Orin 88
Ọmọ Jẹ́ Ohun Ìní Tí Ọlọ́run Fi Síkàáwọ́ Òbí
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Tí ọkùnrin bá di baba
Tí obìnrin sì dìyá àbúrò,
Kí wọ́n rántí, ṣe la fún wọn ṣọ́,
Àwọn nìkan kọ́ ló lọmọ.
Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni;
Òun ni Orísun ìyè àtìfẹ́.
Ó fáwọn òbí ní ìtọ́ni
Kí wọ́n lè fọgbọ́n tọ́ ọmọ wọn.
(ÈGBÈ)
Ti Jèhófà ni ọmọọwọ́ yín;
Ẹ̀mí iyebíye ló jẹ́.
Oore tó ga jù tẹ́ẹ lè ṣe fúnun;
Ni pé kó mòfin Ọlọ́run.
2. Ọ̀rọ̀ t’Ọ́lọ́run pa láṣẹ
Kò gbọ́dọ̀ kúrò lọ́kàn rẹ rárá.
Kọ́ ọmọkùnrin, kọ́ ’mọbìnrin;
Èyí ni ojúṣe tìrẹ.
Máa sọ ọ́ fún wọn lójú ọ̀nà,
Tóo bá dìde tàbí tóo bá ńsinmi.
Kí wọ́n lè rántí lọ́jọ́ ọ̀la,
Kí wọ́n jólóòótọ́, ẹni ’bùkún.
(ÈGBÈ)
Ti Jèhófà ni ọmọọwọ́ yín;
Ẹ̀mí iyebíye ló jẹ́.
Oore tó ga jù tẹ́ẹ lè ṣe fúnun;
Ni pé kó mòfin Ọlọ́run.
(Tún wo Diu. 6:6, 7; Éfé. 6:4; 1 Tím. 4:16.)