Orin 20
Bù Kún Ìpéjọ Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Wá bù kún wa báa ti ńpé jọ,
Jèhófà àwa ńbẹ̀ ọ́.
A dúpẹ́ fún ìpàdé wa;
Kẹ́mìí rẹ wà pẹ̀lú wa.
2. Olúwa, jẹ́ ká mọ̀ ọ́ sìn;
Fọ̀rọ̀ rẹ kún inú wa.
Kọ́ ahọ́n wa láti jẹ́rìí;
Fi ìfẹ́ kún ọkàn wa.
3. Baba, bù kún ìpàdé wa;
Ká lálàáfíà, ìṣọ̀kan.
Kí ọ̀rọ̀ àti ìwà wa
Gbé ọlá Ọba rẹ ga.
(Tún wo Sm. 22:22; 34:3; Aísá. 50:4.)