Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ January 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JANUARY 26
Orin 99 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 19 ìpínrọ̀ 9 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Àwọn Onídàájọ́ 5-7 (8 min.)
No. 1: Àwọn Onídàájọ́ 7:12-25 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bí Jésù Ṣe Fi Hàn Pé Òun Kúnjú Ìwọ̀n Láti Jẹ́ Ọba (5 min.)
No. 3: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Mọ Ọlọ́run—igw ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 1 sí 4 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Ìwé Tá A Máa Lò Lóṣù January àti February. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n ń fi ìwé pẹlẹbẹ Ìròyìn Ayọ̀ lọni. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kan nípa bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà lóde ẹ̀rí. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àpilẹ̀kọ tó sọ pé, “Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ sí Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Láìjáfara?”
10 min: Àwọn Alàgbà Tó Ń Sìnrú fún Olúwa—Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Fi ọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, bi í ní àwọn ìbéèrè yìí: Kí ni ojúṣe yín gẹ́gẹ́ bí olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́? Báwo lẹ ṣe máa ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀? Kí nìdí tí kì í fi í ṣeé ṣe fún yín láti pe gbogbo ẹni tó bá nawọ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́? Báwo ni ẹni tó kàwé, àwọn tó ń dáhùn àtàwọn arákùnrin tó gbé ẹ̀rọ makirofóònù nípàdé ṣe lè mú ká gbádùn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́, ká sì jàǹfààní nínú rẹ̀? Báwo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà tí ẹ lọ láìpẹ́ yìí ṣe túbọ̀ ràn yín lọ́wọ́ kí ọ̀nà tí ẹ gbà ń bójú tó iṣẹ́ pàtàkì yìí lè túbọ̀ dára sí i?
10 min: “Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ—‘Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà.’” Ìjíròrò. Sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà nínú apá yìí tó wà lórí Ìkànnì wa, kí o sì jẹ́ kí àwọn ará wo ọ̀kan lára àwọn fídíò tó wà níbẹ̀. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà lo apá tá a pè ní “Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà” tí a bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, níbi ti èrò pọ̀ sí tàbí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.
Orin 135 àti Àdúrà