ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g24 No. 1 ojú ìwé 10-12
  • Ìwà Àpọ́nlé Ti Dàwátì Nínú Ọ̀pọ̀ Ìdílé!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwà Àpọ́nlé Ti Dàwátì Nínú Ọ̀pọ̀ Ìdílé!
  • Jí!—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁWỌN TÓ WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÚN ARA WỌN
  • OHUN TÓ O LÈ ṢE
  • OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE
  • Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Jí!—2020
  • Ohun Míì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́
    Jí!—2018
  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
Àwọn Míì
Jí!—2024
g24 No. 1 ojú ìwé 10-12
Ọkùnrin kan tí inú ń bí ń tẹ fóònù ẹ̀, ìyàwó ẹ̀ sì ń gbìyànjú láti bá a sọ̀rọ̀. Ọmọkùnrin wọn ń wò wọ́n.

Ìwà Àpọ́nlé Ti Dàwátì Nínú Ọ̀pọ̀ Ìdílé!

ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁWỌN TÓ WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ MÁA BỌ̀WỌ̀ FÚN ARA WỌN

Táwọn tó wà nínú ìdílé bá ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, àlàáfíà á jọba, ọkàn wọn á balẹ̀, ara á sì tù wọ́n.

  • Ìwé The Seven Principles for Making Marriage Work sọ pé tí tọkọtaya bá ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn, wọ́n á túbọ̀ mọyì ara wọn, wọ́n á sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn “nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń ṣe lójoojúmọ́, kódà nínú àwọn ohun tó dà bíi pé kò tó nǹkan.”

  • Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọdé tó bá ń bọ̀wọ̀ fúnni máa ń níyì lójú ara wọn, wọ́n máa ń ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn òbí wọn, wọn kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ ní àárẹ̀ ọpọlọ.

OHUN TÓ O LÈ ṢE

Ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa ohun tẹ́ ẹ máa ṣe nínú ìdílé yín. Lákọ̀ọ́kọ́, ẹ rí i pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé yín ló mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa “bọ̀wọ̀” fúnni. Ìkejì, ẹ kọ àwọn ìwà tẹ́ ẹ fẹ́ káwọn tó wà nínú ìdílé yín máa hù àtàwọn tẹ́ ọ̀ fẹ́ kí wọ́n máa hù. Ìkẹta, ẹ jọ jíròrò àwọn nǹkan yìí nínú ìdílé yín kí gbogbo yín lè mọ bẹ́ ẹ ṣe lè máa bọ̀wọ̀ fún ara yín.

“Àwọn ohun tí òṣìṣẹ́ kára gbèrò láti ṣe máa ń yọrí sí rere.”—Òwe 21:5.

Fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀. Ṣé o máa ń ṣàríwísí àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ tí wọ́n bá ṣàṣìṣe? Ṣé o máa ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tí wọ́n bá sọ èrò wọn? Tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ṣé o kì í já ọ̀rọ̀ gbà mọ́ wọn lẹ́nu tàbí kó o mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bíi pé o ò gbọ́ ohun tí wọ́n sọ? Fi sọ́kàn pé tó o bá ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn á rọrùn fún wọn láti máa bọ̀wọ̀ fún ẹ.

Ohun tó o lè ṣe: Má retí pé ohun tí ẹnì kejì ẹ tàbí àwọn ọmọ ẹ bá ṣe láá mú kó o máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, múra tán láti máa bọ̀wọ̀ fún wọn ní gbogbo ìgbà.

“Nínú bíbu ọlá fún ara yín, ẹ mú ipò iwájú.”—Róòmù 12:10.

Máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn tó ò bá tiẹ̀ fara mọ́ èrò wọn. Tó o bá ń sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ, má ṣe máa lo àwọn ọ̀rọ̀ bíi “gbogbo ìgbà lo máa ń” tàbí “kò sígbà tó o.” Ńṣe nirú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń buni kù, ó lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ, ó sì lè sọ ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan di bàbàrà.

“Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ máa ń mú kí ìbínú rọlẹ̀, àmọ́ ọ̀rọ̀ líle ń ru ìbínú sókè.”—Òwe 15:1.

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń wo fídíò lórí jw.org.

OHUN TÍ ÀWA ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ Ń ṢE

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń rọ àwọn tó wà nínú ìdílé pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. A sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àwọn àpilẹ̀kọ, ìwé àtàwọn fídíò tá à ń gbé jáde, ọ̀fẹ́ sì ni gbogbo ẹ̀.

ÀWỌN TỌKỌTAYA: Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ . . .

  • bí wọ́n ṣe lè máa fetí sílẹ̀ dáadáa

  • bí wọ́n ṣe lè jáwọ́ nínú bíbá ara wọn yan odì

  • bí wọ́n ṣe lè jáwọ́ nínú bíbá ara wọn jiyàn

(Wá “Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé” lórí jw.org)

ÀWỌN ÒBÍ: Ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ náà Ìrànlọ́wọ́ fún Ìdílé lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn . . .

  • bí wọ́n ṣe lè jẹ́ onígbọràn

  • bí wọ́n ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé

  • bí wọ́n ṣe lè máa sọ “ẹ jọ̀wọ́” àti “ẹ ṣeun”

(Wá “Ọmọ Títọ́” àti “Bó O Ṣe Lè Tọ́ Àwọn Ọ̀dọ́” lórí jw.org)

Tún wo àfikún náà “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè,” nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní. (Wá “Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Òbí Ń Béèrè” lórí jw.org)

ÀWỌN Ọ̀DỌ́: Ní abala Ọ̀dọ́ lórí jw.org, wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ, àwọn fídíò àtàwọn ìwé àjákọ tó lè ran àwọn ọ̀dọ́ lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ . . .

  • bí wọ́n ṣe lè lájọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn òbí, ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò wọn

  • bí wọ́n ṣe lè fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bá àwọn òbí wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn òfin tí wọ́n ṣe

  • bí wọ́n ṣe lè jẹ́ káwọn òbí wọn fọkàn tán wọn

(Wá “Ọ̀dọ́” lórí jw.org)

O ò ní sanwó tó o bá fẹ́ lo jw.org. Kò sí pé ò ń san owó sílẹ̀ kó o tó lè lo ìkànnì náà, o ò sì nílò láti forúkọ sílẹ̀ tàbí kó o sọ ìsọfúnni nípa ara ẹ.

Joseph Ehrenbogen.

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I

Oníjàgídíjàgan ni Joseph Ehrenbogen nígbà tó ṣègbéyàwó, lílo oògùn olóró sì ti di bárakú fún un. Ka àpilẹ̀kọ náà “Mo Kọ́ Láti Bọ̀wọ̀ fún Àwọn Obìnrin Kí N Sì Mọyì Ara Mi” kó o lè mọ báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran òun àti ìdílé ẹ̀ lọ́wọ́. Wá àpilẹ̀kọ yìí lórí jw.org.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́