Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bó O Ṣe Lè Fèsì Bí Ẹnì Kan Ò Bá Fẹ́ Gbọ́ Ìwàásù Rẹ
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Jẹ́ ká sọ pé o mọ̀ pé àjálù kan máa tó ṣẹlẹ̀. Àwọn tí kò bá sì sá lọ síbi ààbò máa kú. O wá lọ sí ilé aládùúgbò rẹ kan láti kìlọ̀ fún un, àmọ́ bó o ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ńṣe ló dá ọ̀rọ̀ mọ́ ẹ lẹ́nu pé òun ò ráyé tìẹ. Ó dájú pé o ò kan ní fi ibẹ̀ sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láìgbìyànjú láti jẹ́ kó mọ̀ pé ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu! Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ni kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, wọn ò sì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ tó lè gbẹ̀mí wọn là ni a fẹ́ bá wọn sọ. Ó lè jẹ́ pé ọwọ́ wọn dí nígbà tá a lọ sọ́dọ̀ wọn. (Mát. 24:37-39) Ó sì lè jẹ́ pé irọ́ táwọn kan ti pa fún wọn nípa wa ló jẹ́ kí wọ́n máa ṣe ẹ̀tanú sí wa. (Mát. 11:18, 19) Wọ́n tún lè máa ronú pé kò sí ìyàtọ̀ láàárín àwa àtàwọn ẹ̀sìn yòókù tí wọn ò tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ. (2 Pét. 2:1, 2) Bí àwọn èèyàn ò bá kọ́kọ́ fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká tètè rò pé kò sí bá a ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́ mọ́.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Tó o bá pàdé ẹnì kan tí kò fẹ́ gbọ́ ìwàásù rẹ, lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ìwọ àti ẹni tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tó tún dára jù tẹ́ ẹ lè gbà fèsì.