Máa Tẹ̀ Síwájú Gẹ́gẹ́ Bí Òjíṣẹ́
1 Inú Bàbá wa ọ̀run máa ń dùn gan-an táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ìtẹ̀síwájú yìí kan jíjẹ́ òjíṣẹ́ tí òye rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ tó sì mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká wàásù ìhìn rere. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ alábòójútó níyànjú láti máa fàwọn ohun tó ń kọ́ sílò, kí ìlọsíwájú rẹ̀ lè fara hàn kedere. (1 Tím. 4:13-15) Ó yẹ kí gbogbo wa, tó fi mọ́ àwọn tó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń wàásù pàápàá, gbìyànjú láti mú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù sunwọ̀n sí i.
2 Ní Àfojúsùn: Tá a bá fẹ́ máa tẹ̀ síwájú, àfi ká lóhun kan tá à ń lé. Àwọn nǹkan wo la lè fojú sùn? A lè gbìyànjú láti túbọ̀ já fáfá sí i nínú lílo Bíbélì gẹ́gẹ́ bí idà ẹ̀mí. (Éfé. 6:17) Ó sì lè jẹ́ pé apá kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa la fẹ́ mú sunwọ̀n sí i, irú bíi wíwàásù lópòópónà, wíwàásù lórí tẹlifóònù tàbí wíwàásù níbi táwọn èèyàn ti ń ṣòwò. A lè fi ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́nà tó túbọ̀ múná dóko ṣe àfojúsùn wa. Ohun pàtàkì mìíràn tá a tún lè fi ṣe àfojúsùn wa ni láti túbọ̀ mọ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tá a lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká sì máa darí rẹ̀.
3 Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́: A ti ṣètò àwọn ìpàdé ìjọ láti ràn wá lọ́wọ́ ká bàa lè di òjíṣẹ́ tó túbọ̀ já fáfá, àgàgà Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Bá a bá ṣe ń múra sílẹ̀ fáwọn ìpàdé wọ̀nyí tó, tá à ń pésẹ̀ síbẹ̀, tá a sì ń fàwọn ìmọ̀ràn tá à ń rí gbà níbẹ̀ sílò ni ìbùkún jìgbìnnì tá a máa rí gbà ṣe máa tó.—2 Kọ́r. 9:6.
4 A tún ní láti ran ara wa lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. (Òwe 27:17) Tá a bá ń fetí sílẹ̀ dáadáa sí báwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀, èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Láfikún sí i, alábòójútó Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa lè ṣètò bá a ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ gbà. Tá a bá lè rí aṣáájú-ọ̀nà tàbí akéde kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti di òjíṣẹ́ tó múná dóko, ká lè máa rí ayọ̀ púpọ̀ sí i nínú ìṣẹ́ ìsìn wa, ìyẹn ì bá mà ti lọ̀ wà jù o! Tá a bá ní akéde tuntun ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa, ohun tó máa dáa jù ni pé ká fínnúfíndọ̀ pè é láti bá wa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí.
5 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí Kristẹni ni iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè ṣe lónìí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń fún Jèhófà ní “ẹbọ ìyìn” wa fi hàn pé à ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe. (Héb. 13:15) Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù, ńṣe la máa di òṣìṣẹ́ “tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tím. 2:15.