Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 2
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 2
Orin 134 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 8 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 38-40 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 40:20-38 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ohun Tó Fi Hàn Pé Ọlọ́run Wà—td 34B (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo?—lr orí 20 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù June. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ lo àwọn àbá méjì tó wà lójú ìwé yìí láti ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn àbá náà láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, fún àwọn ará níṣìírí pé kí wọ́n ka àwọn ìwé ìròyìn náà dáadáa, kí wọ́n sì fìtara kópa nínú fífi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Sílẹ̀.” Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 44 àti Àdúrà