Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 26
Orin 60 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 7 ìpínrọ̀ 18 sí 22, àpótí tó wà lójú ìwé 75 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 34-37 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 34:1-16 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ó Yẹ Káwọn Kristẹni Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run—td 34A (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jà?—lr orí 19 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù May. Lo àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù June. Gba àwọn ará níyànjú pé kí gbogbo wọn jáde òde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
10 min: Fífarada Inúnibíni Máa Ń Jẹ́rìí Fáwọn Èèyàn. (Lúùkù 21:12, 13) Ìjíròrò tó dá lé ìwé Ọdọọdún 2013, ojú ìwé 124, ìpínrọ̀ 1 àti ojú ìwé 128, ìpínrọ̀ 1 sí 2. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò. Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Ní kí àwọn ará sọ ọ̀nà tí wọ́n gbà jàǹfààní látinú ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jinlẹ̀ tí àwọn òbí wọn kọ́ wọn.
Orin 88 àti Àdúrà