Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
Kí ni ìdáhùn rẹ?
Bẹ́ẹ̀ ni.
Bẹ́ẹ̀ kọ́.
Kò dá mi lójú.
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn; kì yóò sì sí ikú mọ́, tàbí ọ̀fọ̀, tàbí ẹkún, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ìrora mọ́.”—Ìfihàn 21:4, Bíbélì Mímọ́.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ
Á jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run kọ́ ló ń fa àwọn ìṣòro wa.—Jémíìsì 1:13.
Ara máa tù ẹ́ láti mọ̀ pé àánú wa máa ń ṣe Ọlọ́run tá a bá ń jìyà.—Sekaráyà 2:8.
Ọkàn rẹ á balẹ̀ pé gbogbo ìyà máa dópin.—Sáàmù 37:9-11.
ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Méjì lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:
Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa jìyà, kò sì fẹ́ kí wọ́n rẹ́ wa jẹ. Wo bó ṣe rí lára Jèhófà Ọlọ́run nígbà tí àwọn kan fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Bíbélì sọ pé inú Jèhófà kò dùn rárá nítorí “àwọn tó ń ni wọ́n lára.”—Àwọn Onídàájọ́ 2:18, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Ọlọ́run kórìíra àwọn tó ń ṣe ìkà sí ọmọnìkejì wọn. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé Jèhófà kórìíra “ọwọ́ tó ń ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀.”—Òwe 6:16, 17.
Ọlọ́run ń bójú tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Yàtọ̀ sí pé kálukú mọ “ìṣòro rẹ̀ àti ìrora rẹ̀,” Jèhófà náà mọ ohun tó ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan wa fínra.—2 Kíróníkà 6:29, 30.
Láìpẹ́, Jèhófà máa lo Ìjọba rẹ̀ láti fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. (Mátíù 6:9, 10) Àmọ́ ní báyìí, Jèhófà ń jẹ́ kí àwọn tó ń fi gbogbo ọkàn wá a rí ìtùnú.—Ìṣe 17:27; 2 Kọ́ríǹtì 1:3, 4.
RÒ Ó WÒ NÁ
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn?
Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé RÓÒMÙ 5:12 àti 2 PÉTÉRÙ 3:9.