Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé?
Ṣé o rò pé . . .
inú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni?
àbí inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí?
àbí inú Bíbélì?
Ọ̀KAN LÁRA ÀWỌN TÓ KỌ BÍBÉLÌ SỌ FÚN ỌLỌ́RUN PÉ
“Fún mi ní òye . . . Òtítọ́ ni . . . ọ̀rọ̀ rẹ.”—Sáàmù 119:144, 160, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Bíbélì ń dáhùn ìbéèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.
Ṣé wàá fẹ́ kó dáhùn tìẹ náà?
Ìkànnì jw.org/yo máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.
KA àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì náà
Bíbélì wà níbẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè
Ìdáhùn àwọn ìbéèrè látinú Bíbélì
Ìrànlọ́wọ́ tó wà fún àwọn ìdílé
WO àwọn fídíò tó dá lórí Bíbélì
Ẹ̀kọ́ àti àwọn orin tó wà fún àwọn ọmọdé
Ìmọ̀ràn tó wà fún àwọn ọ̀dọ́
Ìgbàgbọ́ tó lágbára
WA àwọn ìwé jáde
Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
ÈWO LÁRA ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ YÌÍ LÓ Ń JẸ Ọ́ LỌ́KÀN JÙ LỌ?
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa?
Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú?
Wàá rí ìdáhùn látinú Bíbélì sí àwọn ìbéèrè yìí lórí ìkànnì jw.org/yo.
(Lọ sí Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ › OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ)