ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-31 ojú ìwé 1-4
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
  • Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
    Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
  • Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
    Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
  • Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
    Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
Àwọn Míì
Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
T-31 ojú ìwé 1-4

Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?

Ṣé ayé yìí máa . . .

  • wà bó ṣe wà?

  • àbí ó máa burú sí i?

  • àbí ó ṣì máa dáa?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Ọlọ́run . . . máa nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn, ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn nǹkan àtijọ́ ti kọjá lọ.”​—Ìfihàn 21:3, 4, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

Wàá ní iṣẹ́ gidi tó máa tẹ́ ọ lọ́rùn.​—Àìsáyà 65:21-23.

Kò ní sí àìsàn àti ìyà kankan mọ́.​—Àìsáyà 25:8; 33:24.

Inú rẹ á máa dùn, wàá sì lè wà láàyè títí láé pẹ̀lú mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ.​—Sáàmù 37:11, 29.

Ọkùnrin àti obìnrin kan ń wo ọ̀ọ́kán pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa; ọmọbìnrin kan ń bomi rin ewéko; àwọn kọ́lékọ́lé ń kọ́ ilé

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ìlérí Ọlọ́run kì í yẹ̀. Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni Bíbélì pè ní “Olódùmarè” torí pé agbára rẹ̀ kò láàlà. (Ìfihàn 15:3) Torí náà, ó lágbára láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun máa bá wa tún ayé yìí ṣe. Bíbélì sọ pé, “ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”​—Mátíù 19:26.

  • Ọlọ́run fẹ́ mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ń wu Jèhófà gan-an pé kó jí àwọn tó ti kú dìde.​—Jóòbù 14:14, 15.

    Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù, Ọmọ Ọlọ́run, mú àwọn aláìsàn lára dá. Kí nìdí tó fi wò wọ́n sàn? Ìdí ni pé ó wù ú pé kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Máàkù 1:40, 41) Bí Jésù ṣe máa ń fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ ń gbé ìwà Baba rẹ̀ yọ.​—Jòhánù 14:9.

    Torí náà, ó dá wa lójú pé Jèhófà àti Jésù fẹ́ kí ọjọ́ ọ̀la wa dùn bí oyin!​—Sáàmù 72:12-14; 145:16; 2 Pétérù 3:9.

RÒ Ó WÒ NÁ

Ẹnì kan ń tọ́ka sí ẹsẹ kan nínú Bíbélì

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa tún ayé yìí ṣe?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé MÁTÍÙ 6:9, 10 àti DÁNÍẸ́LÌ 2:44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́