Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn gan-an láti sọ fún yín pé ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà àti igba ó lé márùn-ún [351,205] akéde ló ròyìn lóṣù August ọdún 2013. A ò tíì ní iye akéde tó pọ̀ tó báyìí rí. Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tún pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ márùndínlógójì ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàje àti èjìdínláàdọ́rùn-ún ó lé ẹgbẹ̀rin [715,888]. Èyí fi ẹgbàá mọ́kànlélógún, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mẹ́rìnlélógún [42,624] ju iye àwọn tó wá lọ́dún tó kọjá lọ. Iye àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ṣe tún pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a ṣe jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé mẹ́tàlá àti ọgọ́rùn mẹ́jọ dín mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [813,775]. Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí Jèhófà túbọ̀ ń ràn wá lọ́wọ́ láti tan ìhìn rere náà kálẹ̀.