Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 10
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 10
Orin 1 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 4 ìpínrọ̀ 1 sí 9 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 40-42 (10 min.)
No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 41:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Wo Ló Máa Lọ Sí Ọ̀run?—td 41A (5 min.)
No. 3: A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò—lr orí 9 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Ìjọsìn Ìdílé Tó Ń Tuni Lára. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ìdílé kan nípa bí wọ́n ṣe ń ṣe ìjọsìn ìdílé wọn. Báwo ni wọ́n ṣe máa ń ṣe é? Báwo ni wọ́n ṣe máa ń pinnu ohun tí wọ́n máa jíròrò? Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ti lò lórí ìkànnì jw.org? Báwo ni Ìjọsìn Ìdílé ṣe ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí? Kí ni wọ́n ṣe kí àwọn nǹkan míì má bàa ṣèdíwọ́ lákòókò tí wọ́n máa ń ṣe Ìjọsìn Ìdílé wọn? Báwo ni wọn ti ṣe jàǹfààní látinú Ìjọsìn Ìdílé?
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Fèsì Bí Ẹnì Kan Ò Bá Fẹ́ Gbọ́ Ìwàásù Rẹ.” Ìjíròrò. Sọ ohun méjì tàbí mẹ́ta táwọn èèyàn lè sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù wa, kí o sì ní káwọn ará sọ bí wọ́n ṣe lè fèsì. Rán àwọn ará létí pé wọ́n máa láǹfààní láti sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní April 7.
Orin 97 àti Àdúrà