ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 69-73
  • Yúróòpù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yúróòpù
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • “Ṣé Kì Í Ṣe Pé O Ṣèèṣì Yà Síbí?”
  • Ó Rí Ìwé Ìkésíni Lójú Ọ̀nà
  • Ètò Kan Lórí Rédíò Bomi Paná Ẹ̀tanú
  • Ó Fi Ìwé Ìkésíni Sẹ́nu Ọ̀nà
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 69-73
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 69]

À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Yúróòpù

  • ILẸ̀ 47

  • IYE ÈÈYÀN 741,892,871

  • IYE AKÉDE 1,601,915

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 862,555

“Ṣé Kì Í Ṣe Pé O Ṣèèṣì Yà Síbí?”

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan pe obìnrin ará Sòmálíà kan tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Sweden pé kó wá sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, obìnrin náà sì gbà láti lọ. Àmọ́, nǹkan ò lọ bó ṣe rò. Kò sẹ́ni tó tiẹ̀ kí i káàbọ̀, ṣe ni gbogbo wọn kàn ń wò ó. Ojú tì í gan-an, bí kò ṣe rí ẹni fojú jọ. Ẹnì kan tó ṣeé ṣe kó ti kíyè sí i pé ara rẹ̀ ò balẹ̀ bi í pé, “Ṣé kì í ṣe pé o ṣèèṣì yà síbí?”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Ó ní láti jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ló bá jáde. Nígbà tí obìnrin náà rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n pè é wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó bínú gan-an, ó sì sọ fún wọn pé òun ò ní tẹ Gbọ̀ngàn Ìjọba mọ́. Ó ya àwọn Ẹlẹ́rìí náà lẹ́nu, torí wọn ò rí i rárá ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nígbà tí wọ́n jọ ń sọ̀rọ̀, wọ́n wá rí i pé ṣe ló ṣèèṣì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì!

Àwọn Ẹlẹ́rìí náà rọ̀ ọ́ pé kó gbìyànjú láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba nígbà míì. Ó gbà láti lọ, àmọ́ ó sọ pé òun ò ní lò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ tíbẹ̀ ò bá bá òun lára mu. Ṣùgbọ́n, nígbà tó wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba, tayọ̀tayọ̀ ni gbogbo àwọn ará kí i káàbọ̀! Inú rẹ̀ dùn láti wà níbẹ̀ débi pé òun ló gbẹ̀yìn sí Gbọ̀ngàn Ìjọba lẹ́yìn ìpàdé. Látìgbà yẹn ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé déédéé, ó sì ti ṣèrìbọmi báyìí.

Ó Rí Ìwé Ìkésíni Lójú Ọ̀nà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 70]

Orílẹ̀-èdè Gíríìsì: Stergios ti ń kọ́ àwọn ẹlòmíì ní ohun iyebíye tó rí

Orílẹ̀-èdè Gíríìsì ni ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Stergios ń gbé. Bó ṣe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ láàárọ̀ ọjọ́ kan, ó gba ọ̀nà míì tó yàtọ̀ síbi tó máa ń gbà tẹ́lẹ̀. Stergios rí ohun kan lójú ọ̀nà, ohun náà sì gba àfiyèsí rẹ̀. Ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi ló rí. Ìbéèrè kan wà níbẹ̀ tó sọ pé: “Kí ni èrò rẹ nípa Jésù?” Ṣùgbọ́n torí pé àwọn èèyàn wà nítòsí, kò mú ìwé náà nílẹ̀. Nígbà tó délé, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ìbéèrè tó rí nínú ìwé yẹn, ó sì wù ú kó mọ púpọ̀ sí i.

Stergios ti ṣètò láti lọ mu kọfí pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. Nígbà tó ń lọ sọ́dọ̀ wọn, ó gba ojú ọ̀nà tó ti rí ìwé ìkésíni náà bóyá ìwé yẹn á ṣì wà níbẹ̀. Ó bá a níbẹ̀ lóòótọ́, àmọ́ àwọn èèyàn ṣì wà láyìíká ibẹ̀, torí náà kò tún mú un. Nígbà tí Stergios wá ń pa dà lọ sílé lẹ́yìn tí òun àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti mú kọfí tán, ọ̀nà yẹn ló tún gbà, ó rí i pé ìwé yẹn ṣì wà níbẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, ó mú ìwé náà nílẹ̀, ó sì kà á. Lẹ́yìn tó kà á tán, ó pinnu láti lọ sí Ìrántí Ikú Kristi náà.

Lẹ́yìn tí wọ́n parí Ìrántí Ikú Kristi náà, Stergios gbà pé kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé lọ́fẹ̀ẹ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé, ó sì ń ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kó lè sin Jèhófà. Ó ṣèrìbọmi ní àpéjọ àkànṣe kan tí wọ́n ṣe lóṣù March 2013.

Ètò Kan Lórí Rédíò Bomi Paná Ẹ̀tanú

Ní January ọdún 2010, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Finn nílùú Copenhagen, lórílẹ̀-èdè Denmark najú jáde, ó sì kó àwọn ìwé ìròyìn díẹ̀ dání. Bó ṣe ń gba ojú ọ̀nà tóóró kan lọ, ó rí bàbá àgbàlagbà kan tó ń rìn bọ̀ níwájú rẹ̀. Arákùnrin wa fún bàbá náà ní Ìwé ìròyìn Jí! àti Ilé Ìṣọ́ ti oṣù December 2009, èyí tó ní ọ̀kan-ò-jọ̀kan àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ayẹyẹ Kérésìmesì. Nígbà tí bàbá àgbàlagbà náà sọ̀rọ̀, Finn dá ohùn rẹ̀ mọ̀. Atọ́kùn ètò kan tí wọ́n máa ń ṣe lórí rédíò ni bàbá náà, ọ̀mọ̀wé gidi sì ni. Lọ́jọ́ kejì, Finn gbọ́ ètò tí bàbá náà máa ń ṣe, ẹnu sì yà á gan-an nígbà tí Bàbá náà sọ pé òun gba ìwé ìròyìn kan lánàá. Ó wá ka apá kan nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé náà lórí rédíò. Lára ibi tó kà sọ nípa abàmì ìràwọ̀ tó hàn lójú sánmà nígbà tí wọ́n bí Jésù. Ó sọ pé òun gbà pé Sátánì ló mú kí ìràwọ̀ náà hàn lójú sánmà.

Ó wú Finn lórí gan-an bí bàbá yìí ṣe lo ìwé ìròyìn wa. Ó bá pinnu láti wá a lọ. Nígbà tí wọ́n ríra, wọ́n jọ sọ̀rọ̀, Finn sì béèrè tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ bóyá ó ṣeé ṣe láti máa ṣe ètò kan lórí rédíò tó dá lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, ó gba èsì ayọ̀. Ó lé ní ọgbọ̀n [30] ètò yìí tí wọ́n ń fi wákátì méjì ṣe tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìgbà yẹn, ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Bíbélì sì ni gbogbo rẹ̀ dálé. Finn àti atọ́kùn ètò náà sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tí wọ́n bá yàn, wọ́n sì dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń tẹ̀ wọ́n láago lórí ètò náà.

Ọkùnrin kan tó ń gbọ́ ètò náà pe amojú ẹ̀rọ ilé iṣẹ́ rédíò náà, ó sì ní kí wọ́n gba nọ́ńbà tẹlifóònù òun, ó fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá òun kàn. Wọ́n ṣètò láti lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ni ọkùnrin náà ti máa ń gbọ́ táwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ máa ń sọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láìdáa, àmọ́ ètò tó gbọ́ lórí rédíò yìí ló bomi paná ẹ̀tanú tó ní sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọkùnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá sí Ìrántí Ikú Kristi àti àkànṣe àsọyé ti ọdún 2013. Kì í pa ìpàdé ọjọ́ Sunday jẹ, ó sì máa ń dáhùn dáadáa nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Àwọn míì lágbègbè náà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí gbọ́ ìwàásù àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí ètò tí wọ́n gbọ́ lórí rédíò.

Ó Fi Ìwé Ìkésíni Sẹ́nu Ọ̀nà

Ohun kan ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹta àpéjọ àgbègbè kan tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Ítálì. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Lucio ń dágbére fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, tọkọtaya kan wá bá wọn. Lucio béèrè ìjọ tí tọkọtaya náà ti wá. Wọ́n dá a lóhùn pé àwọn ò wá láti ìjọ kankan.

Lucio tún bi wọ́n pé, “Ṣẹ́nì kan ló pè yín wá ni?”

Tọkọtaya náà dáhùn pé, “Rárá o, a kàn wá fúnra wa ni.”

Lucio wá fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an, ló bá bi wọ́n pé, “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ máà bínú o, báwo lẹ ṣe gbọ́ tẹ́ ẹ fi wá?”

Wọ́n sọ pé, “A rí ìwé ìkésíni kan lẹ́nu ọ̀nà wa, òun la kà tá a fi wá.”

Nígbà tí tọkọtaya náà sọ ibi tí wọ́n ń gbé, ńṣe ni ìyàwó Lucio tó ń jẹ́ Ester fìtara sọ pé: “Èmi ni mo fi ìwé ìkésíni yẹn síbẹ̀! Ọjọ́ tá a parí pípín ìwé ìkésíni yẹn ni mo fi sẹ́nu ọ̀nà wọn, mo wò ó pé dípò tí màá fi da èyí tó kù nù, kí n kúkú fi sẹ́nu ọ̀nà àwọn tí kò sí nílé.” Nígbà tí tọkọtaya yìí rí ìwé ìkésíni náà, wọ́n pinnu láti rìnrìn-àjò lọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ ní Sunday tó tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn tí wọ́n sọ̀rọ̀ díẹ̀, Lucio àti ìyàwó rẹ̀ ní kí tọkọtaya yẹn wá jẹun nílé àwọn, wọ́n sì ń fìyẹn bá ọ̀rọ̀ wọn lọ. Tọkọtaya náà gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n máa ń múra ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn sílẹ̀ dáadáa, wọ́n ti ń lọ sípàdé báyìí, kódà wọ́n tún máa ń lóhùn sípàdé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́