ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 53-58
  • Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Wọ́n Ní Kí Tọkọtaya Kan Wá sí Ilé Àwọn
  • Ohun Tó Nílò Gan-an Nìyí
  • Ọdún Mẹ́rin Ló Fi Dá Nìkan Wàásù
  • Ó Gbèjà Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ ní Iléèwé
  • Okùn Bàtà Rẹ̀ Já Lákòókò Tó Yẹ
  • Ẹnì Kan Ṣoṣo Ló Lè Dá A Dúró Kó Má Wàásù Mọ́
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 53-58
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 53]

Ìlú Havana, ní Cuba

À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

  • ILẸ̀ 57

  • IYE ÈÈYÀN 970,234,987

  • IYE AKÉDE 3,943,337

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,341,698

Wọ́n Ní Kí Tọkọtaya Kan Wá sí Ilé Àwọn

Àwọn tọkọtaya kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé ní ìlú Las Vegas, ní ìpínlẹ̀ Nevada, àmọ́ wọ́n ń wá ibi tó pa rọ́rọ́ tí wọ́n lè máa gbé, torí náà wọ́n ta ilé wọn kí wọ́n lè ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Dominican Republic. Àmọ́, ó di dandan kí wọ́n kó kúrò nílé wọn yẹn ní ọjọ́ mẹ́wàá ṣáájú ọjọ́ tí wọ́n máa wọ ọkọ̀ òfuurufú. Àwọn aládùúgbò wọn kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá ní kí wọ́n wá sí ilé àwọn. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀ wọ́n bá àwọn Ẹlẹ́rìí yìí lọ sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́ẹ̀kan. Ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí wọ́n gbọ́ tí wọ́n mẹ́nu kan ọdún 1914, wọ́n sì fẹ́ mọ̀ sí i nípa rẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé ọdún yẹn ṣe pàtàkì nínú ìtàn aráyé. Nígbà tí wọ́n dé orílẹ̀-èdè Dominican Republic, wọ́n ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ wọn wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọdún kan àti oṣù méjì, àwọn méjèèjì ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi.

Ohun Tó Nílò Gan-an Nìyí

Nígbà tí wọ́n pàtẹ ìwé láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè lágbàáyé síbì kan ní ìlú Panama, lórílẹ̀-èdè Panama lọ́dún 2012, àwọn ará wa náà pàtẹ àwọn ìwé wa síbẹ̀. Àwọn ọmọbìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ ọmọléèéwé wá síbi táwọn ará wa kó ìwé sí. Ọ̀kan nínú wọn sọ fún arábìnrin tó wà níbi tá a pàtẹ àwọn ìwé wa sí pé inú òun ò dùn. Ọmọbìnrin náà sọ pé oògùn olóró ti di bárakú fún bàbá òun, òun ò sì mọ nǹkan tóun lè ṣe sí i. Arábìnrin náà fi orí 23 hàn án nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, tó ní àkọlé náà: “Bí Òbí Mi Bá Ń Mutí Lámujù Tó Sì Ń Lòògùn Olóró Ńkọ́?” Ọmọbìnrin náà sọ pé: “Ohun tí mo nílò gan-an nìyí!” Àwọn ọmọbìnrin náà gbá arábìnrin wa mọ́ra, wọ́n sì tún pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́yìn wákàtí kan. Ní ọjọ́ márùn-ún tí wọ́n fi pàtẹ àwọn ìwé náà, àwọn ará wa fi ìwé ńlá ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́rìndínláàádọ́ta [1,046] sóde, wọ́n tún fi ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́rìndínlọ́gọ́fà [1,116] ìwé ìròyìn sóde pẹ̀lú irinwó ó lé mọ́kàdínláàádọ́ta [449] ìwé pẹlẹbẹ. Àwọn èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56] ló kọ àdírẹ́sì ilé wọn sílẹ̀ kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè wá sọ́dọ̀ wọn.

Ọdún Mẹ́rin Ló Fi Dá Nìkan Wàásù

Àdúgbò àdádó kan tó wà lórí òkè kan lórílẹ̀-èdè Costa Rica ni Fredy ń gbé, èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ sì ni Cabecar. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, Fredy gba ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àti ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ní ìlú San José tó jẹ́ olú ìlú wọn. Akéde tó fún un ní àwọn ìwé náà sọ fún un pé kó pa dà lọ sí abúlé rẹ̀ láti lọ wàásù fún àwọn èèyàn rẹ̀. Torí náà ó pa dà lọ, ó dá kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ó sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Lára àwọn àtúnṣe tó ṣe ni pé, ó fi orúkọ ìgbéyàwó rẹ̀ sílẹ̀ lábẹ́ òfin. Lẹ́yìn náà, ó kọ́ àwọn èèyàn Cabecar lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ níbi tí òye rẹ̀ gbé e dé.

Fredy ṣètò ilé ẹ̀kọ́ kan fún àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kíláàsì mẹ́fà ni ilé ẹ̀kọ́ náà ní, ó sì máa ń ṣe ìdánwò fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kó lè mọ bí ìmọ̀ tí wọ́n ní nípa Bíbélì ṣe pọ̀ tó, ìyẹn ló máa fi pinnu kíláàsì tó yẹ kí kálukú wà. Ó ṣètò àwọn ìpàdé, ó tiẹ̀ ṣe Ìrántí Ikú Kristi pàápàá, òun ló sì ń ṣe ìwé ìkésíni tí wọ́n máa ń pín. Ohun tó máa ń kọ sí i ni: “Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ké sí ọ pé kó o wá ṣe Ìrántí Ikú Kristi pẹ̀lú wa.” Ọdún mẹ́rin ló fi ṣe gbogbo èyí, kò sì rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan ní gbogbo àkókò yẹn! Àmọ́, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí òun láti wá ran òun lọ́wọ́.

Láìpẹ́ yìí, Jèhófà dáhùn àdúrà Fredy. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lọ sí àdúgbò rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrìn àjò náà kò rọrùn. Nígbà tí wọ́n rí gbogbo ohun tó ti ṣe, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an ni. Wọ́n sọ pé, “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Fredy kò tíì ṣèrìbọmi, ìgbé ayé rẹ̀ ò yàtọ̀ sí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Lẹ́yìn oṣù mẹ́ta péré, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Kí Fredy lè ṣe ìrìbọmi, ó ní láti sọ̀ kalẹ̀ lórí òkè tí wọ́n ń gbé, òun àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ mọ́kàndínlógún [19] sì lọ sí àpéjọ àgbègbè tó máa kọ́kọ́ ṣe. Ní báyìí, ó ti ṣètò àwùjọ mẹ́ta míì tó ń sọ èdè Cabecar sí àwọn àdádó tó tiẹ̀ tún jìnnà ju ibi tó ń gbé lọ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 55]

Orílẹ̀-èdè Costa Rica: Fredy ti di aṣáájú-ọ̀nà déédéé báyìí, ó sì máa ń lọ sọ́nà jíjìn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ó Gbèjà Ìgbàgbọ́ Rẹ̀ ní Iléèwé

Lọ́jọ́ kan, Anna tó ń lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ní láti gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ nígbà tí àwọn ojúgbà rẹ̀ bínú sí i nítorí kò gba ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan gbọ́. Anna ṣàlàyé pé: “Ṣe ni wọ́n pé lé mi lórí, àmọ́ mo dákẹ́ torí mi ò fẹ́ ṣe ohun tó máa mú káwọn tó ń wò mí ní èrò tí kò tọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún òun nígboyà, ó sì ṣè ìwádìí nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Nígbà tó di ọjọ́ kejì, Anna mú Bíbélì rẹ̀ wá sí iléèwé. Àwọn ọmọléèwé rẹ̀ yí i ká, púpọ̀ nínú wọn ń fi í ṣe yẹ̀yẹ́. Síbẹ̀, ó fìgboyà ka àwọn ẹsẹ Bíbélì mélòó kan fún wọn, ó sì bá wọn fèrò wérò. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn tó ti ń bá a jiyàn panu mọ́. Ẹni tó jẹ́ abẹnugan àwọn alátakò náà ni olórí kíláàsì wọn, àmọ́ òun alára sọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé òun ti wá bọ̀wọ̀ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Jálẹ̀ sáà ẹ̀kọ́ ọdún yẹn, ó bi Anna ní oríṣiríṣi ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.

Okùn Bàtà Rẹ̀ Já Lákòókò Tó Yẹ

Obìnrin kan lórílẹ̀-èdè Barbados ń rìn lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láàárọ̀ ọjọ́ Sunday kan, nígbà tí okùn bàtà rẹ̀ já. Ó lọ sí ilé kan nítòsí, ó sì béèrè bóyá wọ́n ní abẹ́rẹ́ tí òun lè fi mú bàtà òun. Arábìnrin wa kan àti ọmọbìnrin rẹ̀ ló ń gbé ilé náà. Nígbà tí obìnrin náà ń tún bàtà rẹ̀ ṣe, arábìnrin wa ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe ń ṣẹ lónìí fún un. Ọmọ arábìnrin náà sì sọ fún obìnrin náà pé kó bá àwọn lọ́ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bá ṣe díẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ yẹn kan náà. Nígbà tí obìnrin náà rí i pé òun ò lè bá ìjọsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ láàárọ̀ yẹn, ó gbà láti bá wọn lọ́ sípàdé. Nígbà tí ìpàdé ń lọ lọ́wọ́, gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ń pè ló ń ṣí nínú Bíbélì ìtúmọ̀ King James tó wà lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn ohun tó gbọ́ nípàdé yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ó sọ pé ariwo ìlù àti báwọn ṣe máa ń lọgun ní ṣọ́ọ̀ṣì òun ti sú òun, ó sì ti pẹ́ tó ti ń wu òun pé kóun rí ibi tóun á ti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìsí ariwo. Ó gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ó sì tún gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ń lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ, inú rẹ̀ sì máa ń dùn láti kópa níbẹ̀.

Ẹnì Kan Ṣoṣo Ló Lè Dá A Dúró Kó Má Wàásù Mọ́

Arákùnrin ọ̀dọ́ kan lórílẹ̀-èdè Guyana sọ pé: “Mo máa ń fẹ́ wàásù fún àwọn ọmọléèwé mi, àmọ́ ọmọ kan wà tí kò fẹ́ kí n máa wàásù. Lọ́jọ́ kan, ó tì mí lu ògiri, ó wá sọ́ fún mi pé, ‘O ò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́!’ Mo sọ fún un pé, Jèhófà nìkan ló lè dá mi dúró kí n má wàásù mọ́. Nígbà tí mò ń wàásù lọ ní tèmi, ọmọ náà ya báàgì tí mo máa ń gbé kọ́ ẹ̀yìn. Ó gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú, ẹnu mi sì bẹ́jẹ̀. Wọ́n mú àwa méjèèjì lọ sí ọ́fíìsì ọ̀gá iléèwé wa, ó sì béèrè ohun tí mo ṣe fún ọmọ náà tó fi gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́ lójú. Mo sọ fún wọn pé ìhìn rere ni mò ń wàásù, ìdí sì nìyẹn tó fi ń bá mi jà. Ọ̀gá iléèwé wa béèrè ìdí tí mi ò fi bá a jà, ó sì sọ pé ohun tó yẹ kí n ṣe nìyẹn. Mo sọ pé mo ti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ nínú ìwé Róòmù 12:17 pé kí àwa Kristẹni ‘má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.’ Nígbà tí ọ̀gá iléèwé wa gbọ́ ohun tí mo sọ yìí, ó ní kí n máa lọ, ó sì sọ pé òun máa fìyà jẹ ọmọ tó lù mí náà.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 57]

Ìlú Catamarca, ní Ajẹntínà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́