Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ July 15
“Ǹjẹ́ o rò pé inú ọ̀run àpáàdì làwọn ẹni ibi ti máa jìyà? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì fi ohun tó jẹ́ ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ hàn kedere. [Ka Róòmù 6:23a.] Nígbà náà, ṣé ọ̀run àpáàdì wá jẹ́ ibi tá a ti ń fi iná dáni lóró ni? Àbí ó wulẹ̀ jẹ́ ipò kan téèyàn ò ti ní àjọṣe kankan pẹ̀lú Ọlọ́run? Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.”
Ilé Ìṣọ́ Aug. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àwọn àṣà tó wé mọ́ ọn wulẹ̀ jẹ́ ohun ṣeréṣeré tí kò lè pani lára. [Fi kókó kan tàbí méjì hàn án látinú àpótí tó wà ní ojú ìwé 5.] Ǹjẹ́ o ti ronú rí nípa ẹni tó ń mú káwọn èèyàn máa gba irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọ́? [Lẹ́yìn tó bá fèsì, ka 2 Kọ́ríńtì 11:14.] Ìwé ìròyìn yìí ṣe àlàyé nípa ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn gbígba ohun asán gbọ́.”
Jí! Aug. 8
“Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wo tẹ́tẹ́ títa gẹ́gẹ́ bí ohun tó gbayì láwùjọ. Àmọ́, àwọn ẹlòmíràn gbà pé ó máa ń pa ìdílé àti àwùjọ lára. Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò ọ̀ràn tẹ́tẹ́ títa, nípa ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìwádìí tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí. O tún lè kà nípa àwọn ìlànà Bíbélì lórí ọ̀ràn tẹ́tẹ́ títa.” Bí àpẹẹrẹ, ka 1 Tímótì 6:10.
“Bí ìwà ipá àti ìpániláyà ṣe ń pọ̀ sí i láìdáwọ́dúró ń kọ ọ̀pọ̀ èèyàn lóminú gidigidi. Ó ṣeé ṣe kó o gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Oníwàásù 8:9 sọ. [Kà á, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ó sì tún sọ bí irú ìtẹnilóríba bẹ́ẹ̀ ṣe máa dópin láìpẹ́.”