Ohun Míì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
INÚ BÍBÉLÌ LA TI LÈ RÍ ÌTỌ́SỌ́NÀ TÓ DÁRA JÙ LỌ tó wúlò fún tọkọtaya, àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́. Àwọn ìlànà tó wà nínú rẹ̀ máa jẹ́ ká máa ronú lọ́nà tó tọ́, á sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó tọ́.—Òwe 1:1-4.
BÍBÉLÌ TÚN DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ PÀTÀKÌ BÍI:
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá wa?
Ṣé Ọlọ́run ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé?
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú?
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì nínú Bíbélì. Wo fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Wo ìlujá yìí tàbí kó o lọ sí ìkànnì www.jw.org/yo.