Máa Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́
1. Àwọn àpẹẹrẹ wo la ní ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní tó fi hàn pé ó yẹ ká máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
1 Ó ṣe pàtàkì pé kí àwa Kristẹni máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Lúùkù 9:1-5; 10:1-11) Ìdí nìyẹn tí Ákúílà àti Pírísílà náà fi mú Àpólò wọ àwùjọ ẹgbẹ́ wọn, tí wọ́n sì “làdí ọ̀nà Ọlọ́run fún un lọ́nà tí ó túbọ̀ pé rẹ́gí.” (Ìṣe 18:24-26) Fún ìdí yìí kan náà ni Pọ́ọ̀lù fi gba Tímótì tó jẹ́ ajíhìnrere tó nírìírí níyànjú láti máa fi ara rẹ̀ fún kíkọ́ni kí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ lè “fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tím. 4:13-15) Láìka iye ọdún tí a ti fi ń sìnrú fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí akéde ìhìn rere, ó ṣe pàtàkì pé ká máa mú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù sunwọ̀n sí i.
2. Báwo la ṣe lè kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ẹlòmíì?
2 Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Àwọn Ẹlòmíì: Ọ̀nà kan tá a lè gbà mú kí ọ̀nà tá a gbà ń wàásù sunwọ̀n sí i ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ lára àwọn ẹlòmíì. (Òwe 27:17) Torí náà, máa kíyè sí bí ẹni tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀. Sọ fún àwọn akéde tí wọ́n mọ bá a ṣe ń bá àwọn èèyàn fèròwérò pé kí wọ́n dábàá àwọn ohun tó o lè ṣe fún ọ, kó o sì fara balẹ̀ tẹ́tí sí ohun tí wọ́n bá sọ. (Òwe 1:5) Ǹjẹ́ o mọ bí o ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí àwọn apá míì tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa pín sí? Lo ìdánúṣe, sọ fún alábòójútó àwùjọ rẹ tàbí akéde míì tó nírìírí pé kó kọ́ ẹ bí wàá ṣe máa ṣe é. Ó yẹ ká máa rántí pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà lè mú kí ọ̀nà tá a gbà ń wàásù sunwọ̀n sí i, ká sì máa bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ yìí nínú àdúrà wa lójoojúmọ́.—Lúùkù 11:13.
3. Kí ló yẹ ká ṣe tí ẹnì kan bá dábàá ohun tá a lè ṣe, kódà tí kì í bá ṣe pé àwa la ní kó ṣe bẹ́ẹ̀?
3 Má fi ṣèbínú tí ẹnì kan bá dábàá ohun tó o lè ṣe kó o lè sunwọ̀n sí i, kódà tí kì í bá ṣe pé ìwọ lo ní kó ṣe bẹ́ẹ̀. (Oníw. 7:9) Bíi tí Àpólò, ó yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún, ká sì fìrẹ̀lẹ̀ gba ìmọ̀ràn tàbí àbá tó bá fún wa. Ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tí a bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Òwe 12:15.
4. Kí nìdí pàtàkì tí Jésù fi sọ pé ká máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́?
4 Ìtẹ̀síwájú Máa Ń Fi Ògo fún Ọlọ́run: Jésù fi àkàwé kan gba àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́. Ó fi ara rẹ̀ wé igi àjàrà, ó sì fi àwọn ẹni àmì òróró ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wé ẹ̀ka. Ó sọ pé Baba òun wẹ gbogbo ẹ̀ka tó ń so èso mọ́ “kí ó lè so èso púpọ̀ sí i.” (Jòh. 15:2) Bí ẹni tó ni ọgbà àjàrà ṣe ń fẹ́ kí ọgbà àjàrà òun túbọ̀ méso jáde bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń fẹ́ ká máa sapá láti mú bí a ṣe ń so “èso ètè” wa sunwọ̀n sí i. (Héb. 13:15) Kí ló máa yọrí sí tí a bá ń tẹ̀ síwájú gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́? Jésù sọ ìdáhùn, ó ní: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀.”—Jòh. 15:8.