À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ
Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé
ILẸ̀ 47
IYE ÈÈYÀN 4,282,178,221
IYE AKÉDE 74,011
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 672,318
Ìrànlọ́wọ́ fún Ọkùnrin Kan Tó Fọ́jú, Tó Dití Tó sì Yadi
Lọ́dún 1999, ìjọ tó ń sọ èdè àwọn adití ní ìlú Kobe, lórílẹ̀-èdè Japan, gbọ́ pé adití kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hirofumi. Nígbà tí arákùnrin kan lọ sílé Hirofumi, ìyá rẹ̀ kò jẹ́ kí arákùnrin náà rí i. Arákùnrin náà lọ síbẹ̀ léraléra, ó sì bẹ ìyá rẹ̀ pé kó jẹ́ kóun rí i, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó mú Hirofumi wá bá a lẹ́nu ọ̀nà. Irun orí rẹ̀ kún, ó sì tún dá irùngbọ̀n sí, ó wá rí wúruwùru. Ṣe ló dà bí ẹni tí wọ́n pa tì sí aṣálẹ̀ kan fún àìmọye ọdún. Kò sunkún bẹ́ẹ̀ ni kò rẹ́rìn-ín. Yàtọ̀ sí pé adití ni Hirofumi, ó tún fọ́jú. Arákùnrin náà ò kọ́kọ́ mọ ibi tóun ì bá ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ó mú ọwọ́ Hirofumi ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe àpèjúwe lédè àwọn adití. Kò tiẹ̀ ṣohun tó fi hàn bóyá ohun tí arákùnrin náà ń sọ yé e tàbí kò yé e. Ó ti pẹ́ tí Hirofumi ti dá wà, kò sì tíì bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ láti ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn tí ojú rẹ̀ ti fọ́ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31].
Nígbà tí arákùnrin náà pa dà wá lọ́jọ́ kẹta, ó ya ìyá Hirofumi lẹ́nu gan-an, torí ó ti rò pé arákùnrin náà ò ní pa dà wá nígbà tó ti rí ipò tí ọmọ òun wà. Arákùnrin náà tún bẹ ìyá Hirofumi pé kó jẹ́ kí òun rí i, ìyá rẹ̀ tún mú un wá sẹ́nu ọ̀nà. Lẹ́yìn tó pé oṣù kan tí arákùnrin wa ti ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, síbẹ̀ tí kò sí ìyípadà kankan, ìyá Hirofumi sọ fún arákùnrin náà pé kó má yọ ara ẹ̀ lẹ́nu mọ́. Àmọ́, arákùnrin náà ò yé pa dà lọ. Ó máa ń mú kéèkì lọ fún Hirofumi, ó sì máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kó mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àmọ́ lẹ́yìn oṣù méjì míì tí kò sí ìyípadà kankan, ó ṣe arákùnrin náà bíi pé àṣedànù lòun ń ṣe.
Arákùnrin náà pinnu láti lọ síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣùgbọ́n kó tó lọ, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kóun mọ̀ bóyá ó yẹ kí òun ṣì máa lọ síbẹ̀. Nígbà tí arákùnrin náà débẹ̀, ó di Hirofumi lọ́wọ́ mú, ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ sọ fún un pé Ọlọ́run kan wà tó ń jẹ́ Jèhófà, gbogbo ìgbà ló sì ń wò ó láti ọ̀run, ó mọ̀ ọ́n ju ẹnikẹ́ni mìíràn lọ, ó sì mọ̀ pé ó ń jìyà. Ó tún sọ fún un pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ yọ ọ́ kúrò nínú wàhálà. Ìdí nìyẹn tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Hirofumi ò tiẹ̀ kọ́kọ́ ṣe bíi pé ohun tí arákùnrin náà ń sọ yé e; àmọ́ nígbà tó yá ó di ọwọ́ arákùnrin náà mú gírígírí, omijé sì rọra já bọ́ lójú rẹ̀. Ohun tó ṣelẹ̀ yìí wọ arákùnrin náà lọ́kàn débi pé òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn.
Lẹ́yìn tí Hirofumi ti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mọ́kànlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ ìjọ tó wà ládùúgbò rẹ̀, kò sì rin ìrìn àjò lọ sí ìjọ àwọn adití tó wà lọ́nà jíjìn mọ́. Àwọn tó wà nínú ìjọ tó dara pọ̀ mọ́ yìí kò mọ èdè àwọn adití, àmọ́ lẹ́yìn ọdún kan àbọ̀, àwọn arákùnrin àti arábìnrin méjìlélógún [22] nínú ìjọ yẹn ló kọ́ èdè àwọn adití kí wọ́n lè máa túmọ̀ ìpàdé fún Hirofumi. Oṣù January 2012 ni Hirofumi kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ẹnì kan sì túmọ̀ ohun tó sọ. Ní oṣù October ọdún yẹn, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.
Ó Ń Kọ́ Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Orílẹ̀-èdè Philippines ni Floren ń gbé, aṣáájú-ọ̀nà sì ni. Ó kéré tán, ó tó èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣù, ẹ̀ṣọ́ sì ni èyí tó pọ̀ jù lára wọn. Ìrọ̀lẹ́ làwọn ọkùnrin yìí sábà máa ń ṣiṣẹ́, àwọn kan sì máa ń ṣiṣẹ́ mọ́jú. Torí náà, ó gba pé kí Floren máa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà láwọn àkókò tó máa rọrùn fún wọn. Torí náà, ó máa ń lọ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà níbi iṣẹ́ wọn lákòókò ìsinmi wọn tàbí lákòókò míì tó bá rí i pé kò ní dí iṣẹ́ wọn lọ́wọ́. Ó máa ń kọ́ àwọn kan lẹ́kọ̀ọ́ lálaalẹ́ ní nǹkan bí aago méje sí mọ́kànlá, ó sì ń kọ́ àwọn míì ní nǹkan bí aago márùn-ún ìdájí sí aago mẹ́sàn-án àárọ̀. Nígbà míì, ó máa ń ṣètò àkókò rẹ̀ kó lè débẹ̀ nígbà tó bá kù díẹ̀ kí wọ́n gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn. Èyí máa ń jẹ́ kó lè kọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ tó bá fẹ́ gbaṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́, lẹ́yìn náà á wá kọ́ ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ náà lẹ́kọ̀ọ́. Floren sọ pé: “Bí mo ṣe ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ń fún mi láyọ̀ jù lọ.” Ní báyìí, àwọn kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ náà ti ń lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀kan lára àwọn tí Floren kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti ṣe ìrìbọmi, ó sì ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.
Orílẹ̀-èdè Philippines: Floren ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárọ̀ kùtùkùtù
Wọ́n Pinnu Láti Wá Wọn Lọ
Lọ́jọ́ kan tí òjò ń rọ̀, àwọn arábìnrin méjì kan wà lóde ẹ̀rí ní orílẹ̀-èdè Àméníà, wọ́n pàdé ìyá kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ lójú ọ̀nà, wọ́n sì fún wọn ní ìwé àṣàrò kúkúrú kan. Orúkọ ìyá náà ni Marusya, ọmọbìnrin rẹ̀ sì ń jẹ́ Yeva. Ó ya àwọn arábìnrin wa lẹ́nu nígbà tí obìnrin náà sọ fún wọn pé wákàtí méjì ni òun àti ọmọbìnrin òun fi wà nínú òjò kí àwọn lè rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí nìdí? Nígbà tí ẹ̀gbọ́n Marusya wà lẹ́wọ̀n, ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n tì mọ́lé nítorí pé wọn ò dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Marusya ti rò pé tí ẹ̀gbọn òun bá fi máa pa dà dé láti ẹ̀wọ̀n ọkàn rẹ̀ á ti le gan-an, á sì ti di òǹrorò ẹ̀dá. Àmọ́ ṣe ló ti wá di ọmọlúwàbí, ara rẹ̀ sì balẹ̀. Bó sì ṣe ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́, ó ṣe àwọn ìyípadà míì tó mú kí ìgbésí ayé rẹ̀ sunwọ̀n sí i. Gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ya Marusya àti ọmọbìnrin rẹ̀ lẹ́nu, ìdí sì ni pé kì í ṣèní kì í ṣàná ni wọ́n ti ń rí àwọn ìwé táwọn èèyàn máa ń lẹ̀ káàkiri àti ọ̀rọ̀ burúkú táwọn kan máa ń sọ lórí tẹ́lifíṣọ̀n láti ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́. Ṣùgbọ́n Yeva wá ń ronú pé: ‘Èèyàn dáadáa ni ẹ̀gbọ́n mọ́mì mi. Kí ló wá dé tí wọ́n fi ń sọ ọ̀rọ̀ burúkú tó pọ̀ tóyẹn nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?’ Ó fẹ́ rídìí ọ̀rọ̀ yìí, torí náà, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Kò sí bá a ṣe lè mọ òtítọ́ nípa àwọn aráabí yìí àfi tá a bá wá wọn lọ. Ẹ yáa jẹ́ ká wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́ báyìí, kí ọ̀rọ̀ yìí bàa lè yanjú.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ni wọ́n sì ń wá lọ́jọ́ yẹn tí wọ́n fi pàdé àwọn arábìnrin wa. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ìyá àti ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé, wọ́n sì ti tẹ̀ síwájú débi pé wọ́n ti di akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi.
Àwọn Ọmọ Kan Ló Mú Ìwé Ìròyìn Náà Wá
Ìlú Istanbul, lórílẹ̀-èdè Tọ́kì: Arákùnrin kan ń lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ nígbà tó ń wàásù lójú pópó
Obìnrin kan wà nílùú Adana, lórílẹ̀-èdè Tọ́kì. Ìṣòro ńlá kan ń bá obìnrin yìí fínra, wàhálà sì wà nínú ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú. Ìṣòro yìí le débi pé ó tiẹ̀ ti fẹ́ pa ara rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ó rí méjì lára àwọn ìwé ìròyìn wa lẹ́nu ọ̀nà rẹ̀. Ó jọ pé, àwọn ọmọ kan ládùúgbò ló rí àwọn ìwé náà nílẹ̀, wọ́n sì fi wọ́n sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ torí wọ́n rò pé òun ló ni ín. Ìtàn ìgbésí ayé àwọn èèyàn tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà wọ obìnrin yìí lọ́kàn gan-an, ó sì wù ú pé kí ìgbésí ayé tiẹ̀ pẹ̀lú yí pa dà kó sì dà bíi tiwọn. Obìnrin náà pe nọ́ńbà fóònù tí wọ́n kọ sí ẹ̀yìn ọ̀kan lára àwọn ìwé náà, ó sì wá jẹ́ nọ́ńbà arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń gbé nítòsí. Bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn. Obìnrin yìí mọyì ohun tó kọ́, ó sì sọ pé òun fẹ́ máa lọ sí ìpàdé. Ó wá rí i pé Gbọ̀ngàn Ìjọba ò jìnnà rárá sí ilé òun. Látìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé.
Ó Lo Ọjọ́ Mẹ́wàá Lẹ́wọ̀n, Síbẹ̀ Ó Dúró Lórí Ìpinnu Rẹ̀
Ọkùnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Nepal tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bam. Ọlọ́pàá ni, ó sì máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Lọ́jọ́ kan nígbà tó wà lẹ́nu iṣẹ́, ó pàdé tọkọtaya kan lọ́nà tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé Bíbélì ni tọkọtaya náà fi ń dáhùn àwọn ìbéèrè tó bi wọ́n. Bam gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sáwọn ìpàdé. Bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i, ẹ̀rí ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í dà á láàmú nítorí iṣẹ́ tó ń ṣe, ó wá ní káwọn ọ̀gá òun jẹ́ kí òun máa ṣiṣẹ́ ọ́fíìsì, torí pé ìyẹn ò ní gba pé kó máa gbé ìbọn àtàwọn nǹkan ìjà míì. Àwọn ọ̀gá rẹ̀ gbà pé kó máa ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì. Lẹ́yìn tó lọ sí àpéjọ àgbègbè, ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í dà á láàmú, torí náà ó pinnu láti fi iṣẹ́ ọlọ́pàá sílẹ̀ pátápátá.
Inú ìyàwó Bam kò dùn sí ìpinnu tí ọkọ rẹ̀ ṣe yìí. Ìdí sì ni pé yàtọ̀ sí pé iṣẹ́ ọlọ́pàá níyì láwùjọ, wọ́n tún ń gbowó tó pọ̀, owó ìfẹ̀yìntì tí wọ́n ń gbà pẹ̀lú kì í ṣe kékeré láfikún sí àwọn àǹfààní míì. Kí Bam má bàa fi iṣẹ́ ọlọ́pàá sílẹ̀, ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé, “Tó o bá dúró sẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá, èmi náà á kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Nígbà tí ọkọ rẹ̀ ò ṣe ohun tó fẹ́, ó rọ ọ̀gá ọlọ́pàá pé kó ju ọkọ òun sẹ́wọ̀n, ó rò pé ìyẹn máa mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà. Lẹ́yìn tí Bam lo ọjọ́ mẹ́wàá lẹ́wọ̀n, wọ́n fi í sílẹ̀, síbẹ̀ ńṣe ló pinnu láti wá iṣẹ́ míì. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wa kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta, èyí sì gba pé kó máa fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣiṣẹ́ nínú oòrùn. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, inú rẹ̀ dùn. Ó ń tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ó sì di akéde. Nígbà tó yá, àtakò ìyàwó rẹ̀ rọlẹ̀. Torí ìfẹ́ táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin nínú ìjọ fi hàn sí i, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bam ṣì ń pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò, owó tó sì ń rí báyìí bó ṣe ń wa kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́sẹ̀ mẹ́ta pọ̀ ju owó tó ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ọlọ́pàá lọ. Ó ṣèrìbọmi ní àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní February ọdún 2013, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sì ti ń tẹ̀ lé e lọ sípàdé báyìí.
Orílẹ̀-èdè Nepal: Nígbà tí Bam wá iṣẹ́ míì, èyí jẹ́ kí òun àti ìdílé rẹ̀ túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run
Ó Fẹ́ Di Aṣáájú-Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́
Arábìnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Kòríà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Myeong-hee. Ẹsẹ̀ rẹ̀ kan rọ nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjì, torí náà ẹsẹ̀ yẹn ṣì ń fún un níṣòro títí di báyìí. Ó máa ń tètè rẹ̀ ẹ́, ó sì máa ń ṣubú nígbà míì. Bákan náà, àyà rẹ̀ sábà máa ń já, àwọn oògùn tó ń lò sì tún máa ń fa àwọn ìṣòro míì. Myeong-hee kì í lè mí dáadáa, ó tún máa ń dùn-ún gan-an bí ọkàn rẹ̀ ò ṣe balẹ̀ tí àyà rẹ̀ sì máa ń já. Pẹ̀lú gbogbo ìṣòro tí Myeong-hee ní yìí, ó ṣì ń wù ú láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó ti lé lọ́dún méjì báyìí tó ti jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ oṣooṣù ló ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún òun lókun láti ṣe ìpín tòun lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.
“Mo Ti Ń Wá A Láti Ọgbọ̀n Ọdún Sẹ́yìn!”
Arábìnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Indonesia tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agnes. Míṣọ́nnárì ni arábìnrin yìí, ó sì máa ń wàásù fún obìnrin aboyún kan tó jẹ́ ẹni ogójì [40] ọdún tó ń ta ewébẹ̀ lọ́jà. Obìnrin náà fẹ́ràn láti máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa, ó sì máa ń gbà kí wọ́n jọ jíròrò Bíbélì tí ọwọ́ rẹ̀ ò bá fi bẹ́ẹ̀ dí. Lọ́jọ́ kan tí Agnes lọ sí ìsọ̀ obìnrin náà, kò bá a níbẹ̀. Ọkọ rẹ̀ wá sọ fún un pé ìyàwó òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ni. Agnes lọ kí i. Ó fi nǹkan wé Ìwé Ìtàn Bíbélì, ó sì fi ṣe ẹ̀bùn fún un. Ó ya obìnrin náà lẹ́nu pé Agnes wá rí òun àti ọmọ òun, inú rẹ̀ sì dùn gan-an. Àmọ́ ohun tó yà á lẹ́nu jù ni ẹ̀bùn tí Agnes fún un. Obìnrin náà tú ìwé náà, ó wò ó tìyanutìyanu, ó sì sọ pé: “Ibo lo ti rí ìwé yìí? Mo ti ń wá a láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn! Gbogbo ilé ìtàwé ni mo ti wá a lọ, mo sì bi gbogbo èèyàn. Mi ò rí i lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni, kò sẹ́ni tó mọ̀ ọ́n, kò sí ìwé míì tó dà bíi rẹ̀.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé nígbà tí obìnrin náà wà lọ́mọdé, àbúrò ìyá rẹ̀ kan ní Ìwé Ìtàn Bíbélì, ó sì fẹ́ràn láti máa kà á. Obìnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé náà báyìí, ọmọbìnrin rẹ̀ àgbà pẹ̀lú sì fẹ́ràn ìwé náà. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn méjèèjì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Orílẹ̀-èdè Indonesia: Ìwé tí Agnes fi ṣe ẹ̀bùn ló wà lọ́wọ́ rẹ̀ yìí