ORIN 93
Bù Kún Ìpàdé Wa
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ìbùkún rẹ ṣe pàtàkì
Bá a ṣe ń pé jọ fún ‘jọsìn.
A bẹ̀bẹ̀ pé kó o bù kún wa,
Kẹ́mìí rẹ wà pẹ̀lú wa.
2. Jọ̀ọ́, Jèhófà, fi Ọ̀rọ̀ rẹ
Kọ́ wa, kó wọ̀ wá lọ́kàn.
Kọ́ ahọ́n wa ká lè jẹ́rìí,
Ká lè jọ́sìn rẹ dáadáa.
3. Jèhófà, bù kún ‘pàdé wa,
Jọ̀ọ́, jẹ́ ká wà níṣọ̀kan.
Kí ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa
Máa gbé orúkọ rẹ ga.
(Tún wo Sm. 22:22; 34:3; Àìsá. 50:4.)