Orin 97
Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Òjíṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run!
1. Ẹ máa wàásù ’jọba náà nìṣó
Fún èèyàn ilẹ̀ gbogbo.
Pẹ̀lú ìfẹ́ ọmọnìkejì,
Gbé ọlọ́kàn tútù ró.
Àǹfààní ni iṣẹ́ ìsìn wa;
A ńfayọ̀ kéde ọ̀rọ̀ Jáà.
Ẹ lọ sí pápá kẹ́ẹ máa wàásù;
Jẹ́rìí sí oókọ Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú, fìgboyà
wàásù ọ̀rọ̀ náà káàkiri.
Tẹ̀ síwájú, wà nínú òtítọ́
lọ́dọ̀ Jèhófà.
2. Tẹ̀ síwájú ẹ̀yin òjíṣẹ́
Fèrè Ọlọ́run sọ́kàn.
A ńtẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Ọ̀gá wa
Pẹ̀lú ọkàn tó dọ̀tun.
Ìhìn rere Ìjọba tó ńbọ̀,
Gbogbo ayé ló yẹ kó gbọ́.
Lágbára Jèhófà là ńwàásù;
Kò síbẹ̀rù kankan fún wa!
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú, fìgboyà
wàásù ọ̀rọ̀ náà káàkiri.
Tẹ̀ síwájú, wà nínú òtítọ́
lọ́dọ̀ Jèhófà.
3. Lápapọ̀ ni à ńtẹ̀ síwájú,
Ọkùnrin àtobìnrin,
Àṣẹ́kù àtàgùntàn mìíràn,
Níbàámu pẹ̀lú òótọ́.
Iṣẹ́ mímọ́ niṣẹ́ ìsìn wa;
Tọkàntọkàn nìjọsìn wa.
Kí Ọlọ́run bàa lè kà wá yẹ
Ìwà wa gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú, fìgboyà
wàásù ọ̀rọ̀ náà káàkiri.
Tẹ̀ síwájú, wà nínú òtítọ́
lọ́dọ̀ Jèhófà.
(Tún wo Sm. 23:4; Ìṣe 4:29, 31; 1 Pét. 2:21.)