ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w15 4/1 ojú ìwé 4-7
  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TÁ À Ń ṢE
  • Kí Ni Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
    Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
    Jí!—2012
  • Ṣé o gbádùn ohun tó o kọ́?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
w15 4/1 ojú ìwé 4-7
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ WÀÁ FẸ́ KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fún Gbogbo Èèyàn

Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé?

Ọkùnrin kan ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ibiṣẹ́

Lọ́dún 2014, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ [8,000,000] àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè òjìlérúgba [240] tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Iye àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [9,500,000].a Ká sòótọ́, iye àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ju iye àwọn èèyàn tó ń gbé ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn orílẹ̀-èdè tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogóje [140]!

Kí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè ṣe iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí, a máa ń tẹ Bíbélì, àwọn ìwé, àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì míì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù kan ààbọ̀ ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méje (700) èdè! Iṣẹ́ ìtẹ̀wé tí kò lẹ́gbẹ́ yìí ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní èdè tí wọ́n bá fẹ́.

“Nígbà tí mo wà níléèwé, mi ò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn kí n máa kẹ́kọ̀ọ́, àmọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí yàtọ̀. Àwọn ohun tí mo kọ́ tù mí nínú gan-an!”—Katlego, South Africa.

“Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà dáhùn gbogbo ìbéèrè tó ń jẹ mí lọ́kàn àtàwọn míì.”—Bertha, Mẹ́síkò.

“Ilé mi la ti ń sẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ní àkókò tó rọrùn fún mi. Kí ni mo tún ń fẹ́!”—Eziquiel, Brazil.

“Nígbà míì, mo máa ń lo nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú láti fi kẹ́kọ̀ọ́, nígbà míì sì rèé, a lè lò jù bẹ́ẹ̀ lọ, èyí tó bá ti rọrùn fún mi ni.”—Viniana, Ọsirélíà.

“Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, mo sì gbádùn rẹ̀ gan-an!” —Aimé, Benin.

“Ẹni tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ onísùúrù àti onínúure. Èyí mú ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.” —Karen, Northern Ireland.

“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọn ò sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” —Denton, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

ÌDÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ TÁWỌN ÈÈYÀN MÁA Ń BÉÈRÈ NÍPA ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ TÁ À Ń ṢE

Báwo lẹ ṣe máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́?

A máa ń yan onírúurú ẹ̀kọ́ Bíbélì, a sì máa ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá àwọn ẹ̀kọ́ náà mu. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè, bíi: Ta ni Ọlọ́run? Irú ẹni wo ni Ọlọ́run jẹ́? Ṣé ó ní orúkọ? Ibo ló ń gbé? Ǹjẹ́ a lè sún mọ́ ọn? Ohun tó máa ń jẹ́ ìṣòro ni béèyàn ṣe máa rí ìdáhùn nínú Bíbélì.

Kó lè ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rí ìdáhùn, a máa ń lo ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó ní ojú ìwé igbà ó lé mẹ́rìnlélógún [224].b Ńṣe la dìídì ṣe ìwé yìí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú Bíbélì. Ìwé náà ní àwọn ẹ̀kọ́ tó sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, Jésù Kristi, ìyà tó ń jẹ àwa èèyàn, àjíǹde, àdúrà àtàwọn ẹ̀kọ́ míì.

Ìgbà wo ni èèyàn lè máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ibo ló sì ti máa ṣe é?

Ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lè wáyé ní àkókò tó bá rọrùn fún ẹ àti ní ibi tó bá wù ẹ́.

Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa gùn tó?

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lo nǹkan bíi wákátì kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ kò pọn dandan kó gùn tó bẹ́ẹ̀. A máa ṣètò rẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò rẹ mu. Àwọn kan kì í lò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.

Èló lẹ máa ń gbà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà?

Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Èyí sì bá ìtọ́ni tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mu pé: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.”—Mátíù 10:8.

Báwo ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe máa pẹ́ tó?

Ìwọ fúnra rẹ lo máa pinnu bó ṣe máa pẹ́ tó. Ẹ̀kọ́ mọ́kàndínlógún [19] ló wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? O lè ka èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀kọ́ náà, o sì lè ka gbogbo rẹ̀ bí àkókó bá ṣe wà fún ẹ tó.

Ṣé ó pọn dandan kí n di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Rárá. A gbà pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó máa gbà gbọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn tó bá ti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ló máa ń fúnra wọn pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe.

Ibo ni mo ti lè rí ìsọfúnni síwájú sí i?

Wàá rí ìsọfúnni tó kún rẹ́rẹ́ nípa ìgbàgbọ́ àti iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ìkànnì jw.org/yo.

Báwo ni mo ṣe lè béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

  • Àwọn tó ń béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lónírúurú ọ̀nà: lórí íńtánẹ́ẹ̀tì, kíkọ̀wé, àti nípa kíkàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nítòsí

    Kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà lórí ìkànnì www.jw.org/yo.

  • Kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó sún mọ́ ẹ jù lọ lára àwọn tá a kọ sí ojú ìwé kejì nínú ìwé ìròyìn yìí.

  • O tún lè kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè rẹ.

a A sábà máa ń kọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tàbí àwùjọ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. A sì ti tẹ ẹ̀dá tó lé ní mílíọ̀nù igba ó lé ọgbọ̀n [230,000,000] jáde ní ọgọ́rùn-ún méjì ó lé ọgọ́ta [260] èdè.

Ó ń mú Kí Ìdílé Wà Níṣọ̀kan

Eziquiel

“Nígbà tí ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo kíyè sí pé àwọn ìwà rẹ̀ yí pa dà. Èyí mú kí ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wa. Mo wá fẹ́ mọ nǹkan tó ń kọ́, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí mo kọ́ wá jẹ́ kí ìwà tèmi náà dára sí i. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti mú kí ìdílé mi wà ní ìṣọ̀kan.”—Eziquiel.

Karen

“Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mú kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, ọtí àmujù, mo sì tún kọ́ bí máa ṣe ṣàkóso ìbínú mi. Ní báyìí, inú ilé mi ṣeé rí, ó sì wà létòlétò. Mo túbọ̀ wá mọyì ìdílé mi, mo sì gbádùn kí n máa ṣe nǹkan tó máa múnú wọn dùn. Èmi fúnra mi sì láyọ̀ gan-an.”—Karen.

Viniana

“Àwọn kan ń bú mi torí pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ ọkọ mi tì mí lẹ́yìn, ó ni: ‘Ohun tó bá wu ẹlẹ́nu ló lè fẹnu ẹ̀ sọ. Ohun tó ṣe pàtàkì sí mi ni pé ohun tó ò ń kọ́ tí jẹ́ kí ìwà rẹ dára sí i. Máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ lọ́.’ Kò tíì sígbà tí ìdílé wa ṣọ̀kan báyìí rí!”—Viniana.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́