ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • T-35 ojú ìwé 1-4
  • Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
  • Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
    Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?
  • Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
    Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
  • Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
    Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?
  • Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
    Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?
Àwọn Míì
Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?
T-35 ojú ìwé 1-4
Bàbá àti ìyá ń wo àwòrán ọmọ wọn kékeré tó ti kú

Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?

Kí ni ìdáhùn rẹ?

  • Bẹ́ẹ̀ ni.

  • Bẹ́ẹ̀ kọ́.

  • Kò dá mi lójú.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Àjíǹde . . . yóò wà.”​—Ìṣe 24:​15, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ

Ó máa tù ẹ́ nínú tí èèyàn rẹ bá ṣaláìsí.​—2 Kọ́ríńtì 1:​3, 4.

Kò ní jẹ́ kó o máa bẹ̀rù ikú.​—Hébérù 2:15.

Á mú kó dá ẹ lójú pé wàá pa dà rí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú.​—Jòhánù 5:​28, 29.

Ìrètí àjíǹde ń tu ìdílé kan àti opó kan nínú

ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Bíbélì pe Jèhófà Ọlọ́run ní “orísun ìyè.” (Sáàmù 36:9; Ìṣe 17:​24, 25) Ó dájú pé Ẹni tó lágbára láti dá ohun gbogbo lágbára láti jí òkú dìde.

  • Ọlọ́run ti jí àwọn òkú dìde rí. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa èèyàn mẹ́jọ tí Ọlọ́run jí dìde, ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà wà lára wọn. Kò pẹ́ rárá tí àwọn kan lára wọn kú tí wọ́n fi jíǹde, àmọ́ ọ̀kan wà lára wọn tó jẹ́ pé odindi ọjọ́ mẹ́rin ló ti wà nínú ibojì!​—Jòhánù 11:​39-44.

  • Ó ń wu Ọlọ́run pé kó jí àwọn òkú dìde. Jèhófà kórìíra ikú, ó kà á sí ọ̀tá wa. (1 Kọ́ríńtì 15:26) Ó fẹ́ ṣẹ́gun ikú tó jẹ́ ọ̀tá wa pátápátá, torí náà ó máa jí àwọn òkú dìde. Ó ń wù ú gan-an pé kó jí gbogbo àwọn tó wà nínú ìrántí rẹ̀ dìde, ó sì fẹ́ kí wọ́n tún wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé.​—Jóòbù 14:​14, 15.

RÒ Ó WÒ NÁ

Ọmọkùnrin kékeré kan ń dàgbà títí ó fi darúgbó

Kí nìdí tá a fi ń darúgbó tá a sì ń kú?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé JẸ́NẸ́SÍSÌ 3:​17-19 àti RÓÒMÙ 5:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́