Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 13
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 13
Orin 131 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 1 ìpínrọ̀ 10 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 6-10 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 9:18–10:7 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Dá Ayé Kó Lè Jẹ́ Párádísè—td 25A (5 min.)
No. 3: Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa—lr orí 2 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àǹfààní Tó Wà Nínú Sísọ Àsọtúnsọ Lóde Ẹ̀rí. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Jàǹfààní, ojú ìwé 206 sí 207. Lo ọ̀kan lára àwọn kókó tó wà nínú ìwé náà láti ṣe àṣefihàn kan ní ṣókí.
10 min: Àwọn Ọkùnrin Tí Ń Ṣe Ìránṣẹ́ Lọ́nà Tí Ó Dára Lọ́pọ̀lọpọ̀. (1 Tím. 3:13) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ méjì. Àwọn iṣẹ́ wo ni wọ́n ń bójú tó nínú ìjọ, ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ń bójú tó àwọn iṣẹ́ náà? Kí nìdí tí wọ́n fi sapá kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́? Kí nìdí tí wọ́n fi fẹ́ràn láti máa lo ara wọn fún àǹfààní ìjọ tí wọ́n sì ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́?
10 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Míkà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 35 àti Àdúrà