Orin 17
Ẹ Tẹ̀ Síwájú Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí!
1. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pinnu,
A múra tán láti gbèjà ìhìn rere.
Bí Sátánì tiẹ̀ ńhalẹ̀ mọ́ wa,
Aò bẹ̀rù a ńfìgbàgbọ́ tẹ̀ síwájú.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí tó gbóyà!
Ẹ yọ̀ pé ẹ ńkópa nínúuṣẹ́ Ọlọ́run!
Ẹ kéde fáyé pé, Párádísè dé tán,
Pé láìpẹ́ gbogbo ’bùkún rẹ̀ yóò dé.
2. Ọm’ogun Jáà kìí lépa adùn ayé;
Ayé àtàwọn aláṣẹ kọ́ la fẹ́ wù.
A wà láìléèérí nígbà gbogbo,
Aó sì di ìwà títọ́ wa mú dópin.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí tó gbóyà!
Ẹ yọ̀ pé ẹ ńkópa nínúuṣẹ́ Ọlọ́run!
Ẹ kéde fáyé pé, Párádísè dé tán,
Pé láìpẹ́ gbogbo ’bùkún rẹ̀ yóò dé.
3. Ayé kò retí Ìjọba Ọlọ́run;
Wọ́n ńba oókọ mímọ́ rẹ̀ jẹ́, wọn kò kàá kún.
Ẹ jẹ́ kí àwa yàá sí mímọ́,
Ká jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè mọ̀ọ́n.
(ÈGBÈ)
Tẹ̀ síwájú ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí tó gbóyà!
Ẹ yọ̀ pé ẹ ńkópa nínúuṣẹ́ Ọlọ́run!
Ẹ kéde fáyé pé, Párádísè dé tán,
Pé láìpẹ́ gbogbo ’bùkún rẹ̀ yóò dé.
(Tún wo Fílí. 1:7; 2 Tím. 2:3,4; Ják. 1:27.)