ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb22 September ojú ìwé 3
  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ohun Tó Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́
    Jí!—2020
  • Bó O Ṣe Lè Lo Ìkànnì Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìkànnì Wa Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ó Wúlò Fún Àwa Àtàwọn Ẹlòmíì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
mwb22 September ojú ìwé 3

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Wàá Rí Ìmọ̀ràn Tó Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Lórí Ìkànnì JW.ORG

Gbogbo ohun tá a nílò ká lè fara da àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó le koko yìí ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (2Ti 3:1, 16, 17) Síbẹ̀, àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé a lè má mọ bá a ṣe lè rí àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ pàtó kan. Bí àpẹẹrẹ, ṣé òbí ni ẹ́, tó o sì ń wá ìmọ̀ràn lórí bó o ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ? Ṣé ọ̀dọ́ ni ẹ́, tó o sì ń dojú kọ àwọn ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ rẹ wò? Ṣé ò ń ṣọ̀fọ̀ ikú ọkọ tàbí ìyàwó rẹ? Lórí Ìkànnì jw.org, wàá rí àwọn ìsọfúnni táá jẹ́ kó o mọ àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ipò yìí àtàwọn ipò míì tó o lè bá ara ẹ.—Owe 2:3-6.

Ìkànnì jw.org lórí tablet kan. Apá Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ ni wọ́n ṣí i sí.

Lórí Ìkànnì jw.org, te apá tá a pè ní Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ. (Wo àwòrán 1.) Nínú àwọn ohun tó gbé wa, yan èyí tó o fẹ́. Tàbí kó o lọ sí apá OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ kó o sì yàn èyí tó o fẹ́. (Wo àwòrán 2.) O tún lè rí àwọn apá yìí lórí JW Library®.a Wàá rí àwọn àpilẹ̀kọ náà kà ní èyíkéyìí lára àwọn ibi tá a tọ́ka sí yìí. Ohun míì tó o lè ṣe ni pé kó o tẹ ohun tó o fẹ́ ṣèwádìí lé lórí sí apá tá a pè ní “wà a” lórí Ìkànnì jw.org.

Ìkànnì jw.org lórí tablet kan. Apá OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ lábẹ́ OHUN TÁ A NÍ ni wọ́n ṣí i sí.

Tẹ àwọn àkọlé yìí sí apá wá a, kó o sì ṣàkọsílẹ̀ àwọn àpilẹ̀kọ tí wàá fẹ́ kà.

  • Ọmọ títọ́

  • Ìṣòro àwọn ọ̀dọ́

  • Ikú ọkọ tàbí aya

a Orí jw.org nìkan lo ti lè rí gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà lábẹ́ àwọn ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ kan.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́