Ojú Ìwòye Bíbélì
Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Jíjẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà?
NÍNÚ ìwàásù tá a mọ̀ bí ẹní mowó yẹn, èyí tí Jésù Kristi ṣe lórí òkè, ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” Ó tún sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5, 9) Ohun tó ń jẹ́ pé èèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà kọjá kéèyàn jẹ́ ẹni tí kì í fàjàngbọ̀n, tàbí ẹni tára ẹ̀ balẹ̀. Ẹni tó jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà máa ń fẹ́ ṣe dáadáa sáwọn èèyàn ó sì máa ń sa gbogbo ipá ẹ̀ láti rí i pé àlàáfíà jọba níbi tóun bá wà.
Lákòókò tiwa yìí, ṣó ṣeé ṣe láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù tá a kọ sókè yẹn ṣá? Àwọn kan rò pé kéèyàn tó lè rọ́wọ́ mú lóde òní, ojú ẹ̀ ní láti le ó sì gbọ́dọ̀ lágídí, kódà tó bá dójú ẹ̀ kó dà á síjà. Ṣé ohun tó mọ́gbọ́n dání jù ni pé kéèyàn fagídí pàdé agídí? Àbí ó ṣàǹfààní kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà? Ẹ jẹ́ ká wo ìdí mẹ́ta tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Jésù náà rò, èyí tó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.”
◼ Ó Ń FINI LỌ́KÀN BALẸ̀ Òwe 14:30 sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” Ọ̀pọ̀ ìròyìn látọ̀dọ̀ àwọn oníṣègùn fi hàn pé ìbínú àti dídi kùnrùngbùn lè ṣokùnfà àrùn rọpárọsẹ̀ àti àrùn ọkàn. Nígbà tí ìwé ìròyìn àwọn oníṣègùn kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn èèyàn tí wọ́n ní àrùn ọkàn, ó sọ pé ìbínú tó ń bú jáde dà bíi májèlé. Ìwé ìròyìn náà tún sọ pé “téèyàn bá ń bínú torí ẹ̀ fi ń gbóná, ó lè ní àìsàn táá mú ara ẹ̀ máa gbóná.” Àmọ́ àwọn tó ń lépa àlàáfíà lè ní “ọkàn-àyà píparọ́rọ́” kí wọ́n sì jàǹfààní rẹ̀.
Àpẹẹrẹ irú ẹ̀ ni ti bàbá kan tó ń jẹ́ Jim tó ti ń fi Bíbélì kọ́ni báyìí, tó sì ń gbé láàárín àwọn èèyàn tó ń sọ èdè Vietnamese lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Bàbá tó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta yìí sọ pé: “Lẹ́yìn tí mo ti lo ọdún mẹ́fà lẹ́nu iṣẹ́ ológun tí mo sì ti bá wọn dé ojú ogun lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè Vietnam, ohun tó ń jẹ́ ìwà ipá, ìbínú àti ìjákulẹ̀ kò ṣàjèjì sí mi mọ́. Àwọn nǹkan tí mo ti là kọjá sẹ́yìn bẹ̀rẹ̀ sí í kó ìdààmú bá mi débi tí mi ò fi lè sùn bó ṣe yẹ. Kò pẹ́ tí ara fi bẹ̀rẹ̀ sí ni mí, tí iṣan ara mi ò ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ tí inú sì ń dà mí láàmú.” Kí ló wá fún un ní ìtura o? Ó dáhùn pé: “Ẹ̀kọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ mi ló gba ẹ̀mí mi là. Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run ní in lọ́kàn láti mú ayé tuntun alálàáfíà wá, tí mo tún kọ́ nípa bí mo ṣe lè gbé ‘àkópọ̀ ìwà tuntun’ wọ̀, pẹ̀sẹ̀ lọkàn mi balẹ̀. Ara mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í yá sí i.” (Éfésù 4:22-24; Aísáyà 65:17; Míkà 4:1-4) Ọ̀pọ̀ àwọn míì ló ti rí i látinú ohun tójú wọn rí pé téèyàn bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, ó máa mú kó túbọ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn àti okunra, á sì mú kí onítọ̀hún sún mọ́ Ọlọ́run.—Òwe 15:13.
◼ Ó MÁA Ń JẸ́ KÉÈYÀN RẸ́NI GIDI BÁ ṢỌ̀RẸ́ Tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, àárín àwa àtàwọn èèyàn á máa gún régé. Bíbélì sọ pé ká ‘mú gbogbo . . . ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ wa pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.’ (Éfésù 4:31) Àwọn tó máa ń hùwà jàgídíjàgan sábà máa ń fi ìwà wọn lé àwọn èèyàn sá lára wọn tí wọ́n á sì wá rí ara wọn bíi kò-rẹ́ni-bá-rìn tí kò ní ọ̀rẹ́ tó lè gbára lé. Òwe 15:18 sọ pé: “Ènìyàn tí ó kún fún ìhónú ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ẹni tí ó lọ́ra láti bínú ń mú aáwọ̀ rọlẹ̀.”
Alàgbà ni Arákùnrin Andy, tó jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógójì nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú New York City. Inú jàgídíjàgan ló dàgbà sí. Ó ṣàlàyé pé: “Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni mí nígbà tí wọ́n ti fi mí sójú agbo ẹ̀ṣẹ́ kíkàn. N kì í ka àwọn tí mo fẹ́ bá jà séèyàn. Gbogbo èrò mi ni pé ‘kí n gbá èèyàn lẹ́ṣẹ̀ẹ́ tàbí kí wọ́n kàn mí lẹ́ṣẹ̀ẹ́.’ Nígbà tó yá mo bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́. Àìmọye ìjà ìgboro àti rògbòdìyàn ni mo bá wọn dá sí. Àwọn ìgbà kan wà tí wọ́n ti gbé ìbọn sí mi létí rí, wọ́n sì ti yọ̀bẹ sí mi rí pẹ̀lú. Oníwàhálà ló pọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń kó kiri, inú fu ẹ̀dọ̀ fu la sì fi ń bá ara wa lò.”
Kí ló mú kí Andy wá máa lépa àlàáfíà báyìí? Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan mo lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ojú ẹsẹ̀ tí mo débẹ̀ ni mo rí i pé ìfẹ́ wà láàárín àwọn tó wà níbẹ̀. Látìgbà náà wá ni mo ti ń fara mọ́ àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ àlàáfíà yìí, bí mo sì ṣe ń bá wọn rìn ti mú kí n ní ọkàn tó pa rọ́rọ́, ó sì ti mú kí n gbé èrò tí kò dáa tí mo ní tẹ́lẹ̀ kúrò lọ́kàn. Mo ti lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀ tá a lè jọ wà fún ara wa pẹ́.”
◼ Ó Ń FÚN ÈÈYÀN NÍ ÌRÈTÍ ỌJỌ́ IWÁJÚ Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ lára ìdí tó fi yẹ kéèyàn jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ni pé ó ń fi ọ̀wọ̀ hàn fún ohun tí Ẹlẹ́dàá wa sọ pé òun fẹ́ ṣe. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ rọ̀ wá pé: “Máa wá ọ̀nà láti rí àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.” (Sáàmù 34:14) Téèyàn bá gbà pé Jèhófà Ọlọ́run wà, tó ń kọ́ nípa àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó ń fúnni ní ìyè tó sì ń tẹ̀ lé wọn, onítọ̀hún á di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Tá a bá sì wá di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run wàyí, a ó jèrè “àlàáfíà Ọlọ́run.” Àlàáfíà tó ga jù sì lèyí torí pé kò sí ìṣòro tí ìgbésí ayé lè mú wá tó lè borí ẹ̀.—Fílípì 4:6, 7.
Síwájú sí i, tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, à ń fi irú ẹni tá a fẹ́ jẹ́ han Jèhófà. A ó lè fi han Ọlọ́run nísinsìnyí pé a ó lè fara mọ́ bí ìgbésí ayé á ṣe rí nínú ayé tuntun alálàáfíà tó ṣèlérí. Nígbà tó bá mú àwọn ẹni ibi kúrò tó sì mú kí àwọn onínú tútù “jogún ilẹ̀ ayé,” gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí, ojú wa ló máa ṣe. Ìbùkún ńlá nìyẹn á mà jẹ́ o!—Sáàmù 37:10, 11; Òwe 2:20-22.
A wá rí i kedere báyìí pé ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání ni Jésù sọ nígbà tó sọ pé “aláyọ̀ ni àwọn ẹlẹ́mìí àlàáfíà.” A lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn, àjọṣe tó dán mọ́ràn àti ìrètí tó dájú fún ọjọ́ iwájú. Àwọn ìbùkún yìí á jẹ́ tiwa tá a bá lè sa gbogbo ipá wa láti “jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
“Ara mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í yá sí i”—Jim
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Mo ti lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀ tá a lè jọ wà fún ara wa pẹ́.”—Andy