“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
1. Ìlànà Bíbélì wo ló yẹ ká fi sílò tá a bá pàdé àwọn onílé tó ń bínú sí wa?
1 Èèyàn àlàáfíà làwa èèyàn Jèhófà. Ìhìn rere àlàáfíà la sì ń polongo fáráyé. (Aísá. 52:7) Àmọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà míì, a máa ń pàdé àwọn èèyàn tó ń bínú torí pé a wá wàásù fún wọn. Kí ló máa jẹ́ ká lè fi hàn pé a jẹ́ èèyàn àlàáfíà nígbà tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé?—Róòmù 12:18.
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lo ìfòyemọ̀?
2 Máa Lo Ìfòyemọ̀: Òótọ́ ni pé inú lè máa bí àwọn kan torí pé wọn ò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tá à ń wàásù. Àmọ́, ó lè máà jẹ́ iṣẹ́ ìwàásù wa ló ń bí àwọn míì nínú. Bóyá ṣe ni wọn ò ráyè lásìkò tá a wá yẹn. Ó sì lè jẹ́ pé ìṣòro tó ń bá wọn fínra ló jẹ́ kí wọ́n máa kanra. Kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ ìhìn rere tá à ń wàásù ni wọ́n ń bínú sí, ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ó lè jẹ́ ohun tí kò jóòótọ́ tí wọ́n gbọ́ nípa wa ló ń bí wọn nínú. (2 Kọ́r. 4:4) Tá a bá ń lo ìfòyemọ̀, èyí á jẹ́ ká lè máa ní sùúrù, a ò sì ní máa rò pé àwa ni wọ́n ń bínú sí.—Òwe 19:11.
3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún onílé?
3 Máa Bọ̀wọ̀ Fúnni: Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ló ní àwọn nǹkan tí wọ́n gbà gbọ́ tó sì fìdí múlẹ̀ gan-an lọ́kàn wọn. (2 Kọ́r. 10:4) Wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu bóyá wọ́n máa gbọ́ ọ̀rọ̀ wa tàbí wọn kò ní gbọ́ ọ. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú kéré ohun táwọn tá à ń wàásù fún gbà gbọ́. Ká má sì ṣe ka ara wa sí pàtàkì jù wọ́n lọ. Tí wọ́n bá sọ pé ká kúrò lọ́dọ̀ àwọn, ẹ jẹ́ ká fi ibẹ̀ sílẹ̀ wọ́ọ́rọ́wọ́.
4. Báwo la ṣe lè fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀?
4 Máa Fi Ohùn Pẹ̀lẹ́ Sọ̀rọ̀: Kódà tí wọ́n bá bú wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká fi ṣèbínú. Ohùn pẹ̀lẹ́ ló yẹ ká fi dáhùn, ká má ṣe sọ ohunkóhun tó lè tàbùkù sí wọn. (Kól. 4:6; 1 Pét. 2:23) Dípò ká bá wọn jiyàn, ibi tí èrò wa bá ti jọra ló máa dáa ká sọ̀rọ̀ lé lórí. A lè dọ́gbọ́n béèrè ìdí tí wọn kò fi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Nígbà míì sì rèé, ohun tó máa dáa jù ni pé ká fi ibẹ̀ sílẹ̀, kó má bàa dà bíi pé à ń bá wọn fa ọ̀rọ̀.—Òwe 9:7; 17:14.
5. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú jíjẹ́ èèyàn àlàáfíà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?
5 Tá a bá hùwà jẹ́jẹ́ tó fi hàn pé a jẹ́ èèyàn àlàáfíà, ẹni tá a fẹ́ bá sọ̀rọ̀ àmọ́ tí kò gbọ́ lè rántí ìwà wa, kó sì fetí sílẹ̀ nígbà míì. (Róòmù 12:20, 21) Ó tiẹ̀ lè pa dà wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́jọ́ kan láìka pé ó ti máa ń ta kò wá tẹ́lẹ̀. (Gál. 1:13, 14) Bóyá ẹni yẹn pa dà wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tàbí kò wá, tá a bá kó ara wa níjàánu, tá a sì fi hàn pé a jẹ́ èèyàn àlàáfíà, ìwà wa yóò fi ìyìn fún Jèhófà, yóò sì buyì kún ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá a fi ń kọ́ni.—2 Kọ́r. 6:3.