ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/06 ojú ìwé 1
  • Ẹ Má Ṣe Ṣojo Síbẹ̀, Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Má Ṣe Ṣojo Síbẹ̀, Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Jíjẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà?
    Jí!—2006
  • “Máa Wá Àlàáfíà, Kí o Sì Máa Lépa Rẹ̀”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Ǹjẹ́ O Ń Wàásù Láìṣojo?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
km 11/06 ojú ìwé 1

Ẹ Má Ṣe Ṣojo Síbẹ̀, Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà

1 Ọ̀pọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún ló máa ń fi tinútinú sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún wa, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yìí ta ko òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a gbọ́dọ̀ wàásù láìṣojo, síbẹ̀ a ní láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn” ká sì máa ṣọ́ra ká má bàa máa ṣẹ àwọn èèyàn láìnídìí. (Róòmù 12:18; Ìṣe 4:29) Báwo la ṣe lè jẹ́ aláìṣojo ká sì tún jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà bá a ṣe ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run?

2 Wá Ibi Tọ́rọ̀ Yín Ti Jọra: Ẹni tó bá lẹ́mìí àlàáfíà kì í fẹ́ jiyàn. Bá a bá kàn ń ta ko ohun tẹ́ni tá à ń bá sọ̀rọ̀ gbà gbọ́ láìnídìí, kò ní jẹ́ kó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa. Bó bá sọ ohun tá a mọ̀ pé kò tọ̀nà, ṣe ni ká fọgbọ́n mú kókó kan tá a jọ gbà wọnú ìjíròrò náà. Bó bá jẹ́ pé ohun tá a jọ gbà gbọ́ la sọ̀rọ̀ lé lórí, ó ṣeé ṣe ká lè mú ẹ̀tanú tó bá ní kúrò kí ọ̀rọ̀ wa sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.

3 Bá a bá jẹ́ kọ́rọ̀ tí ò tọ̀nà tẹ́ni náà sọ kọjá lọ bẹ́ẹ̀, ṣé kì í ṣe pé a gbà pé òótọ́ ló sọ tàbí pé ṣe là ń fomi la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ó tì o. Iṣẹ́ táwa Kristẹni gbà kì í ṣe láti máa ta ko gbogbo èrò òdì tá a bá gbọ́ táwọn èèyàn ń sọ, kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ́ ojúṣe wa ni láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Mát. 24:14) Dípò tá a ó fi gbaná jẹ nígbà tẹ́nì kan bá sọ ohun tá a mọ̀ pé kò tọ̀nà, ṣe là bá wo ohun tó sọ yẹn bí àǹfààní tá a fi lè mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀.—Òwe 16:23.

4 Fọ̀wọ̀ Wọn Wọ̀ Wọ́n: Àwọn ìgbà kan máa wà tá a ní láti fi àìṣojo àti ìgboyà já ẹ̀kọ́ èké nírọ́. Àmọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́mìí àlàáfíà, a ò ní máa bẹnu àtẹ́ lu àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀kọ́ tí ò tọ̀nà kọ́ àwọn èèyàn, a ò sì ní máa sọ̀rọ̀ àbùkù sí wọn. Àwọn èèyàn ò ní gbọ́ tiwa tá a bá ń ṣe bíi pé àwa la mọ̀ jù, ṣùgbọ́n bá a bá rẹ ara wa sílẹ̀ tá a sì ń fi pẹ̀lẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe káwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ sún mọ́ wa. Bá a bá ń fọ̀wọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún wọ̀ wọ́n tá ò sì bẹnu àtẹ́ lu ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ó máa jẹ́ kí wọ́n rí ara wọn bí ẹni iyì, á sì tipa bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn láti gba ọ̀rọ̀ tá a bá bá wọn sọ.

5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kíyè sí ìgbàgbọ́ àwọn tó wàásù fún, ó sì gbé ìhìn rere kalẹ̀ lọ́nà tó máa gbà wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Ìṣe 17:22-31) Tinútinú ló fi “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo” kó bàa lè “rí i dájú” pé òun “gba àwọn kan là.” (1 Kọ́r. 9:22) Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere láìṣojo.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́