọ́.
Ohun tó dára jù ni pé kéèyàn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látorí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ kí ó sì máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ ní wẹ́rẹ́ wẹ́rẹ́. (Hébérù 6:1) Bó o bá ṣe ń tẹ̀ síwájú, wàá lè jẹ “oúnjẹ líle,” ìyẹn àwọn òtítọ́ tó jinlẹ̀. (Hébérù 5:14) Ohun tí Bíbélì bá sọ ni abẹ gé. Àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì, bí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, á ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ lórí àwọn ẹ̀kọ́ lóríṣiríṣi.
Ṣé O Ṣe Tán Láti Fàkókò Sílẹ̀ Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ Kó O Lè Lóye Bíbélì?
A lè ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí àkókò kan pàtó àti sí ibi tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ ló ń kẹ́kọ̀ ọ́ nínú ilé wọn. Orí tẹlifóònù làwọn mìíràn tiẹ̀ ti ń kẹ́kọ̀ọ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà kì í ṣe èyí táwọn èèyàn máa pọ̀ níbẹ̀ rẹpẹtẹ, àmọ́ wọ́n á ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò rẹ, òye rẹ àti ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tó o ní mu. Kò sí pé wọ́n máa ṣe ìdánwò fún ẹ, ẹnikẹ́ni kò sì ní dójú tì ọ́. Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó o ní nínú Bíbélì, wàá sì kọ́ bó o ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run.
O ò ní sanwó fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. (Mátíù 10:8) Ọ̀fẹ́ ni wọ́n ń ṣe é fáwọn èèyàn tí ń ṣe onírúurú ẹ̀sìn àtàwọn tí kò tiẹ̀ lẹ́sìn kankan àmọ́ tí wọ́n fi tọkàntọkàn nífẹ̀ẹ́ sí mímú kí ìmọ̀ wọn nípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pọ̀ sí i.
Àwọn wo ló lè pẹ̀lú rẹ nínú ìjíròrò náà? Gbogbo ìdílé rẹ. Ọ̀rẹ́ rẹ èyíkéyìí tó o bá fẹ́ láti ké sí náà lè wà níbẹ̀. Bó bá sì jẹ́ pé ìwọ nìkan lo fẹ́ kí wọ́n máa bá jíròrò, dáadáa náà ni.
Wákàtí kan lọ̀pọ̀ máa ń yà sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Yálà àyè rẹ̀ yọ fún ọ láti lò jù bẹ́ẹ̀ lọ tàbí o kò ní lè lò tó bẹ́ẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí ti múra tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
A Pè Ọ́ Láti Wá Kẹ́kọ̀ọ́
A rọ̀ ọ́ pé kó o kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe èyí ni pé kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì kan lára èyí tó wà nísàlẹ̀ yìí. A ó sì wá ṣètò pé kí ẹnì kan wá máa bá ọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
□Màá fẹ́ láti gba ẹ̀dà kan ìwé náà Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
□Ẹ jọ̀wọ́, ẹ kàn sí mi nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́.
Bá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, gbogbo ẹsẹ Bíbélì wá látinú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.