ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/02 ojú ìwé 1
  • Gbé Àwọn Ohun Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Kalẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbé Àwọn Ohun Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Kalẹ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Gbé Àwọn Góńgó Tí Wàá Lépa ní Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn Tuntun Kalẹ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ẹ̀yin Èwe—Kí Ni Àwọn Góńgó Yín Nípa Tẹ̀mí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Bọ́wọ́ Rẹ Ṣe Lè Tẹ Àwọn Àfojúsùn Rẹ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
km 8/02 ojú ìwé 1

Gbé Àwọn Ohun Tẹ̀mí Tí Wàá Máa Lépa Kalẹ̀

1 Àǹfààní ńláǹlà ló mà jẹ́ láti máa yin Jèhófà títí ayérayé o! Kí ọwọ́ wa lè tẹ góńgó yẹn, a lè gbé àwọn ohun tẹ̀mí tọ́wọ́ wa lè tẹ̀ ní àkókò yìí kalẹ̀, ká sì ṣiṣẹ́ láti lé wọn bá. Èyí á jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti lo okun wa lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání. (1 Kọ́r. 9:26) Àwọn ohun wo lọwọ́ rẹ lè tẹ̀?

2 Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Ṣé gbogbo ìpàdé ìjọ lo máa ń múra sílẹ̀ fún níkọ̀ọ̀kan? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé o máa ń wáyè láti ṣèwádìí, ṣé o sì máa ń ṣàṣàrò nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́? Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó o bá ń múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀, ṣé ńṣe lo kàn máa ń fàlà sábẹ́ àwọn ìdáhùn àbí o máa ń wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí, tí wà á sì ronú jinlẹ̀ lórí àwọn àlàyé tá a ṣe lórí wọn? Ṣé o lè fi ṣe góńgó rẹ láti máa ṣèwádìí lórí àwọn kókó díẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ látinú Bíbélì kíkà tá a yàn fún Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run? Wíwalẹ̀jìn nípa tẹ̀mí lọ́nà yìí máa ń gba àkókò àti ìsapá, àmọ́ ó máa ń mú àwọn èrè tẹ̀mí rẹpẹtẹ wá.—Òwe 2:4, 5.

3 Àwọn Ìpàdé Ìjọ: Ohun mìíràn tó o tún lè máa lépa ni pípésẹ̀ sí gbogbo ìpàdé ìjọ márààrún déédéé. Títètè dé láti bá àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kẹ́gbẹ́ pọ̀, ká sì kópa nínú orin àti àdúrà ìbẹ̀rẹ̀ máa ń fún ìjọ lókun. A tún lè gbìyànjú láti máa dáhùn ní gbogbo ìpàdé ká sì ṣiṣẹ́ lórí mímú kí àwọn ìdáhùn wa túbọ̀ dára sí i. Bóyá o lè sọ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú ìpínrọ̀ náà ṣe bá ìjíròrò náà mu tàbí kó o sọ bí ohun tí à ń kọ́ lọ́wọ́ náà ṣe lè wúlò nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́.—Héb. 10:24, 25.

4 Iṣẹ́ Ìwàásù: Iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa máa ń tẹ̀ síwájú gan-an nígbà tá a bá gbé àwọn góńgó tí a ó máa lépa kalẹ̀. Ṣé o ní iye wákàtí kan tó o ti pinnu fúnra rẹ pé wàá máa lò nínú iṣẹ́ ìsìn lóṣooṣù? Àwọn kan ti rí i pé èyí ń ṣèrànwọ́. Àbí kẹ̀, ṣé o lè ṣe dáradára sí i láwọn apá ibì kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ, irú bíi lílo Bíbélì nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò tó túbọ̀ múná dóko, sísapá láti ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí kíkọ́ni lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́?

5 Ẹ̀yin òbí, ṣé ẹ̀ ń fún àwọn ọmọ yín níṣìírí láti gbé àwọn góńgó tí wọn yóò máa lé nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kalẹ̀? Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé sísìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà, míṣọ́nnárì, tàbí ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì jẹ́ ọ̀nà kan tó dára gan-an láti fi bí ìmọrírì wọn ṣe jinlẹ̀ tó fún Jèhófà hàn.—Oníw. 12:1.

6 Bá a ti ń yẹ àwọn ìgbòkègbodò wa wò, tá à ń gbé àwọn ohun tí a óò máa lépa nípa tẹ̀mí kalẹ̀, tá a sì ń sapá láti mú kí ọwọ́ wa tẹ̀ wọ́n, à óò rí ayọ̀ púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìsìn wa, à óò sì tún jẹ́ ìṣírí fún àwọn ẹlòmíràn.—Róòmù 1:12.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́