Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fèsì Tí Ẹni Tó O Fẹ́ Wàásù fún Bá Ń Bínú
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí à ń bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ni wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí. Àmọ́, Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan máa kórìíra wa. (Jòh. 17:14) Torí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu tí a bá bá àwọn tínú ń bí pàdé lóde ẹ̀rí. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fèsì lọ́nà tó máa dùn mọ́ Jèhófà, ẹni tí à ń ṣojú fún. (Róòmù 12:17-21; 1 Pét. 3:15) Tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ náà kò ní di ńlá. Yóò sì tún jẹ́ ẹ̀rí fún ẹni tí a wàásù fún àtàwọn tó ń wò wá, èyí sì lè mú kí wọ́n tẹ́tí sílẹ̀ nígbà míì tí àwọn ará wa bá tún lọ wàásù fún wọn.—2 Kọ́r. 6:3.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Ẹ ṣe ìdánrawò bí ẹ ṣe lè dá ẹni tí inú ń bí lóhùn nígbà ìjọsìn ìdílé yín.
Tí o bá kúrò lọ́dọ̀ onílé tínú ń bí, kí ìwọ àti ẹni tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí jíròrò ọ̀nà míì tó dáa jù tó yẹ kó o gbà dá ẹni náà lóhùn.