Àwọn Ìfilọ̀
Ìwé tá a máa lò ní March àti April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! May àti June: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú èyíkéyìí tí ìjọ bá ní lọ́wọ́, irú bíi, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? àti àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú márùn-ún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde: Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì Jẹ́?, Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Ọ̀la?, Kí Ló Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀?, Ta Ló Ń Darí Ayé Yìí?, Ǹjẹ́ Ìyà Lè Dópin?
Ọjọ́ Monday, April 14, 2014 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Tó bá jẹ́ ọjọ́ Monday ni ìjọ yín máa ń ṣèpàdé, kí ẹ ṣe é ní ọjọ́ míì tí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yín lọ́sẹ̀ yẹn. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ó di dandan kẹ́ ẹ fagi lé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, kí olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fi àwọn apá Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó bá kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n kún Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì lóṣù yẹn.
Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù March 2014, àkòrí àsọyé fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ọlọ́run Máa Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Là Lọ́wọ́ Wàhálà Ayé.”