Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 12
Orin 114 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 18 ìpínrọ̀ 20 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 188 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jóṣúà 21-24 (8 min.)
No. 1: Jóṣúà 24:14-21 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí La Lè Kọ́ Látinú Àpẹẹrẹ Màríà, Ìyá Jésù? (5 min.)
No. 3: Jèhófà Ni Ẹlẹ́dàá Tó Jẹ́ Alágbára Gíga Jù Lọ—igw ojú ìwé 2 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 3 ìpínrọ̀ 1 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa “sìnrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú títóbi jù lọ.”—Ìṣe 20:19.
10 min: Ẹ Máa Sìnrú fún Olúwa Pẹ̀lú Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú Títóbi Jù Lọ. Ìjíròrò. Ka Ìṣe 20:19. Lẹ́yìn náà, ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí ni ọ̀rọ̀ ìṣe náà “sìnrú” túmọ̀ sí? (2) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà sìnrú fún Olúwa? (3) Kí ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀? (4) Báwo ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ṣe ń jẹ́ ká ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
20 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fèsì Tí Ẹni Tó O Fẹ́ Wàásù fún Bá Ń Bínú.” Ìjíròrò. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò àpilẹ̀kọ náà, ní ṣókí, ṣe àṣefihàn alápá méjì. Nínú àṣefihàn àkọ́kọ́, akéde náà kò fún onílé tí inú ń bí lésì lọ́nà tó dára. Nínú àṣefihàn kejì, akéde náà fèsì lọ́nà tó dára. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n fi àwọn àbá tó wà lábẹ́ “Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí” sílò.
Orin 76 àti Àdúrà