Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 19
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 19
Orin 47 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 19 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Onídàájọ́ 1-4 (8 min.)
No. 1: Onídàájọ́ 3:1-11 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Báwo Lo Ṣe Lè Mọ Ọlọ́run?—igw ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
No. 3: Báwo Ni Ẹ̀mí Ṣe Ń Pa Dà Sọ́dọ̀ Ọlọ́run?—Oníw. 12:7 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa “sìnrú fún Olúwa pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú títóbi jù lọ.”—Ìṣe 20:19
10 min: Ǹjẹ́ Ò Ń Lo Ìwé Ìwádìí? Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Báwo ni Ìwé Ìwádìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tí a bá ń ka (a) Àwọn Onídàájọ́ 16:1-3 (b) Lúùkù 6:17 àti (d) Róòmù 15:19? (2) Báwo ni Ìwé Ìwádìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè lóye àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní kíkún (a) “ómérì” àti “eéfà (Ẹ́kís. 16:32, 36),” (b) “tálẹ́ńtì (Mát. 25:15),” àti (d) “Ábíbù” àti “Nísàn (Diu. 16:1)”? Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún gbogbo àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n máa lo ìwé yìí dáadáa.
10 min: Ó Gba Pé Ká Máa Ní Sùúrù Ká Sì Lo Ìdánúṣe Bá A Ṣe Ń Sìnrú fún Olúwa. Ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Ọdọọdún 2014, ojú ìwé 59, ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 62, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 67, ìpínrọ̀ 2. Ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Máa Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 20 àti Àdúrà