Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ August 4
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ AUGUST 4
Orin 51 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 11 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 4-6 (10 min.)
No. 1: Númérì 4:17-33 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ìjọba Ọlọ́run Bẹ̀rẹ̀ Ìṣàkóso Nígbà Táwọn Ọ̀tá Kristi Ṣì Wà Lẹ́nu Iṣẹ́ Ibi Wọn—td 23B (5 min.)
No. 3: Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí—lr orí 28 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù August. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lójú ìwé yìí ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni nígbà tí a bá ń ṣe ìpolongo àkànṣe ní àwọn òpin ọ̀sẹ̀. Ní kí àwọn ará sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tó fi yẹ ká fi àwọn ìwé ìròyìn lọni nígbà tó bá yẹ láwọn òpin ọ̀sẹ̀ oṣù August? Àwọn ìgbà wo ló sì yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?
10 min: Ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nígbà tí wọ́n lo àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà.” Ní kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.
Orin 75 àti Àdúrà